Jump to content

Vitalina Varela (Òṣèrébìnrin)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Vitalina Varela
Ọjọ́ìbí1966 (ọmọ ọdún 57–58)
Orílẹ̀-èdèCape Verdean
Iṣẹ́Actress
Notable workVitalina Varela

Vitalina Varela (tí wọ́n bí ní ọdún 1966) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Cape Verde.

Wọ́n bí Varela ní orílẹ̀-èdè Cape Verde. Ó ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú Joaquin Varela ní àwọn ọdún 1980, wọ́n sì ti ní àwọn ọmọ méjì. Ọkọ rẹ̀ Joaquin di olóògbé ní ọdún 2013.[1] Varela kó àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ ní ọdún 2014 nínu eré kan tí Pedro Costa ṣe tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Horse Money.[2] Varẹla kíì ṣe iṣẹ́ òṣèré tẹ́lè bẹ́è sì ni kò kọ́ṣẹ́ eré ṣíṣe.[3] Ṣùgbọ́n lẹ́hìn tí òun àti Pedro Costa di ọ̀rẹ́ nípasẹ̀ fíìmù tí wọ́n dì jọ siṣẹ́ pọ̀ lóri rẹ̀, Costa wòye pé ó yẹ kí àwọn ṣe fíìmù míràn lórúkọ rẹ̀.[4]

Ní ọdún 2019, ó kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Vitalina Varela, tí Costa sì jẹ́ olùdarí. Ipa rẹ̀ dá lóri fífẹ́ arákùnrin kan gẹ́gẹ́ bi ọkọ rẹ̀. Arákùnrin náà di ẹni tí wọ́n wá fún bi ogójì ọdún tí àwọn méjèjì síì kọ̀ láti fojúkojú títí arákùnrin náà fi jẹ́ Ọlórun nípè.[5]

Eré náà dá lóri ìṣẹ̀lẹ̀ ayé Varela fúnrarẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe jẹ́ wípé lẹ́hìn ọjọ́ kẹẹ̀ta tí ọkọ rẹ̀ ṣaláìsí ni ó wa lọ sí ìlú Lisbon.[3] Peter Bradshaw fi ẹyìn fún Varela fún iṣẹ́ takuntakun rẹ̀ nínu eré náà.[2] Varela gba àmì-ẹ̀yẹ òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Locarno Film Festival, tí fíìmù náà sì gba ẹ̀bùn Golden Leopard fún fíìmù tí ó tayọ jùlọ.[6]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • 2014: Horse Money
  • 2019: Vitalina Varela

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]