Christmas

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Xmas)
Àwòrán ìbí Jésù.
Christmas
Ọdún Kérésìmesì
Also calledNoël, Nativity, Xmas, Yule
Observed byChristians, many non-Christians[1][2]
TypeChristian, cultural
SignificanceAyẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù
Date
Celebrationsìfúni lẹ́bùn, àti àpéjọpọ̀
ObservancesÌpéjọpọ̀ ní ilé ìjọsìn

Ọdún Kérésìmesì(tí wọ́n ń pè ní Christmas ní èdè Gẹ̀ẹ́sì) jé ayẹyẹ ọdọọdún láti ṣe àjọyọ̀ ibí àti ìwà sáyé Jésù Kristi, èyí tí ó ma ń sábà wáyé ní ọjọ́ Kàrúndinlogbin oṣù Kejìlá(Dec 25). Bí ó tilè jẹ́ wípé àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńṣe àjọyọ̀ yìí ní ọjọ́ Kàrún lélógún oṣù Kejìlá, àwọn Kristẹni míràn ṣe ayẹyẹ náà ní ọjọ́ míràn, bí àpẹẹrẹ, àwọn ìjọ ní órílẹ̀ èdè Armenia ṣe ajoyo náà ni ọjọ́ keje oṣù kini(Jan 6). Àwọn ìjọ míràn ní Armenia tí ó ún lo Kalenda Julian ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì ní ọjọ́ kádinlogun oṣù Kínní ọdún(Jan 19), ọjọ́ kejìdínlógún sì jẹ́ ọjọ́ aisimi Kérésìmesì. Àwọn míràn tún ṣe ayẹyẹ yìí ní ọjọ́ kerinlelogun oṣù Kejìlá(Dec 24).[2][7][8]

Ìtàn Kérésìmesì sọ nípa àkọlé majẹmu titun inú Bíbélì, tí ó sọ nípa ibí Jesu nínú Bethlehem láti mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa ibi rẹ̀ ṣe. [9].

Nígbà tí Jósẹ́fù àti Maria ìyá Jesu wọ ìlú náà, ilé ibùsùn tí wón wò kò ní ìyára, èyí mú kí wón fi ibùjẹ ẹran lọ̀ wọ́n, ilé ibuje ẹran yìí ni a bí Jesu sí, àwọn áńgẹ́lì sì kéde ibí rẹ̀ fún àwọn oluso àgùntàn, tí àwọn Olùṣọ́ àgùntàn náà sì fi ọ̀rọ̀ nípa ibí rẹ̀ lédè. Gẹ́gẹ́ ìtàn Bíbélì, a bí Jésù nígbà isejoba Herod the Great. Ìtàn ìhìn rere Luku sọ nípa bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe fi Nazareti(ìlú wọn) kalẹ tí wón sì wá sí Bethlehemu láti wá san owó orí. Wọ́n pẹ́ kí wọ́n tó dé Bethlehemu, ìgbà tí wón sì dé ìbè, kò sí àyè mó ní ilé igbalejo. Wọ́n fi ilé ibùjẹ ẹran lọ̀ wọ́n, wọ́n sì kalè síbè, àìpé rẹ̀ ni wọ́n bí Jesu.

Àbá oríṣiríṣi ni ó wà nípa ijọ́ tí a bí Jesu, lẹ́yìn bi ọdún ọgọrun mẹ́rin tí wón bí Jésù, àwọn ìjọ pinu láti fi ọjọ́(ayẹyẹ) náà sí Dec 25. Nígbà tí oyún Èlísábẹ́tì pé oṣù mẹ́fà, Grabrieli farahàn Maria, ó sì sọ fún pé yó lóyún. Nkan pàtàkì láti mọ̀ ni pé kì í ṣe gbogbo ìjọ àkókó ni ó fọwọ́ si fífi ọjọ́ Kàrún lélógún oṣù Kejìlá ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì.

Ọ tún le ka èyí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Christmas as a Multi-faith Festival—BBC News. Retrieved September 30, 2008.
  2. 2.0 2.1 "In the U.S., Christmas Not Just for Christians". Gallup, Inc. December 24, 2008. Retrieved December 16, 2012. 
  3. Gwynne, Paul (2011). World Religions in Practice. John Wiley & Sons. ISBN 978-1-44436005-9. https://books.google.com/?id=tdsRKc_knZoC&pg=RA5-PT130. 
  4. Ramzy, John. "The Glorious Feast of Nativity: 7 January? 29 Kiahk? 25 December?". Coptic Orthodox Church Network. Retrieved January 17, 2011. 
  5. Kelly, Joseph F (2010). The Feast of Christmas. Liturgical Press. ISBN 978-0-8146-3932-0. https://books.google.com/?id=EDO5bcaMvUIC&pg=PT27. 
  6. Jansezian, Nicole. "10 things to do over Christmas in the Holy Land". The Jerusalem Post. http://www.jpost.com/Travel/Around-Israel/10-things-to-do-over-Christmas-in-the-Holy-Land. "...the Armenians in Jerusalem – and only in Jerusalem – celebrate Christmas on January 19..." 
  7. "The Global Religious Landscape | Christians". Pew Research Center. December 18, 2012. Archived from the original on March 10, 2015. Retrieved May 23, 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. "Christmas Strongly Religious For Half in U.S. Who Celebrate It". Gallup, Inc. December 24, 2010. Archived from the original on December 7, 2012. Retrieved December 16, 2012. 
  9. Crump, William D. (September 15, 2001). The Christmas Encyclopedia (3 ed.). McFarland. p. 39. ISBN 978-0-7864-6827-0. https://archive.org/details/christmasencyclo00will. "àwọn Kristẹni gbàgbọ́ pé àwọn ẹsẹ Bibeli kọ̀kan jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ibí Jesu Kristi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹsẹ Bibeli yí wà nínú Majẹmu láíláí ... a bi ni Bethlehemu (Micah 5:2): "Ati iwọ Betlehemu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹ̀run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tọ̀ mi wá; ijade lọ rẹ̀ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye.""