Ìbàdàn Grammar School
Ìbàdàn Grammar School ni ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ girama kan tí ó wà ní agbègbè Mọ̀lété ní ìgboro ìlú Ìbàdàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .
Ìtàn bí wọ́n ṣe dá a sílẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀ ní ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ọdún 1913. Ilé-ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tí ó lààmì-laaka nínú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ girama tí wọ́n wà ní ìlú Ìbàdàn.[1]. Lásìkò tí ètò ẹ̀kọ́ bá ń lọ lọ́wọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn lámèyítọ́ ni wọ́n máa ń wá láti wá ṣe àbẹ̀wò sí ọgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ńlá láwùjọ Ìbàdàn ni wọ́n máa ń rán àwọn ọmọ wọn lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ yí fún ètò ẹ̀kọ́ tó yanrantí. [1] Ní ọdún kẹtàlélọ́gbọ̀n àkókọ́ tí wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀, àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ọkùnrin nikan ni wọ́n ń gbà wọlé láti kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀. Ilé-ẹ̀kọ́ yìí di ilé-ẹ̀kọ́ fún takọ-tabo ní ọdún 1941. Láàrín ọdún 1950 sí 1960, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìwé-ẹ̀rí "Higher School Certificate"(HSC) nígba tí wọ́n bá parí ẹ̀kọ́ iwe mẹ́fà. Ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ akọ́kọ́ ni Alexander Babátúndé Akínyẹlé. [2]
Àwọn àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- English
- Mathematics
- Civic Education
- Animal Husbandry
- Technical Drawing
- Accounting
- Auto Mechanics
- Christian Religious Studies
- Physics
- French Language
- Yorùbá Language
- Chemistry
- Geography
- Biology
- Agricultural science
- Economics
- Computer and IT
- Music
- Literature-In-English
- History
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde níbẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Mike Adénúgà
- Ayọ̀ Rosiji
- Michael Ọmọlẹwà
- Abdul Hamid Adiamoh
- Alex Ibru
- Olúṣẹ́gun Àgàgú
- Bọ́lá Ìgè
- Michael Ọlátúnjí Ọnàjídé
- Ken Nnamani
- Adedotun Aremu Gbadebo III
- Justice Ayotunde Phillips
- Alfred Diete-Spiff
- FOM Atake
Àwọn Itọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Toyin Falola; Adebayo Oyebade (2003). The Foundations of Nigeria: Essays in Honor of Toyin Falola. Africa World Press. ISBN 9781592211203. https://books.google.com/books?id=H5Lzf7s2M8EC&pg=PA288&dq=Ibadan+Grammar+School&hl=en&sa=X&ved=0CDgQ6AEwBmoVChMI2c7wjciKxgIVECDbCh3x7wC-#v=onepage&q=Ibadan%20Grammar%20School&f=false.
- ↑ Jide Osuntokun (March 14, 2013). "Centenary of Ibadan Grammar School". The Nation. http://thenationonlineng.net/new/centenary-of-ibadan-grammar-school/.
Ìtàkùn ìjásóde
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]"Ibadan Grammar School, Old Students Association".