Jump to content

Àjẹsára rotavirus

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
H. Fred Clark àti Paul Offit, tí wọ́n ṣe àwárí RotaTeq.

Àjẹsára rotavirus jẹ́ àjẹsára tí a fi ń dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn kan tí à ń pè ní rotavirus.[1] Àwọn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn wọ̀nyí ló má a ń sábà ṣe òkùnfà ìgbẹ́ gbuuru tó lágbára púpọ̀ láàárín àwọn ọmọdé.[1] Àjẹsára náà a má a dènà ìwọ̀n 15 sí 34% ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbẹ́ gbuuru tó lágbára púpọ̀ náà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣì ń tẹ̀síwájú, àti ìwọ̀n 37 sí 96% ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbẹ́ gbuuru tó lágbára púpọ̀ náà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ní ìtẹ̀síwájú.[2] Àjẹsára náà dàbí èyí tó má a ń dín ewu ikú tó ti ipasẹ̀ ìgbẹ́ gbuuru wáyé kù láàárín àwọn ọmọdé.[1] Fífún àwọn ọmọ-ọwọ́ ní àjẹsára náà dàbí ohun tó má a ń dín ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà kù láàárìn àwọn àgbàlagbà àti láàárín àwọn tí kò tíì gba àjẹsára náà tẹ́lẹ̀ rí.[3]

Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gbani nímọ̀ràn pé kí àjẹsára rotavirus jẹ́ ara àwọn àjẹsára tí à ń gbà lóòrèkóòrè, pàápàá júlọ ní àwọn agbègbè ibi tí àrùn náà ti wọ́pọ̀. A gbọ́dọ̀ ṣe èyí ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú gbígbé àwọn ohun bíi fífún ọmọ lọ́yàn, fífọ ọwọ́ ẹni, àti lílo omi tó mọ́ àti ìmọ́tótó lárugẹ. Ẹnu ni a ń gbà fúnni ní àjẹsára náà, ènìyàn sì nílò ìwọ̀n egbògi náà méjì sí mẹta. A gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fúnni láti ìgbà tí ènìyàn bá ti tó ọmọ ọ̀sẹ̀ mẹ́fà.[1]

Lílò àjẹsára náà kò léwu. Èyí kan lílò fún àwọn tó ní àrùn kògbóògùn HIV/AIDS pàápàá. Ẹ̀yà ìṣáájú àjẹsára náà níí ṣe pẹ̀lú lílọ́pọ̀ ìfun, ṣùgbọ́n ẹ̀yà titun rẹ̀ ní báyìí kò tíì ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú èyí dájúdájú. Nítorí ewu tó lè wáyé, a kò gbani nímọ̀ràn láti lòó fún àwọn ọmọ-ọwọ́ tí ìfun wọn ti lọ́ pọ̀ rí. A ṣe àgbéjáde àwọn àjẹsára náà nípasẹ̀ kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn rotavirus tí a ti sọ di aláìlágbára.[1]

Àjẹsára náà di èyí tó wà fún lílò ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 2006.[4] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[5] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ bíi 6.96 sí 20.66 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[6] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ ju 200 USD lọ.[7] Dí ọdún 2013 oríṣi àjẹsára náà méjì ni ó wà káàkiri àgbáyé, Rotarix àti RotaTeq, pẹ̀lú àwọn oríṣi díẹ̀ mìíràn tó tún wà ní àwọn orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan.[1]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 "Rotavirus vaccines. WHO position paper – January 2013.". Releve epidemiologique hebdomadaire / Section d'hygiene du Secretariat de la Societe des Nations = Weekly epidemiological record / Health Section of the Secretariat of the League of Nations 88 (5): 49-64. 1 February 2013. PMID 23424730. http://www.who.int/wer/2013/wer8805.pdf?ua=1. 
  2. Soares-Weiser, Karla, ed (2012). "Vaccines for preventing rotavirus diarrhoea: vaccines in use". Cochrane Database Syst Rev 11: CD008521. doi:10.1002/14651858.CD008521.pub3. PMID 23152260. 
  3. Patel MM, Steele D, Gentsch JR, Wecker J, Glass RI, Parashar UD (January 2011). "Real-world impact of rotavirus vaccination". Pediatr. Infect. Dis. J. 30 (1 Suppl): S1–5. doi:10.1097/INF.0b013e3181fefa1f. PMID 21183833. 
  4. "Rotavirus Vaccine Live Oral". The American Society of Health-System Pharmacists. Retrieved Dec 14, 2015. 
  5. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF). World Health Organization. October 2013. Retrieved 22 April 2014. 
  6. "Vaccine, Rotavirus". International Drug Price Indicator Guide. Retrieved 6 December 2015. 
  7. Hamilton, Richart (2015). Tarascon Pocket Pharmacopoeia 2015 Deluxe Lab-Coat Edition. Jones & Bartlett Learning. p. 317. ISBN 9781284057560.