Àjàkálẹ̀ àrùn Nipha

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àjàkálẹ̀ àrùn Nipha

Àjàkálẹ̀ àrùn Nipha jẹ́ àrùn kan tó jákè jáko ní kòkò àìfojúrí Nipha ń ṣokùfà rẹ̀.[1] Àrùn yí ma ń fojú han lára ẹni tí ó ba ko nípa kí ẹni náà ó ní àìsàn Ibà,Ikọ́, Orí fífọ́, Àìlè mí Kanlẹ̀ àti Iye méjì [2][1] Èyí tún lè mú kí alásìn yí ó dákú lọ gbọnrangandan.

Ohun tí ó ń ṣokùnfà àrùn yí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kòkòrò àrùn Nípha ni ó jẹ́ ọ̀kan nínú ẹbí kòkòrò tí Ẹnipafírọ́ọ́sì tí má ń gbe nínú ẹjẹ̀ ohun abẹ̀mí.[1] Kòkòrò arùn àìfojúrí yí ni ó a lè kó nípa jíjẹ lalára èso tí ẹyẹ Àdán bá ti fẹnu bà. Ẹ̀wẹ̀, àrùn yí lè tàn kálẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ọmọnìyàn sí ọmọnìyàn tàbi ẹranko sí eranko, bákan náà láti ọ̀dọ̀ ẹranko sí ènìyà àti ènìyàn sí ẹranko nígbà tí a bá ní ìfaragbà yálà èémí, ẹ̀jẹ̀, sínsín ẹni tí ó àrùn yí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ .[3] Ìṣèwádí àrùn yí lò m ń dá lè orí ììfiléde ìwádí tí ó bá jáde láti iyàrá ayàfiẹ̀wò jáde.[4]

Ṣiṣẹ́ Ìwòsàn àti ọ̀nà ìpèsè Oògùn rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Títọ́jú aláìsàn tí ó ní àrùn Nipha ni pípèsè ìtọ́jú tó péye. Ní àsìkò ọdún 2018, kòì tíì sí Oògùn kan pàtó fún ìtọ́jú àrùn náà. Àmọ́, ṣíṣọ́ra-ẹni nípa sísúnmọ́ ẹyẹ àdán, Ẹlẹ́dẹ̀ àti kí a má jẹ dàbínù tútù ni ọ̀nà kan pàtàkì tí a fi lè ṣọ́ ara wa kúrò níbi ìkọlù àrùn náà. [5] Àwọn tí wọ́n kò àrùn Nípa ni ọdún 2018 ń lọ sí nkan bí ọgọ́ta ó lè mẹ́wàá tí ìdá 75 nínú àwọn wọ̀nyí sì dèrò ọ̀run.[6][7][8] Ní inú oṣù Karùn ún ọdú 2018, yí kan náà, àwọn .ẹ́tàdínlógún ni wọ́n gbèkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbora ní Ìpínlẹ̀ Ke ra la ní orílẹ̀-èdè India. [9][10][11]

Ìtàn bí àjàkálẹ̀ àrùn yí ṣe bẹ̀rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n kọ́kọ́ kẹ́fín sí àrùn yí ní ọdún 1988, nígbà tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Malaysia, tí wọ́n sì àmúpamọ́ rẹ̀ ní ọdún 1999. [1][12].[12] [1][12]

Àwọn àmì tí a fi lè mọ ẹni tí ó bá ní àrùn Nipha[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìnlá tí aláìsàn bá ti lùgbàdì àrùn yí ni yóò ma bẹ̀rẹ̀ sí ní àìsàn Ibà, orí- fífọ́, ìṣe iyè méjì àti sise ségesège ọpọlọ aláìsàn náà. Àwọn àmì yí lè sun síwájú kí ó sì di ara wíwú, tí ó sì lè fa kí ọpọlọ ẹni náà ó pajúdé. Èyí ni àmì tó búrú jùlọ tí àrùn Nípa ń fún ni. Ẹ̀wẹ̀, aláìsà náà tún lè ma kojú ìṣòro níbi ọ̀rọ̀ sísọ, àti àwọ ibi kọ́lọ́fín ara. [12] Àwọn aláìsàn tí wọ́n ní kòkòrò àrùn Nipha tí wọn kò lè má kanlẹ̀ ni wọ́n ní ànfàní àti kò àrùn náà bá èlò mìíràn kíá kíá.[13][14]

Àwọn ewu rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn òṣìṣẹ́ ilé Ìwòsàn ni wọ́n ní wà ní ipò ewu jùlọ nítorí wípé àwọn ni wọ́n ń ṣètọ́jú àwọn aláìsàn fúndí èyí, ó ṣeé ṣe kí wọ́n tètè kò àrùn yí lára àwọn aláìsàn tí wọ́n ń tọ́jú.[15][16]

Dídẹ́kun Àjàkálẹ̀ àrùn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìdẹ́kun àjàkálẹ̀ àrùn Nipha ni ó ṣe pàtàkì jùlọ nígbà tí kò tíì sí Oògùn tí a lè fi dẹ́kun àrùn náà. Láti ṣe èyí, a gbọ́dọ̀ yálà fún jíjẹ àwọn èso èyíkéyí tí ẹyẹ bá ti jẹ, kí á yẹra fún sísúnmọ̀ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ àti lílọ sí àyè tí àrùn yí bá ti wà. Kíkó àwọn ohun jíjẹ sínú àpò ìpamọ́ tí ó lè dáàbò bò àwọn ohun jíjẹ wa. Ṣíṣe ìfiléde nípa àjàkálẹ̀ àrùn yí kí a lè dẹ́kun ìtànkálẹ̀ rẹ̀.

,[18] [19] [18].[20]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 "WHO Nipah Virus (NiV) Infection". www.who.int. Archived from the original on 18 April 2018. Retrieved 21 May 2018.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Signs and Symptoms Nipah Virus (NiV)". CDC (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 24 May 2018. 
  3. "Transmission Nipah Virus (NiV)". CDC (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 20 March 2014. Retrieved 24 May 2018. 
  4. "Diagnosis Nipah Virus (NiV)". CDC (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 20 March 2014. Retrieved 24 May 2018. 
  5. "Prevention Nipah Virus (NiV)". CDC (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 20 March 2014. Retrieved 24 May 2018. 
  6. "A treatment for and vaccine against the deadly Hendra and Nipah viruses". Antiviral Research 100 (1): 8–13. October 2013. doi:10.1016/j.antiviral.2013.06.012. PMC 4418552. PMID 23838047. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=4418552. 
  7. "Nipah virus outbreaks in the WHO South-East Asia Region". South-East Asia Regional Office. WHO. Retrieved 23 May 2018. 
  8. "Morbidity and mortality due to Nipah or Nipah-like virus encephalitis in WHO South-East Asia Region, 2001-2018" (PDF). SEAR. Retrieved 2 June 2018. 112 cases since Oct 2013 
  9. CNN, Manveena Suri (22 May 2018). "10 confirmed dead from Nipah virus outbreak in India". CNN. https://www.cnn.com/2018/05/22/health/nipah-virus-death-toll-rises-intl/index.html. 
  10. "Nipah virus outbreak: Death toll rises to 14 in Kerala, two more cases identified". Hindustan Times. 27 May 2018. Retrieved 28 May 2018. 
  11. "After the outbreak" (in en). Frontline. https://www.frontline.in/the-nation/public-health/article24200872.ece. 
  12. 12.0 12.1 12.2 12.3 "Nipah Virus (NiV) CDC". www.cdc.gov (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). CDC. Archived from the original on 16 December 2017. Retrieved 21 May 2018.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  13. "Recurrent zoonotic transmission of Nipah virus into humans, Bangladesh, 2001-2007". Emerging Infectious Diseases 15 (8): 1229–35. August 2009. doi:10.3201/eid1508.081237. PMC 2815955. PMID 19751584. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=2815955. 
  14. "Transmission of Nipah Virus - 14 Years of Investigations in Bangladesh". The New England Journal of Medicine 380 (19): 1804–1814. May 2019. doi:10.1056/NEJMoa1805376. PMC 6547369. PMID 31067370. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=6547369. 
  15. Luby, Stephen P.; Gurley, Emily S.; Hossain, M. Jahangir (2012). Transmission of Human Infection with Nipah Virus. National Academies Press (US). https://www.ncbi.nlm.nih.gov/books/NBK114486/. Retrieved 21 May 2018. 
  16. Balan, Sarita (21 May 2018). "6 Nipah virus deaths in Kerala: Bat-infested house well of first victims sealed". The News Minute. https://www.thenewsminute.com/article/6-nipah-virus-deaths-kerala-bat-infested-house-well-first-victims-sealed-81650. 
  17. "Nipah Virus Infection symptoms, causes, treatment, medicine, prevention, diagnosis". myUpchar. Retrieved 27 January 2020. 
  18. 18.0 18.1 "Nipah Virus Transmission from Bats to Humans Associated with Drinking Traditional Liquor Made from Date Palm Sap, Bangladesh, 2011-2014" (in en-us). Emerging Infectious Diseases 22 (4): 664–70. April 2016. doi:10.3201/eid2204.151747. PMC 4806957. PMID 26981928. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=4806957. 
  19. Balan, Sarita (21 May 2018). "6 Nipah virus deaths in Kerala: Bat-infested house well of first victims sealed". The News Minute. https://www.thenewsminute.com/article/6-nipah-virus-deaths-kerala-bat-infested-house-well-first-victims-sealed-81650. 
  20. "A Hendra virus G glycoprotein subunit vaccine protects African green monkeys from Nipah virus challenge". Science Translational Medicine 4 (146): 146ra107. August 2012. doi:10.1126/scitranslmed.3004241. PMC 3516289. PMID 22875827. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3516289.