Vlekete (Ọjà Ẹrú)
Ìrísí
Vlekete, ọjà okowò ẹrú jẹ́ ọjà tí wọ́n ti ń ṣe káràkátà ẹrú ní ìlú Àgbádárìgì tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Badagry ní ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (Nigeria). Wọ́n dá ọjà yìí sílẹ̀ lọ́dún 1502. Òrìṣà kan tí wọ́n ń pè ní Vlekete ni wọ́n fi orúkọ rẹ̀ dá ọjà náà. Ó jẹ́ ọjà ẹrú tó gbajúmọ̀ gidigidi nílẹ̀ adúláwò nígbà okowò ẹrú ní Badagry tí gbogbo àwọn olókowò káàkiri ilẹ̀ Áfíríkà máa ń kó ẹrú wọn wá tà fún àwọn òyìnbó. Èyí ló mú Vlekete jẹ́ ọjà ẹrú tó tóbi jù lọ ní Áfíríkà.[1] [2] [3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Tijani, H.I. (2010). The African diaspora: historical analysis, poetic verses, and pedagogy. Learning Solutions. ISBN 978-0-558-49759-0. https://books.google.com/books?id=fdFPAQAAIAAJ. Retrieved 2019-11-30.
- ↑ Olaide-Mesewaku, A.B.; Olaide-Mesewaku, B.A. (2001). Badagry district, 1863-1999. John West Publications Ltd.. ISBN 978-978-163-090-3. https://books.google.com/books?id=aJMuAQAAIAAJ. Retrieved 2019-11-30.
- ↑ Njoku, Jude (2013-02-05). "Vlekete: When a slave market becomes a tourist centre". Vanguard News. Retrieved 2019-11-30.