OC Ukeje

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
OC Ukeje
Ọjọ́ìbíOkechukwu Ukeje
15 Oṣù Keje 1981 (1981-07-15) (ọmọ ọdún 42)
Lagos State, Nigeria
Ẹ̀kọ́University of Lagos
Iṣẹ́Film actor, model, musician
Ìgbà iṣẹ́2007— present
TelevisionAmstel Malta Box Office realiyTV Show
Olólùfẹ́
Senami Ibukunoluwa Togonu-Bickersteth (m. 2014)
Awards2008 Africa Movie Academy Awards for Most Promising Actor

Okechukwu Ukeje /{{{1}}}/, tí àọn ènìyàn tún mọ̀ sí OC Ukeje jé òṣèrékùnrin ilẹ̀ Nàìjíríà,[1]àti olórin.[2] Ó di gbajúmọ̀ lẹ́yìn tó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Amstel Malta Box Office (AMBO).[3] Ó ti gba ọ̀pọlọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ bí i Africa Movie Academy Awards, Africa Magic Viewers Choice Awards, Nollywood Movies Awards, Best of Nollywood Awards, Nigeria Entertainment Awards àti Golden Icons Academy Movie Awards. Ó sì ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù àgbéléwò lóríṣịríṣi tó ti gba ọ̀pọ̀ àmì-ẹ̀yẹ, bí i Two Brides and a Baby, Hoodrush, Alan Poza, Confusion Na Wa àti Half of a Yellow Sun.[4]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Okechukwu Ukeje wá láti ìlú Umuahia,[5]Ipinle Abia, àmọ́ Ìpínlẹ̀ ÈkóNàìjíríà ni wọ́n bi sí tó sì dàgbà sí. Òun ni ọmọ kejì láàárín àwọn ọmọ mẹ́ta ti òbí rẹ̀ bí.[6]

Iṣẹ́ tó yàn láàyò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-ìwé Federal Government College Ijanikin, ní Ojo, ní Eko ni ó lọ. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré-ṣíṣe nígbà tó wà ní ọdún kìíní ní University of Lagos, Yaba, pẹ̀lú eré orí-ìtàgé kan. Ó tẹ̀síwájú láti ṣe iṣẹ́ orin kíkọ àti eré-ṣíṣe, àmọ́ eré orí-ìtàgé ló fi bẹ̀rẹ̀, ó sì ṣe é fún ọdún mẹ́rin àkọ́kọ́ kí ó tó gba àmì-ẹ̀yẹ ti ètò Amstel Malta Box Office (AMBO).[7] Ìfarahàn àkọ́kọ́ rẹ̀ lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán wáyé nínú fíìmù White Waters (2007) pẹ̀lú Joke Silva àti Rita Dominic. Izu Ojukwu sì ni olùarí erẹ́ náá. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Africa Movie Academy Awards (AMAA) fún òṣèrékùnrin tó dára jù lọ ní ọdún 2008, àti City People's Award fún Best New Act (2010).[8]

Kò dẹ́kun orin kíkọ. Ó ṣịṣẹ́ pẹ̀lú àwọn olórin mìíràn ní Nàìjíríà. Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀ fíìmù àti ètò orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán láàárín ọdún 2008 àti 2012.[9]

Ìgbésí ayé ara ẹni[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ukeje ń gbé ní Eko, ní Nàìjíríà. Arábìnrin Senami Ibukunoluwa Togonu-Bickersteth ni ó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ní 8 November 2014.[10][11]

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Fíìmù Ojúṣe Ìtọ́ka
2007 White Waters Actor
2008 Comrade Hakeem
2011 Black Gold Peter Gadibia
Two Brides and a Baby Badmus
2012 Black November Peter Gadibia
Hoodrush Shez Jabari
Till Death Do Us Part (Short) John
2013 Confusion Na Wa Charles Duka
Alan Poza Alan Poza
Half of a Yellow Sun Aniekwena
Awakening Nicholas
Gone Too Far Iku
The Rubicon David
2014 When Love Happens Dare
Gidi Up (TV Series) Obi (2014 – )
A Play Called a Temple Made of Clay (Short) Hakeem [12]
2015 The Department Segun
Before 30 Ayo (2015-)
2016 The Arbitration Mr. Gbenga
Remember me
North East Emeka Okafor
2017 Potato Potahto Mr. Tony Wilson [13][14]
Catch.er Detective Komolafe
2018 Shades of Attraction
In Sickness and Health
The Royal Hibiscus Hotel
2019 Heaven's Hell Ahmed
Ashen
2020 Shine Your Eye Amadi
2022 Black mail [15]
2022 Brotherhood Izra
2023 Orah Agent Uche Odi

Àmì-ẹ̀yẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Àmì-ẹ̀yẹ Ìsọ̀rí Fíìmù Èsì Ìtọ́ka
2008 Africa Movie Academy Awards Most Promising Actor White Waters Gbàá
2012 Africa Movie Academy Awards Best Actor in a Leading Role Confusion Na Wa Wọ́n pèé
2013 Nigeria Entertainment Awards Best Lead Actor in a Film Alan Poza Gbàá
Best of Nollywood Awards Best Lead Actor in an English Movie Gbàá
Nollywood Movies Awards Best Actor in a Lead Role Hoodrush Gbàá [16]
Africa Magic Viewers Choice Awards Best Actor in a Drama Two Brides and a Baby Gbàá [17]
2019 Best of Nollywood Awards Best Actor in a Lead role – English Unbreakable Wọ́n pèé [18]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Adebayo, Tireni (2021-07-16). "OC Ukeje quietly marks 40th birthday". Kemi Filani News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-12. 
  2. I’m Attracted To Older Women – Okechukwu Chukwudi Ukeje 6 November 2012
  3. "OC Ukeje, Actor". Mandy. Retrieved 2016-05-13. 
  4. "List of winners of Nigeria Entertainment Awards 2013". 
  5. "Why women send nude photographs to me - OC Ukeje". naijanewsmagazine.blogspot.com. 10 June 2013. 
  6. "Nigeria: OC Ukeje, Majid Breaking the Cinemas". allAfrica.com. Retrieved 2016-05-13. 
  7. "How I handle my female admirers —O.C Ukeje". Vanguard. http://www.vanguardngr.com/2011/05/how-i-handle-my-female-admirers-%E2%80%94o-c-ukeje/. 
  8. Systems, Clearwox. "Oc Ukeje on iBAKATV | Home for Nollywood Movies". ibakatv.com. Archived from the original on 2016-08-22. Retrieved 2016-05-13. 
  9. "O.C. Ukeje". IMDb. Retrieved 2016-05-13. 
  10. "OC Ukeje Shares On His Marriage Experience And How He Met His Wife". Pulse Nigeria TV. Misimola. 19 May 2015. Retrieved 19 May 2015. 
  11. "Nollywood actor, OC Ukeje weds at 33 – Nigerian Entertainment Today – Nigeria's Top Website for News, Gossip, Comedy, Videos, Blogs, Events, Weddings, Nollywood, Celebs, Scoop and Games" (in en-GB). Nigerian Entertainment Today – Nigeria's Top Website for News, Gossip, Comedy, Videos, Blogs, Events, Weddings, Nollywood, Celebs, Scoop and Games. 2014-11-10. http://thenet.ng/2014/11/nollywood-actor-oc-ukeje-weds-at-33/. 
  12. 'Kusare, Mak (2000-01-01), A Play Called a Temple Made of Clay, retrieved 2016-05-13 
  13. "Shirley Frimpong-Manso's 'Potato Potahto' makes it to Netflix - MyJoyOnline.com". www.myjoyonline.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-02-03. 
  14. Frimpong-Manso, Shirley (2019-12-15), Potato Potahto (Comedy), O. C. Ukeje, Joselyn Dumas, Joke Silva, Kemi Lala Akindoju, 19 April Entertainment, Ascend Studios, Lufodo Productions, retrieved 2021-02-03 
  15. "Obi Emelonye's 'Black Mail' Opens in 100 UK Cinemas – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2022-08-04. 
  16. "Phone Swap, OC Ukeje and Rita Dominic Win Big at 2013 NMA". Channels Television. Retrieved 2022-07-22. 
  17. Inyang, Ifreke (2013-03-10). "Mercy Johnson, Mirror Boy, Jackie Appiah, OC Ukeje - See full list of winners from AMVCA 2013". Daily Post Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-22. 
  18. Bada, Gbenga (2019-12-15). "BON Awards 2019: 'Gold Statue', Gabriel Afolayan win big at 11th edition". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-10-10.