Wikipedia:Àìṣojúṣájú
Ìrísí
Kíkọ Wikipedia láìṣojúṣájú
[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn aláfikún sí Wikipedia ní wọ́n gbọ́dọ̀ sapá láti kọ àwọn ayọkà àti àkọsílẹ̀ orí Wikipedia láì ṣe ègbè tàbí ró ilé apá kan dá apá kan sí tàbí ṣe ojú-ìṣájú níbi àgbékalẹ̀ wọn, bí ǹkan bá ṣe rí ni wọ́n ma kọọ́ sílẹ̀. Wọ́n ma ń gbìyànjú láti yàgò fún ìpolongo tí kò lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n kìí ṣe fàá-kája lórí ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, dípò bẹ́ẹ̀ onírúurú àríwòye àti ẹ̀rí máa jẹ́mi nìṣó tí ó bá wà ní àrọ́wọ́tó ni wón yóò lò láti fi gbe ẹ̀rí ọ̀rọ̀ wọn. Gbogbo àyọkà pátá ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe lámèyìtọ́ ìjágeere wọn pẹ̀lú àwọn ìtọ́kasí tí ó rẹ́sẹ̀walẹ̀, pàá pàá jùlọ bí àyọkà kan bá fẹ́ lọ́júpọ̀ tàbí tí ó bá jẹ́ àyọkà nípa alààyè ènìyàn. Láfikún, a kò fàyè gba ' ìrírí, èrò, tàbí ìròrí aláfikún lórí Wikipedia. Bí ẹyẹ bá ṣe fò la ṣe ń sọ̀kò rẹ̀.