Jump to content

Uche Azikiwe

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Uche Azikiwe
Ọjọ́ìbíUche Ewah
4 Oṣù Kejì 1947 (1947-02-04) (ọmọ ọdún 77)
Afikpo, Ebonyi State
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Nigeria
Olólùfẹ́Nnamdi Azikiwe
(1973–1996, his death)
Àwọn ọmọ2

Uche Ewah Azikiwe tí a bí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kejì ọdún 1947 jẹ́ Ọ̀mọ̀wé ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, olùkọ́ àti òǹkòwé. Òun ni opó Nnamdi Azikiwe Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí. [1][2] Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ti Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ tí ìmọ̀ Ìpìlẹ̀-ẹ̀kọ́ (the department of Educational Foundation, Faculty of Education), ní University of Nigeria, Nsukka. Lọ́dún 1999, wọ́n yàn án mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ adarí ilé ìfowópamọ́-àgbà (member, board of directors of Central Bank of Nigeria )

Ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí i ní ọjọ́ kẹrin oṣù kejì ọdún 1947 ni ìlú Afikpo ní ìpínlẹ̀ Ebonyi. A bí i sínú ìdílé Sergeant Major Lawrence A. àti Florence Ewah.

Ó gboyè Bachelor of Arts nínú EnglishUniversity of Nigeria, Nsukka (UNN) kí ó tó tẹ̀ síwájú láti gba ìwé-ẹ̀rí Masters nínú Curriculum Studies and Sociology of Education. Ní ọdún 1992, ó gboyè Ph.D. ninu Sociology of Education/Gender Studies ní Fásitì kan náà.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]