Jump to content

Yaba Bus Terminal

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Yaba Bus Terminal wà ní ọ̀nà Murtala Mohammed Way, Agbègbè Ìdàgbàsókè Yaba tí a mọ̀ sí Local Council Development Area ní Lagos Mainland, ibìkan lára Ìpínlẹ̀ Èkó ní Ilẹ̀ Nàìjíríà.[1][2] Yaba jẹ́ ìgbèríko tó wà ní òkè ńlá tí a mọ̀ sí "Mainland" ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ó ti di ibi ìṣòwò, gbígbé ènìyàn nípasẹ̀ ọkọ̀, ètò ẹ̀kọ́ àti ibùdó eré ìdárayá. Yaba di ibùdó fún oríṣiríṣi àwọn iṣẹ́ ìṣòwò, èyítí ó jẹ́ kí ó di apá kan lára Ètò Ọkọ̀ ti Ìpínlẹ̀ Èkó.[3]

Ọdún 2021 ni wọ́n ṣe ìfilọlẹ̀ rẹ̀ àti pé a kọ́ọ nípasẹ̀ Aláṣẹ Ọkọ̀ Agbègbè Ìlú Èkó tí a ń pè ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Lagos Metropolitan Area Transport Authority (LAMATA),[4] àti ìdásílẹ̀ ṣíṣí rẹ̀ ní gbangba wáyé nípasẹ̀ Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Babajide Sanwo-Olu gẹ́gẹ́ bí apá kan ti ètò gbígbé ńlá kan.[5][6][7] A ṣe àpèjúwe èbúté ọkọ̀ akérò náà bí ètò ohun Ìgbàlódé kan.[1]

Ibùsọ̀ ètò ọkọ̀ ni a ṣe pẹ̀lú ìkójọpọ̀ àti ibi ìtúsílẹ̀ ìkójọpọ̀ fún bíi àárun-dín-lógún midi àti àwọn ọkọ̀ akérò agbára gíga mẹ́rin fún àkókò ìkójọpọ̀ kan, ó rọrùn fún àwọn ọkọ̀ akérò agbára gíga ogún. Ó ní ìgbọ́nsẹ̀, ìtọ́jú omi tí ó dúró sí bìkan, àdaṣe agbègbè, mọ̀nàmọ́ná.[8]

Olúpilẹ́ṣẹ̀ 200KVA àti olùyípadà 500KVA ti wà ní ibùdó ní èbúté ọkọ̀ láti pèsè agbára. Ètò ìṣàkóso ọ̀nà òpópónà wà tí a ń pè ní Traffic System Management (TSM), ọ̀nà tí ó ṣé rìn fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀.

A ṣe ìtumọ̀ ibùsọ̀ ọkọ̀ yìí pẹ̀lú ilé ìṣàkóso kan tí ó ní yàrá ìṣàkóso, ìgbìmọ̀ ìfihàn àlàyé èrò-ọkọ̀, àwọn ọ́fíìsì, àwọn ilé ìtàjà ìṣòwò, ààyè ATM kan, ẹyọ tíkẹ́tì kan, agbègbè ìjóko, agbègbè ilé oúnjẹ pẹ̀lú ibi ìdáná oúnjẹ àti rọgbọkú ìdádúró lórí ilẹ̀ àkọ́kọ́.[9]

Àwọn Ọ̀nà Tó Lọ Sí Yaba[10]

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Lawanson - Itire
  • Ijesha - Cele
  • Iyana- Ipaja
  • Ikeja
  • Berger
  • Oyingbo
  • Akoka

Àwọn Ìtọ́ka Sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "Intermodal transportation: Sanwo-Olu inaugurates ultra-modern Yaba Bus Terminal". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-15. Retrieved 2021-12-14. 
  2. "Sanwo-Olu inaugurates Yaba Bus Terminal" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-15. Retrieved 2021-12-17. 
  3. "Intermodal transportation: Sanwo-Olu inaugurates ultra-modern Yaba Bus Terminal". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-15. Retrieved 2021-12-17. 
  4. "Lagos Govt Commissions Yaba Bus Terminal, Four Years After Project Conception". Channels Television. Retrieved 2021-12-17. 
  5. "Excitement in Lagos as new Yaba bus terminal opens". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-17. Archived from the original on 2021-12-14. Retrieved 2021-12-14. 
  6. "Sanwo-Olu inaugurates Yaba Bus Terminal" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-15. Retrieved 2021-12-14. 
  7. "Yaba terminal, our vision for regulated bus services – Sanwo-Olu". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-15. Retrieved 2021-12-14. 
  8. "Lagos Govt Commissions Yaba Bus Terminal, Four Years After Project Conception". Channels Television. Retrieved 2021-12-17. 
  9. "Excitement in Lagos as new Yaba bus terminal opens". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-17. Archived from the original on 2021-12-14. Retrieved 2021-12-17. 
  10. "Intermodal transportation: Sanwo-Olu inaugurates ultra-modern Yaba Bus Terminal". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-15. Retrieved 2021-12-17.