Unbreakable (fíìmù Nollywood)
Unbreakable jẹ́ fíìmù ajẹmọ́fẹ̀ẹ́ ti orílẹ̀-èdẹ̀ Nàìjíríà tó dá lórí baálé ilé kan tó ní láti kojú ìṣòro ààrùn ọpọlọ ti ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀fẹ́ rẹ̀. Buky Campbell ló ṣàgbéjáde fíìmù yìí, tí olùdarí rẹ̀ sì jẹ́ Ben Chiadika, Sola Osofisan ló sì kọ ọ́. Oṣù kẹwàá ọdún 2018 ni wọ́n ya fíìmù yìí ní ìlú Èkó.[1]
Àwọn akópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]OC Ukeje bí i Chidi
Arese Emokpae bí i Ikepo
Yinka Davies bí i Receptionist
John Dumelo bí i Mike
Wendy Lawal bí i Kunle
Uche Mac-Auley bí i Dr Tebowei
Bimbo Manuel bí i Damola
Richard Mofe-Damijo bí i General
Ìtàn ní ṣókí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìgbéyàwó Chidi àti Ikepo jẹ́ èyí tó ní arinrin lọ́pọlọpọ̀, wọ́n sì gbáradì aĺti bẹ̀rẹ̀ ayé wọn gẹ́gẹ́ bí i lọ́kọ láya. Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ ní ibiṣẹ́, lẹ́yìn ọ́nimuùnù wọn, Chidi rí fọ́nrán ìyàwó tí ó fi sílẹ̀ kó tó kúrò ní ilé, ní ojú títì tó ń rìn lọ, tó sì ń sọ oríṣiríṣi lẹ́nu.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Unbreakable focuses on mental illness". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-11-21. Retrieved 2022-07-25.