Ìjọba Ìbílẹ̀ Oṣòdì-Ìsọlọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Oṣòdì-Ìsọlọ̀

Oshodi Isolo Local Government Secretariat in Oyetayo Street, Oshodi,Lagos State
LGA and suburb
Location in Lagos
Location in Lagos
Country Nigeria
StateLagos State
Area
 • Total17 sq mi (45 km2)
Population
 (2017)
 • Total1,000,509
Time zoneUTC+1 (WAT)

Oṣòdì-Ìsọ̀lọ̀ jẹ́ Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ (LGA) kan láàrín Ìpínlẹ̀ Èkó. Ìjọba ìbílẹ̀ yí jẹ́ dídá sílẹ̀ lábẹ́ ìṣẹ̀jọba Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní Ìpínlẹ̀ Èkó Alhaji Lateef Káyọ̀dé Jákàndè, tí gbogbo ènìyàn tún mọ̀ sí Bàbá Kékeré. Ẹni tí ó kọ́kọ́ jẹ́ Alága àti Olùdarí ìjọba Ìbílẹ̀ náà ni Olóògbé Sir Isaac Adémólú Bánjókó. Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Oṣòdì-Ìsọlọ̀ yí jẹ́ ẹ̀ka Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìkẹjà. Iye ènìyàn tí ó tó 621,509, ni ó ń gbé abẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn ọdún 2006 ṣe fi yé ni. Ẹni tí ó jẹ́ Alága àti Olùdarí ìjọba ìbílẹ̀ náà lásìkò àpilẹ̀kọ yí ni Hon. Idris Bolaji Muse Ariyoh.[1]

Àwọn Ẹkùn Ìjọba ìbílẹ̀ ibẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìjọba ìbílẹ̀ yí ní ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ Mọ́kànlá, àwọn ni:

  1. Oṣòdì/Bọ́ládé
  2. Orílé Oṣòdì
  3. Máfolúkù
  4. Ṣógúnlẹ̀
  5. Ṣógúnlẹ̀/Alásìá
  6. Ìsọlọ̀
  7. Àjàó Estate
  8. Ìlasa-màjà
  9. Ọkọ́ta
  10. Ìṣàgátẹ̀dó
  11. Òkè-Afá/Èjìgbò.[2]

Àwọn Ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "WORKING VISIT TO OSHODI/ ISOLO LOCAL GOVERNMENT AREA". www.noa.gov.ng. 2018-03-22. Retrieved 2020-03-17. 
  2. oolasunkanmi (2019-12-17). "OSHODI-ISOLO LOCAL GOVERNMENT HOLDS BUDGET RETREAT, BANS END-OF-YEAR STREET CARNIVALS". Lagos State Government. Retrieved 2020-03-17. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]