Àrùn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn Ebola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àrùn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn Ebola
Àrùn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn Ebola1976 àwòrán àwọn nọ́ọ̀sì méjì tó dúró síwájú Mayinga N., ẹnití ó ní àrùn kòkòrò àìlèfojúrì afàìsàn Ebola; ó kú lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ sí àsìkò náà nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀ sísun láti inú wá.
Àrùn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn Ebola1976 àwòrán àwọn nọ́ọ̀sì méjì tó dúró síwájú Mayinga N., ẹnití ó ní àrùn kòkòrò àìlèfojúrì afàìsàn Ebola; ó kú lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ sí àsìkò náà nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀ sísun láti inú wá.
1976 àwòrán àwọn nọ́ọ̀sì méjì tó dúró síwájú Mayinga N., ẹnití ó ní àrùn kòkòrò àìlèfojúrì afàìsàn Ebola; ó kú lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ sí àsìkò náà nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀ sísun láti inú wá.
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10A98.4 A98.4
ICD/CIM-9065.8 065.8
DiseasesDB18043
MedlinePlus001339

Àrùn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn Ebola (EVD) tàbí Ibà ẹlẹ́jẹ̀ sísun Ebola (EHF) jẹ́ àrùn ẹ̀dá ènìyàn èyítí Kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn Ebola n ṣe òkùnfa rẹ̀. Àwọn àmì àìsàn náà a má a bẹ̀rẹ̀ lẹyìn ọjọ́ méjì sí ọ̀sẹ̀ mẹta tí ènìyàn bá ṣe aláàbápàdé kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn náà, pẹ̀lú ibà, ọ̀fun dídùn, ìrora nínú iṣan ara, àti orí fífọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti má a nwáyé, inú ríru, èébì, àti ìgbẹ́ gbuuru a má a tẹ̀lẹ́ èyí, pẹ̀lú àìṣedéédé iṣẹ́ ẹ̀dọ̀ àti àwọn kídìnrín. Lásìkò yìí, àwọn ènìyàn kan a má a bẹ̀rẹ̀ sí ní ìṣòro ẹ̀jẹ̀ sísun.[1]

Ènìyàn lè kó kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn náà bí ó bá farakan ẹ̀jẹ̀ tàbí àwọn omi ara ẹranko tó ní àrùn náà (pàápàá jùlọ àwọn ọ̀bọ tàbí àwọn àdán ẹlẹ́nu gígùn pẹ̀lú ojú nlánlá).[1] A kò tíì ṣe àkọsílẹ̀ àtànká àrùn náà nípasẹ̀ afẹ́fẹ́ ní àyíká adánidá.[2] Àdán ẹlẹ́nu gígùn pẹ̀lú ojú nlánlá náà ni a gbàgbọ́ pé ó má a ngbé àrùn náà káàkiri, tí ó sì má a ntàn-án káàkiri láì jẹ́ pé àrùn náà pa òun fúnraararẹ̀ lára. Lọ́gán tí àkóràn àrùn náà bá ti bá ènìyàn kan, àrùn náà lè tàn káàkiri bákan náà láti ara ènìyàn kan sí èkejì. Àwọn ọkùnrin tó bọ́ lọ́wọ́ ewu àrùn náà ṣì lè kó àrùn bá ẹlòmíràn nípasẹ̀ àtọ̀ wọn fún bí oṣù méjì. Láti lè ṣe ìwádìí àrùn náà, àwọn àrùn mìíràn tó ní àmì tó jọ mọ́ èyí bíi akọ ibà, àrùn onígbáméjì kọ́lẹ́rà àti àwọn ibà ẹ̀jẹ̀ sísun lára tó wáyé nípasẹ̀ kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn mìíràn ni a ó ò kọ́kọ́ mú kúrò. Láti lè jẹri sí òtítọ́ àrùn náà, a ó ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a gbà sílẹ̀ fún àwọn èròjà agbóguntàrùn nínú ara tí n dójú ìjà kọ àwọn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn, fún RNA tí n dójú ìjà kọ àwọn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn, tàbí fún kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn náà fúnraarẹ̀.[1]

Bí a ṣe lè dènà àrùn náà ni dídin ìtànkáàkiri rẹ̀ kù láti ara àwọn ọ̀bọ àti ẹlẹ́dẹ̀ tó ti kó àrùn náà sí ara àwọn ènìyàn. A lè ṣe èyí nípa ṣíṣe àyẹ̀wò irú àwọn ẹranko bẹ́ẹ̀ fún àrùn náà, pípa wọ́n, àti sísọ òkú wọn nù ní ọ̀nà tí ó tọ́ bí a bá rí àrùn náà lára wọn. Síse ẹran dáradára àti wíwọ aṣọ tó yẹ láti dáàbòbo ara nígbàtí a bá npa tàbi kun ẹran lè ṣe ìrànwọ́, bákan náà sì ni wíwọ aṣọ tó yẹ láti dáàbòbo ara àti fífọ ọwọ́ nígbàtí a bá wà ní àyíká ibi tí ẹnití ó ní àrùn náà wà. Omi àti ẹran tó jáde láti ara ẹnití ó ní àrùn náà ni a gbọ́dọ̀ gbé tàbí dìmú pẹ̀lú ìṣọ́ra pàtàkì.[1]

Kò sí ìwòsàn kan pàtó fún àrùn náà; lára àwọn akitiyan fún ríran àwọn ẹnití àrùn yìí bá lọ́wọ́ ni fífún wọn ni, yálà àpòpọ̀ omi iyọ̀ àti ṣúgà fún dídá omi tí ara pàdánù padà sínú ara (omi ṣúgà àti iyọ̀ tó dùn díẹ̀ fún mímu) tàbi àwọn omi tí a ngba iṣan ara fún ni.[1] Ìwọ̀n iye ẹniti nkú nípasẹ̀ àrùn náà ga púpọ̀

References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 "Ebola virus disease Fact sheet N°103". World Health Organization. March 2014. Retrieved 12 April 2014. 
  2. "2014 Ebola Virus Disease (EVD) outbreak in West Africa". WHO. Apr 21 2014. Retrieved 3 August 2014.  Check date values in: |date= (help)

External links[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]