Jump to content

Wikipedia:Ìrẹ̀lẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ojúewé yìí ní ìpinu ọ̀nà ìṣiṣẹ́ kan Wikipedia nínú. Ó jẹ́ èso ìfohùnṣọ̀kan, bẹ́ ẹ̀ sì ni ó jẹ́ gbígbàgbọ́ pé gbogbo àwọn oníṣe gbọ́dọ̀ tẹ̀lé wọn gbámúgbámú. Ẹ le ṣàtúnṣe àkóónú ojúewé náà sùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ọ mọ́ ṣe ìyípadà ìpinu ọ̀nà ìṣiṣẹ́ kankan láì kọ́kọ́ filọ àwọn oníṣe yìókù.
Àkékúrús:
WP:Ìrẹ̀lẹ̀
WP:I
Ìrẹ̀lẹ̀, ìbọ̀wọ̀ fún ara wa ṣ pàtàkì

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ara ìṣe wa ní Wikipedia, ó sì wà lára òpó márún tí ó gbé Wikipedia ró. Ètò ìmúlò yìí ṣe àlàyé nípa bí a ṣe fẹ́ kí oníṣẹ́ ṣe máa dojú kọ ìṣòro tí wọ́n bá yọjú. Níwọ̀nba, àwọn olóòtú gbọ́dọ̀ ḿa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Kí wọ́n máa gbìyànjú lati mú ìtẹ̀síwájú bá ìwé-ìmọ ọ̀fẹ́ kí wọ́n sì máa hu ìwà tó dára, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, ìwà tútú, pàápàá jùlọ tí ìtàkùrọ́sọ̀ bá ń gbóná jinjin. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí Wikipedia fẹ́ níṣe pẹ̀lú gbogbo àwọn olóòtú nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ní Wikipedia, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ní ojú ewé ọ̀rọ̀ oníṣẹ́ àtí ojú ewé ọ̀rọ̀ àyọkà àti gbogbo ìjíròrò pèlú tàbí nípa àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ tí ó jẹ́ olùkọ Wikipedia.