Zangbetọ

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Zangbetọ (Benin).
Zangbetọ (2020).

Zangbeto jẹ́ Òrìṣà àwọn ẹ̀yà Ògù ní Àgbádárìgì tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Badagry, tí wọ́n gbàgbọ́ pé ìran Yorùbá, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṢẸ̀ wá láti orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin àti orílẹ̀-èdè Togo. Zángbétọ́ lè jade nígbà kúgbàà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ọdún Òrìsà tàbí aỵẹyẹ ìbílẹ̀. ‘Zangbetọ’ jẹ́ Òrìsà tó mò n pa idán ní ọjọ́ ayẹyẹ láti yẹ́ àwọn ènìyàn sì. ‘Zangbetọ’ sì tún jẹ ààbò fún ìlú kí àwọn ọlọ́sà máa ba wọ̀lú ní òru. Tí ọ̀rọ̀ kan bá sí se pàtàkì, ‘Zangbetọ’ kan náà ni wọn yóò ran láti lọ jẹ́ irú isẹ́ bẹ́è. Tí ẹnìkan bà sì sẹ̀ tàbí lódí sí ofin ìlú, àrokò ‘Zangbetọ’ ni wọn yóò fí síwájú ilé e rẹ̀. Ẹníkẹ́ni tí wọ́n bá sì fi irú àrokò yìí síwájú ilé rẹ̀ yóò ní láti dé aàfin Ọba kí ó sì san ohun kóhun tí wọn bá ni kò san ki ó to lè wo ilé rẹ̀. Àgbálo gbábọ̀ ọ̀rọ̀ nii ni pé àwọn ẹ̀sìn àtọ̀hunrìnwá wà ṣùgbọ́n ẹ̀sìn àbáláyé kò lè parun, nítorí pe, gbogbo àwọn Òrìsà wọ̀nyí ṣì wà síbẹ̀.[1] [2]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. France-Presse, Agence (2018-05-27). "Zangbeto: Voodoo Savior of Benin's Mangroves - Voice of America". Voice of America. Retrieved 2019-11-30. 
  2. "Benin. Dancing with the spirits". News & views from emerging countries. Archived from the original on 2019-08-18. Retrieved 2019-11-30.