Jump to content

Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B
Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ BElectron micrograph of hepatitis B virus
Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ BElectron micrograph of hepatitis B virus
Electron micrograph of hepatitis B virus
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B16.,
B18.0B18.1 B16.,
B18.0B18.1
ICD/CIM-9070.2070.3 070.2070.3
OMIM610424
DiseasesDB5765
MedlinePlus000279

Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B jẹ́ àjẹsára tí a fi ń dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B.[1] Ọmọ tuntun a maa gba àkọ́kọ́ abẹ́rẹ́ Àjẹsára yíi láàrín wákàtí mẹ́rìndínlógún tí wọ́n bíi àti abẹ́rẹ́ yíi méjì tàbí méta lẹ́yìn ìgbà náà. Èyí pẹ̀lú àwon tí ara wọn kò ní anfààní púpọ̀ lati dojú kọ àrùn, bi àwon tí ó ní àrùn kògbóògùn HIV/AIDS tàbi àwon tí wọ́n bí lọ́jọ́ àìpé. Lílo Àjẹsára yíi déédéé máa n dáàbò bo èèyàn márùndínlọ́gọ́rú nínú ọgọ́rún èèyàn tí kò ní àrùn.[1]

Ṣíṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ lati ríi dájú wípé Àjẹsára yíi ṣiṣẹ́ jẹ́ ohun tí ó ṣe kókó fún àwon tí ó ní anfààní jùlọ lati ní àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B. Àfikún abẹ́rẹ́ Àjẹsára yíi lè wúlò fún àwon tí ara wọn kò ní anfààní púpọ̀ lati dojú kọ àrùn ṣùgbọ́n kò pọn dandan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èniyàn. Àwon tí ó ti kó àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B ṣùgbọ́n tí wọn kò gba abẹ́rẹ́ Àjẹsára yíi gbúdọ̀ gbàá pẹ̀lú àjẹsára tí àwon òyìnbó ń pè ní "hepatitis B immune globulin". Inú iṣan ni wọ́n máa ń gba abẹ́rẹ́ Àjẹsára yíi tí á fi dè inú ara.[1]

Ewu nípa lílo Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B ò wọ́pọ̀. Ìrora lè wáyé níbi tí a gba abẹ́rẹ́ sí. lílo Àjẹsára yíi kò léwu nígbà oyún àti nìgba fífún ọmọ lọ́yàn. Kò ní ìbáṣepọ̀ tí ó dájú pẹ̀lú Guilain-Barre syndrome. Wọ́n pèlo Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B tí ó wà bayí nípa ọ̀nà tàbí ọgbọ́n recombinant DNA. Wọ́n dáwà tàbí pẹ̀lú àwon Àjẹsára míràn.[1]

Wọ́n fọwọ́sí Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ United States ní odún 1981.[2] Èyí tí kò léwu púpọ̀ di títà ní odún 1986.[1] Ó jẹ́ ìkan lára àwon oògún tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣàkójọ ẹ̀ sí oògún tó wúlò jùlọ fún ìlera.[3] Ní bíi 2014, òṣùwọ̀n owó rẹ̀ lójú pálí kúsí US$ 0.58–13.20 fún abẹ́rẹ́ kan.[4] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, iye owó rẹ̀ kúsí US$50–100.[5]

Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B.

Ọmọ tuntun tí ìyá tó bá ní àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B bá bí a máa gba abẹ́rẹ́ àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B pẹ̀lú imunogulobulínì.[6] Báyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè a màa gba abẹ́rẹ́ àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B fún àwon ọmọ ìkókó lati dènàn àìsàn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B. Ní àwon orílẹ̀ èdè tí ó ní anfààní jùlọ lati ní àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B, gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára yí fún ọmọ tuntun ti dínkù àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B àti àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀. Wọ́n fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ilẹ̀ Taiwan, níbi tí wọ́n tí ṣètò gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B kárí gbogbio àgbáyé ní odún 1984 wípé gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà má a ń dín ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn tí wọ́n ń pè ní hepatocellular carcinoma kù láàárìn àwon ọmọdé.[7] Ní ilẹ̀ UK, gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B wà làra àyẹ̀wò Ìbálòpọ̀ tí wọ́n má a ṣe ń fún àwon ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin lòpọ̀ (MSM). Wọ́n ṣe irú ètò yii ní orilẹ̀ ède Ireland.[8]

Ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ agbègèbè, gbígba Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B jẹ́ dandan fún àwon òṣìṣẹ́ ìlera àti fún àwon òṣìṣẹ́ ilé àyẹ̀wò fún ìlera.[9] Ilé ìṣàkoso àti ìdènàn àrùn ti ilẹ̀ United States gbani ní ìmọ̀ràn pé gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B ṣe pàtàkì fún àwon tó ní àrùn àtọ̀gbe melitus.[10]

Natasha Wooden ń gba abẹ́rẹ́ Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B fún ológún ojú omí ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Lẹ́yin àkọ́kọ́ gba àjẹsára yìí lẹ́ẹ̀mẹta, àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ lè tẹ̀le láàárìn oṣù kan sí mẹrin fún àrídájú iṣẹ́ rẹ̀, tí wọ́n ń pè ní ìdènàn àìsàn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B lójú pẹpẹ áńtíjẹ́nì, agbóguntàìsàn tí ó ju 100 mIU/ml lọ. Írú ìdáhun báyìí má ń wáyé láàárìn 85 sí 90% èèyàn.[9] Ìdáhun agbóguntàìsàn tí ó wáyé láàárìn 10 sí 100 mIU/ml jẹ́ ìdáhun tí kò péyé. Àwọn èèyàn tí ìdáhun agbóguntàìsàn wọn bá ń ṣíṣe báyìí má ń gba ohun tí ó má fún agbóguntàìsàn yìí lágbára láìsí ìdí fún àyẹ̀wò ẹ́jẹ́.[9] Àwọn èèyàn tí ìdáhun agbóguntàìsàn wọn ò póṣùwọ̀n (tí ìdáhun agbóguntàìsàn wọn bá kéré sí 10 mIU/ml) gbọ́dọ̀ ṣe àyẹ̀wò jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B, wọn á sí gba abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí lẹ́ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lẹ́yìn abẹ́rẹ́ àjẹsára ẹ̀ẹ̀kejì, àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ á tẹ̀le láàárìn oṣù kan sí mẹrin fún àrídájú iṣẹ́ rẹ̀. Àwọn èèyàn tí ó rí ìyàtọ̀ lẹ́yìn abẹ́rẹ́ àjẹsára ìkejì lè rí ìyàtọ̀ tí wọ́n bá gba àjẹsára yii sára[11] tàbí Àfikún ìdá àjẹsára yii[12] tàbí ìdá meji Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ A àti B.[13] Àwọn èèyàn tí ó pàpà rí ìyàtọ̀ lẹ́yìn èyi á gba hepatitis B immunoglobulin (HBIG) tí wọ́n bá kó àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B lọ́jọ́ wájú.[9]

Àwon ohun tí ó ń ṣe okùnfà ìdáhun agbóguntàìsàn tí ò póṣùwọ̀n ni tí ọjọ́ orí bá ju ogójì, ìsanrajù, àti sìgá mímu,[14] àti ọtí mímu pàápàá bí èèyàn bá ní àrùn ẹ̀dọ̀.[15] Àwon aláìsàn tí adínà àìsàn wọn ò póṣùwọ̀n tàbí tí kíndìrín wọn kò ṣisẹ̀ dáadáa lè ma dáhun si àjẹsára dáadáa, Fífún wọn ní àjẹsára déédéé tàtí àfikún ìdá àjẹsára yii lè ṣe wón láànfàní.[9] Ókéré jù, ìwádí kan fihàn pé iṣẹ́ Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B kò péye fún àwon tí ó ní àrùn kògbóògùn HIV.[16]

Iye àkókò ìdáàbòbò

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Airman Sandra Valdovinos, lati Delano, Calif. ń gba abẹ́rẹ́ Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B fún Airman Adam Helton, lati Mesa, Ariz..

Báyìí, ìgbàgbọ́ ti wà pé iye àkókò ìdáàbòbò Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B kò lópin. Síbẹ̀síbẹ̀, tẹ́lẹ̀ ìgbàgbó wà pé iye àkókò tí Àjẹsára jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ B lè ṣe ìdáàbòbò mọ kò ju bí ọdún máàrún sí méje.[17][18]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 "Hepatitis B vaccines WHO position paper". Weekly epidemiological record 40 (84): 405–420. 2 Oct 2009. http://www.who.int/wer/2009/wer8440.pdf. 
  2. Moticka, Edward. A Historical Perspective on Evidence-Based Immunology. p. 336. ISBN 9780123983756. https://books.google.ca/books?id=2TMwAAAAQBAJ&pg=PA336. 
  3. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF). World Health Organization. October 2013. Retrieved 22 April 2014. 
  4. "Vaccine, Hepatitis B". International Drug Price Indicator Guide. Retrieved 6 December 2015. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  5. Hamilton, Richart (2015). Tarascon Pocket Pharmacopoeia 2015 Deluxe Lab-Coat Edition. Jones & Bartlett Learning. p. 314. ISBN 9781284057560. 
  6. Mast, E. E.; Margolis, H. S.; Fiore, A. E.; Brink, E. W.; Goldstein, S. T.; Wang, S. A.; Moyer, L. A.; Bell, B. P. et al. (2005). "A comprehensive immunization strategy to eliminate transmission of hepatitis B virus infection in the United States: recommendations of the Advisory Committee on Immunization Practices (ACIP) part 1: immunization of infants, children, and adolescents" (Free full text). MMWR. Recommendations and reports : Morbidity and mortality weekly report. Recommendations and reports / Centers for Disease Control 54 (RR–16): 1–31. PMID 16371945. http://www.cdc.gov/mmwr/PDF/rr/rr5416.pdf. 
  7. Chang, M. -H.; Chen, C. -J.; Lai, M. -S.; Hsu, H. -M.; Wu, T. -C.; Kong, M. -S.; Liang, D. -C.; Shau, W. -Y. et al. (1997). "Universal Hepatitis B Vaccination in Taiwan and the Incidence of Hepatocellular Carcinoma in Children". New England Journal of Medicine 336 (26): 1855–1859. doi:10.1056/NEJM199706263362602. PMID 9197213. 
  8. "Hepatitis B vaccine". www.nhs.uk. 
  9. 9.0 9.1 9.2 9.3 9.4 Joint Committee on Vaccination and Immunisation (2006). "Chapter 12 Immunisation of healthcare and laboratory staff—Hepatitis B" (PDF). Immunisation Against Infectious Disease 2006 ("The Green Book") (3rd ed.). Edinburgh: Stationery Office. pp. 468. ISBN 0-11-322528-8. Archived from the original on 2013-01-07. http://www.dh.gov.uk/en/Publichealth/Healthprotection/Immunisation/Greenbook/DH_4097254?IdcService=GET_FILE&dID=115800&Rendition=Web. Retrieved 2016-05-20. 
  10. Centers for Disease Control and Prevention (CDC) (2011). "Use of hepatitis B vaccination for adults with diabetes mellitus: recommendations of the Advisory Committee on Immunization Practices (ACIP).". MMWR Morb Mortal Wkly Rep 60 (50): 1709–11. PMID 22189894. http://www.ncbi.nlm.nih.gov/entrez/eutils/elink.fcgi?dbfrom=pubmed&tool=sumsearch.org/cite&retmode=ref&cmd=prlinks&id=22189894. 
  11. King; Taylor, E. M.; Crow, S. D.; White, M. C.; Todd, J. R.; Poe, M. B.; Conrad, S. A.; Gelder, F. B. (1990). "Comparison of the immunogenicity of hepatitis B vaccine administered intradermally and intramuscularly". Reviews of infectious diseases 12 (6): 1035–1043. doi:10.1093/clinids/12.6.1035. PMID 2148433. 
  12. Levitz; Cooper, B.; Regan, H. (1995). "Immunization with high-dose intradermal recombinant hepatitis B vaccine in healthcare workers who failed to respond to intramuscular vaccination". Infection control and hospital epidemiology : the official journal of the Society of Hospital Epidemiologists of America 16 (2): 88–91. doi:10.1086/647062. PMID 7759824. 
  13. Cardell, K.; Åkerlind, B.; Sällberg, M.; Frydén, A. (2008). "Excellent Response Rate to a Double Dose of the Combined Hepatitis a and B Vaccine in Previous Nonresponders to Hepatitis B Vaccine". The Journal of Infectious Diseases 198 (3): 299–226. doi:10.1086/589722. PMID 18544037. 
  14. Roome, A. J.; Walsh, S.; Cartter, M.; Hadler, J. (1993). "Hepatitis B vaccine responsiveness in Connecticut public safety personnel". Journal of the American Medical Association 270 (24): 2931–2934. doi:10.1001/jama.270.24.2931. PMID 8254852. 
  15. Rosman, Md, A.; Basu, P.; Galvin, K.; Lieber, C. (1997). "Efficacy of a High and Accelerated Dose of Hepatitis B Vaccine in Alcoholic Patients a Randomized Clinical Trial". The American Journal of Medicine 103 (3): 217–222. doi:10.1016/S0002-9343(97)00132-0. PMID 9316554. 
  16. Pasricha, N.; Datta, U.; Chawla, Y.; Singh, S.; Arora, S.; Sud, A.; Minz, R.; Saikia, B. et al. (2006). "Immune responses in patients with HIV infection after vaccination with recombinant Hepatitis B virus vaccine". BMC Infectious Diseases 6: 65. doi:10.1186/1471-2334-6-65. PMC 1525180. PMID 16571140. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=1525180.  Cold or Flu like symptoms can develop after receiving the vaccine, but these are short lived. As with any injection, the muscle can become tender around the injection point for some time afterwards
  17. Krugman; Davidson, M. (1987). "Hepatitis B vaccine: prospects for duration of immunity". The Yale journal of biology and medicine 60 (4): 333–339. PMC 2590237. PMID 3660859. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=2590237. 
  18. Petersen, K. M.; Bulkow, L. R.; McMahon, B. J.; Zanis, C.; Getty, M.; Peters, H.; Parkinson, A. J. (2004). "Duration of Hepatitis B Immunity in Low Risk Children Receiving Hepatitis B Vaccinations from Birth" (Free full text). The Pediatric Infectious Disease Journal 23 (7): 650–655. doi:10.1097/01.inf.0000130952.96259.fd. PMID 15247604. http://www.medscape.com/viewarticle/483473.