Jump to content

Wikipedia:Àyọkà ọṣẹ̀ 29 ọdún 2012

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àsìá ilẹ̀ Índíà
Àsìá ilẹ̀ Índíà

Índíà, lóníbiṣẹ́ bi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Índíà (Híndì: भारत गणराज्य Bhārat Gaṇarājya), jẹ́ orílẹ̀-èdè kan ní Gúúsù Ásíà. Òhun ni orílẹ̀-èdè keje tótóbijùlọ gégé bíi ìtóbi ìyaoríilẹ̀, orílẹ̀-èdè kejì tóní alábùgbé jùlọ pẹ̀lú iye bíi ẹgbẹgbẹ̀rúnkejì 1.18 àwọn ènìyàn, àti orílẹ̀-èdè òṣèlúaráàlú alábùgbé jùlọ lágbàáyé. O ja mo Okun India ni guusu, Okun arabu ni iwoorun, ati Ebado Benga ni ilaorun, India ni ile eti odo to je 7,517 kilometres (4,700 mi). O ni bode mo Pakistan ni iwoorun; Saina, Nepal, ati Bhutan si ariwa; ati Bangladesh ati Burma ni ilaorun. India wa nitosi Sri Lanka, ati Maldives ti won wa ni Okun India.

Gege bi ile Asa-Olaju Afonifoji Indus ati agbegbe ojuona owo latayeraye ati awon ile obaluaye, orileabe India je didamo fun ola aje ati asa re kakiri atigba to ti wa. Esin nla merin, Hinduism, Buddhism, Jainism ati Sikhism ni won bere latibe, nigbati Zoroasrianism, Esin Ju, Esin Kristi ati Imale de sibe ni egberundun akoko IO (CE) won si kopa ninu bi orisirisi asa agbegbe na seri. Diedie o je fifamora latowo British East India Company lati ibere orundun ikejidinlogun, o si di ile amusin Ile-oba Isodokan lati arin orundun ikandinlogun, India di orile-ede alominira ni 1947 leyin akitiyan fun isominira to se pataki fun isatako alaise jagidijagan kakiri.

India je orile-ede olominira kan to ni ipinle 28 ati awon agbegbe isokan meje pelu sistemu onileasofin oseluaralu. Okowo India ni okowo ikokanla titobijulo gege bi olorujo GDP lagbaye ati ikerin titobijulo gege bi ibamu agbara iraja. Otun je omo egbe Ajoni awon Orile-ede, G-20, BRIC, SAFTA ati Agbajo Owo Agbaye. India je orile-ede toni ohun-ijagun bombu inuatomu, o si ni ile-ise ologun ikewa ton nawojulo pelu ile-ise ologun adigun keji titobijulo lagbaye. Atunse okowo to bere lati 1991 ti so India di ikan ninu awon okowo to n dagba kiakia julo lagbaye; sibesibe, aini si tun ba ja ati aimookomooka, iwa-ibaje, arun, ati aijeunkanu. Gege bi awujo esin olopolopo, eledepupo ati eleya eniyan pupo, India tun je ibugbe fun opolopo awon eran-igbe ni opolopo ibi alaabo. (tẹ̀síwájú...)