Àgídìgbo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àgídìgbo jẹ́ ohun èlò orin ìbílẹ̀ tí ìrísí rẹ̀ dàbí dùrù (Piano) àwọn Gẹ̀ẹ́sì àwọn Yorùbá tí wọ́n ma ń fi okùn sí láti lè gbe kọ́rùn fún lílù. Lásìkò tí wọ́n bá fẹ̀ dára wọn lára yá. Alágìídìgbo náà yóò wọ òrùka tó lúpọn, ọrùn ìṣà tábí ìgò sọ́wọ́ àtànpàkò rẹ̀, eyí tí yóò fi ma kan ẹ̀gbẹ pátákó àgídìgbo náà. Yóò sì tún ma fi ọwọ́ mẹ́wẹ̀wá rẹ̀ ta àwọn ìtàkùn ahọ́n irin tí wọ́n ti so mọ́ àpótí àgídìgbo náà lẹ́sẹẹsẹ, tí ìyẹn náà yóò sì ma mu óhùn àdídùn jáde. Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni wọ́n fi ma ń gbe àgídìgbo lẹ́sẹ̀ lójú aré. [1]

Irúfẹ́ Orin tí ó ń lo Àgídìgbo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ma ń lo àgídìgbo nínú orin Wákà tàbí Àpàlà. Bákan náà ni àgídìgbo jẹ́ gbajú gbajà khun èlò orin ní àwọn agbègbè bíi Ìbàdàn, Ìjẹ̀bú. Babatunde Yusuf Olátúnjí, ni ẹni tójẹ́ ìlú-mọ̀ọ́ka olórin tó ma ń lo àgídìgbo nínú orin rẹ̀, pàá pàá jùlọ nínú àwo rẹ̀ tí ó péní "Oyin Mọmọ Àdò" (Sweet as Honey), tí fọ́nrán rẹ̀ sì jẹ́ ẹlẹ́keeje (track 7) ní ọdún 1959.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Utilisateur, Super (2018-02-22). "PhD Oral Examination, Thursday, 22 Feb 2018". Institute of African Studies of Ibadan. Archived from the original on 2020-10-19. Retrieved 2019-03-14.