Jump to content

Émile Derlin Zinsou

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Émile Derlin Zinsou
Émile Derlin Henri Zinsou
Emile Zinsou
Emile Zinsou
President of Dahomey
In office
17 July 1968 – 10 December 1969
AsíwájúAlphonse Amadou Alley
Arọ́pòIropa Maurice Kouandété
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1918-03-23)23 Oṣù Kẹta 1918
Ouidah, Dahomey
Aláìsí28 July 2016(2016-07-28) (ọmọ ọdún 98)
Cotonou, Benin
(Àwọn) olólùfẹ́Florence Atayi Guy Gaspard
ProfessionPolitician, physician
Signature

Émile Derlin Zinsou tí wọ́n bí ní ejò kẹtalélógú oṣù kẹta ọdún 1918 tí ó sì papò da ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù keje 2016 [1] jẹ́ olóṣèlú, ònímọ̀ ìjìnlẹ̀ físíìsì tí ó sì tún jẹ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Dahomey kí ó tó di orílẹ̀-èdè Benin pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọ ológun ilẹ̀ Dahomey láàrín ọdún 1968 sí ọdún 1969 Zinsou wà lára àwọn tí wọ́n buwọ́ lu [[òfin tí da àjọ African Union sílẹ̀ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù keje ọdún 2000 ní orílẹ̀-èdè Togo.


Ìgbẹ́ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ibẹ̀rẹ̀ ayé ati iṣẹ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Zinsou ní ìlú Ouidah ní ọjọ́ kẹtalélógún oṣù kẹta ọdún 1918. Ó kẹ́kọ́ ní Porto Novo ati ilé-ẹ̀kọ́ Ecole William Ponty tí ó wà ní ìlú Senegal. Ó kẹ́kọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn ní ilé-ẹ̀kọ́ Dakar Medical College tí ó sì di ònímọ̀ ìṣègùn. Zinsou di oníṣègùn ní ilé-iṣẹ́ ọmọ ogun Faranse ní ọdún 1939-1940. Kò pẹ́ púpọ̀ tí ó fi dá ilé ìṣègùn tirẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì dara pọ̀ mọ́ ìṣèlú.[2]

Ipa rẹ̀ nínú ìṣèlú lásìkò ìṣèjọba rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Zinsou jẹ́ ìkan pàtàkì nínú àwọn olóṣèlú ilẹ̀ Dahomey tí wọ́n ẹgbẹ́ ìṣèlú akọ́kó Union Progressiste Dahoméenne (UPD) sílẹ̀ ní ilẹ̀ Dahomey.[2] Ládokò náà, òun ni igbákejì ọ̀gbẹ́ni Sourou-Migan Apithy ní ọdún 1945, ó sì tún jẹ́ igbákejì olórí é ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Faranse. Ó tún jẹ́ igbákejì sí ilé aṣojú ṣòfin French Union láàrín ọdún 1947 sí 1953. Lásìkò yí, ẹgbẹ́ ìṣèlú UPD pín yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ látàrí ẹ̀yà tí ọ̀gbẹ́ni Apithy, Hubart Maga àti Justin Ahomadégbé-Tomêtin léwájú wọn. Zinsou kò àwọn ìpín tókù sòdí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ahomadégbé-Tomêtin's ati Bloc Populaire Africain láti da ẹgbẹ́ ìṣèlú [Union Démocratique Dahoméenne]] sílẹ̀.[3] Ó sìnlú nílé ìgbìmọ̀ Aṣòfin àgbà nílẹ̀ Faranse gẹ́gẹ́ bí sẹ́nétọ̀ láàrín ọdún 1955 sí 1958. Lásìkò yí ni Zinsou ní ìbáṣepọ̀ tó gbópọn pẹ̀lú Léopold Sédar Senghor tí padà di àarẹ orílẹ̀-èdè Senegal Zinsou tún jẹ Mínísítà fún ètò ọrọ̀-ajé lásìkò "loi-cadre" tí ó jẹ́ àsìkò ìjàngbara ní ọdún 1958 sí 1959. Kò wu Zinsou kí àwọn ìlú amọ́nà tí ó wà lábẹ́ àwọn àmúnisìn Faranse, ìdí nìyí tí ó fi jẹ akọ̀wé fún ẹgbẹ́ Parti du Regroupement Africain (PRA) tí ó wà ní ìlú Dakar. Zinsou kúrò lẹ́yìn Apithy ní ọdún 1959 lẹ́yìn tí Apithy náà jáwọ́ nínú ìṣọ̀kan ilẹ̀ Mali tí ó jẹ́ ìkan lára àkọsílẹ̀ àwọn PRA.[3] Lẹ́yìn tí ilé Dahomey gba òmìnira, Zinsou di aṣojú ilé Faransé. Ó di Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè lábẹ́ ìṣèjọba Maga láàrín ọdún 1962 kí wọ́n tó yọ ọ́ kúrò láìrò tẹ́lẹ̀ ní ọdún 1962. Òun ni wọ́n yan gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè akọ̀wé gbogbo gbòò fún ilẹ̀ Faransé fún ìṣọkan ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní ọdún 1964. Òun náà tún ni won fi ṣe olùdámọ̀ràn pàtàkì fún àwọn ìlú tí wọ́n wà ní ẹkùn Àríwá ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí wọ́n ń sọ Faransé lórí Anglo-American Cooperation ní ìlú Paris. Zinsou tún di mínísítà fún ilẹ̀ òkèrè níparí oṣù Kejìlá ọdún 1965 sí 1967 lábẹ́ ìṣèjọba Christophe Soglo.[3] Lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbajọba 1967 coup àti mọ̀kàrúù ìbò 1968, Zinsou ni àwọn ọmọ ológun fa kalẹ̀ láti jẹ ààrẹ orílẹ̀-èdè náà ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje ọdún 1968, ìfàkalẹ̀ yí kọ́kó rújú nítorí wípé kò fẹ́ràn àwọn ológun rárá. Gẹ́gẹ́ bí ààrẹ, ó gbé òfin tí ó de kíkó èrú wọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́, tí ó sì gbé ìgbésẹ̀ lórí gbígba owó orí kalẹ̀. Ìgbésẹ̀ yí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará ìlú ati àwọn ọmọ ológun nínú pẹ̀lú fún ìgbésẹ̀ ìjọba Zinsou.[3] Látàrí ìgbésẹ̀ ìjọba rẹ̀ yí, olórí òṣìṣẹ́ ìjọba rẹ̀ Maurice Kouandété dìtẹ̀ gba ìjọba rẹ̀ ní ọjọ́ kẹwá oṣù kejìlá ọdún 1969, nígbà tí wọ́n yin ìbọn léra léra mọ́ ilé ìjọba tí awọn méjì nínú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ sì kú ní fọná-fọnṣu.[4] Zinsou kò rí ju ìbò mẹ́ta lọ nínú ìdìbò gbogbo gbòò tí wọ́n ṣe ní ọdún 1970, ó sì kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ ìjọba ààrẹ ilẹ̀ Benin. Dípò kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, ó kò lọ sí ilẹ̀ Paris.[5]

  1. Lentz, Harris M. (4 February 2014). Heads of States and Governments Since 1945. ISBN 9781134264902. https://books.google.com/books?id=D6HKAgAAQBAJ&q=%C3%89mile+Derlin+Zinsou+1918&pg=PA88. 
  2. 2.0 2.1 Houngnikpo & Decalo 2013, p. 373.
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 Houngnikpo & Decalo 2013, p. 374.
  4. "A Job with Little Future". Time (Time Inc.). 19 December 1969. Archived from the original on 14 December 2008. https://web.archive.org/web/20081214143358/http://www.time.com/time/magazine/article/0,9171,941734,00.html. Retrieved 6 November 2008. 
  5. Houngnikpo & Decalo 2013, p. 375.

Àwọn itọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Houngnikpo, Mathurin; Decalo, Samuel (2013). Historical Dictionary of Benin. Rowman & Littlefield. ISBN 978-0810871717. 

Àwọn Ìtàkùn ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àdàkọ:S-offÀdàkọ:S-end
Preceded by
Assogba Oké
Foreign Minister of Benin
1962–1963
Succeeded by
Hubert Maga
Preceded by
Tahirou Congacou
Foreign Minister of Benin
1965–1967
Succeeded by
Benoît Sinzogan


Àdàkọ:Authority control