Jump to content

Wikipedia:Àyọkà ọ̀ṣẹ̀ 42 ọdún 2020

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣe àmúlò Ìjìnnà-síra-ẹni nípa títò lọ́wọọ̀wọ́ láti wọnú ọjà ìgbàlódé ní ìlú London nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn èrànkòrónà lọ́dún 2020
Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣe àmúlò Ìjìnnà-síra-ẹni nípa títò lọ́wọọ̀wọ́ láti wọnú ọjà ìgbàlódé ní ìlú London nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn èrànkòrónà lọ́dún 2020

Nínú ìmò ètò ìlera ìgboro, ìsúnjìnnà-síra-ẹni láwùjọ tàbí ìsúnjìnnà-síra-ẹni láifarakan-ra (Social distancing lédè gẹ̀ẹ́sì) jẹ́ ìlànà tí kìí ṣe nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìlò oògùn pẹ̀lú èròǹgbà láti dènà títànká àjàkálẹ̀ ààrùn nípa jíjìnnà sí ara ẹni lójúkojú láti ṣe àdínkù iye ìgbà tí àwọn ènìyàn lè súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí. Ó jẹ mọ́ ìṣèdiwọ̀n bí ènìyàn kan ṣe lè jìnnà sí ẹlòmíràn (irú òdiwọ̀n bẹ́ẹ̀ máa ń yàtọ̀ láti ìgbà dé ìgbà àti ní orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan) àti yíyẹra fún ìpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn. Nípa Ìjìnnà-síra-ẹni, ó ṣe é ṣe kí àdínkù wà fún kíkó àjàkálẹ̀ ààrùn rán ẹni tí kò láàrùn èyí tí ó lè wáyé nípa dídára pọ̀ mọ́ ẹni tí ó ti kó ààrùn, tí èyí yóò sìn ṣe àdínkù iye ẹni tí ààrùn bẹ́ẹ̀ lè pa. A máa ń lo ìlànà yìí pẹ̀lú ìwà ìmọ́tótó èémí àti fífọwọ́ ẹni. Nígbà rògbòdìyàn àjàkálẹ̀ ààrùn ẹ̀rànkòrónà 2019, àjọ ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) dábàá láti ṣègbè fún Ìjìnnà-síra-ẹni tí ó tako Ìjìnnà-sáwùjọ-eni, láti ṣàlàyé pé Ìjìnnà-síra-ẹni ni ó lè ṣe àdínkù kíkó àjàkálẹ̀ ààrùn náà, àwọn ènìyàn ṣì lè ní ìbáṣepọ̀ tó dára nípa lílo ìmọ̀-ẹ̀rọ. Láti ṣe àdínkù ìkóràn àjàkálẹ̀ ààrùn àti láti dènà iṣẹ́ àṣekúdórógbó fún àwọn elétò ìlera, pàápàá jù lọ nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin Ìjìnnà-sápèéjọ ni wọ́n là kalẹ̀, lára wọn ni títi ilé-ìwé àti àwọn ilé ìjọsìn pa, ìdágbé, ìséra-ẹni dènà àjàkálẹ̀ ààrùn, òfin kónílégbélé àti gbígbégidínà ìpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn. (ìtẹ̀síwájú...)