Jump to content

Wande Abimbola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Chief
Ògúnwán̄dé Abím̄bọ́lá
Ọjọ́ ìbí24 Oṣù Kejìlá 1932 (1932-12-24) (ọmọ ọdún 91)
ọ̀yọ́, Nàìjíríà
Iṣẹ́olórí ẹsìn, ònímọ̀-àgbà fásitì, ati olóṣèlú
Alma materUniversity of Ibadan

Wándé Abímbọ́lá (ọjọ́ ìbí Oṣù Kẹfà 26, 1932 ní. ìlú Ọ̀yọ́, Nigeria) ó jẹ́ olùkọ́ lítírésọ̀ ní ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ Èdè àti Lítírésọ̀ Aáfíríkà ní Yunifasiti Obafemi AwolowoIle-Ife, Nigeria.[1] Ó jẹ́ olórí ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ yìí fún ọjọ́ pípé kí ó tó wá di 'Dean Faculty of Arts' ní ilé-ẹ̀kọ́ kan náà. Ìgbà tí ó ṣe ni ó di olórí oko fún Obafemi Awolowo University OAU. Sáà méjì ni ó fi je olórí oko yìí. Lẹ́yìn ìgbà tí ó fi ipò olórí oko yìí sílẹ̀ ni ó fẹ̀yìn tì. Ó se ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lórí èdè Yorùbá ní pàtàkì jùlọ lórí Ifá.[2][3]

Ìkẹ́kọ̀ọ̀ rẹ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1963, Abimbola kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ nípa ìtàn ní University College, Ibadan. [4] Ní ọdún 1971, ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Masters ní Northwestern University, Evanston, Illinois. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Doctorate nípa ìtàn àròsọ láti University of Lagos ní ọdún 1966.[5] Abímbólá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè PhD àkọ́kọ́ ní University of Lagos. [6] Ó di ọ̀jọ̀gbọ́n (Professor) ni3 1976.[7]

Abimbola kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Fáṣítì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, awon náà ní; University of Ibadan láàrin ọdún 1963 sí 1965, University of Lagos láàrin 1966 sí 1972, University of Ifè láàrin ọdún 1972 sí 1991. Ó ti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn fásitì àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn bí Indiana University, Amherst College, Harvard University, [8] Boston University, Colgate University, University of Louisville.

Abimbola ti kọ àwọn ìwé lórí Ifá àti àsà Yórùbá. Ní ọdún 1977, NOK Publishers tẹ ìwé tí Abímbólá kọ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Ifá Divination Poetry.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Abimbda, Wande; Abimbola, Wande. "Wande Abimbola". AfroCubaWeb. Retrieved 2019-05-28. 
  2. "Ifa, wandeabimbola.com Home". Ifa, wandeabimbola.com Home. 2011-10-28. Retrieved 2019-05-28. 
  3. Published (2015-12-15). "I was ridiculed for returning home a poor senator –Prof. Wande Abimbola". Punch Newspapers. Retrieved 2019-05-28. 
  4. "Prof. Wande Abimbola, Awise Awo Agbaye – DAWN Commission" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-09-29. 
  5. "Prof. Wande Abimbola, Awise Awo Agbaye – DAWN Commission" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-23. 
  6. "Prof. Wande Abimbola, Awise Awo Agbaye – DAWN Commission" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-23. 
  7. "Wande Abimbola celebrates His Birthday". Oduduwa Watch. Archived from the original on 2021-01-20. Retrieved 2021-01-23. 
  8. "Wande Abimbola". www.afrocubaweb.com. Retrieved 3 May 2019.