Jump to content

Ìkún-omi Mozambique ọdún 2000

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwòrán àwọn ènìyá̀n tó ṣàgbákò ìkún omi ti ilẹ̀ Mozambique, tí wọ́n ń dúró de ọkọ̀

Ìkún omi Mozambique ti ọdún 2000 jẹ́ àjálù ńlá ibi tí ó wáyé ní Osù Kejì àti Oṣù Kẹta ọdún 2000. Àjálù ìkún omi ńlá náà ṣẹlẹ̀ látàrí òjò ńlá tí ó wá nípasẹ̀ Cyclone Leon-Elineléyìí tó ṣẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin léyìí tí ó sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di aláìnílé lórí. Ó fẹ́rẹ̀ tó àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rin(800) tó kú, tí 1400 km 2 ilẹ̀ ọlóràá ní ìpalára; àti pé ẹgbààwá (20,000) màálù àti óúnjẹ ló ṣòfò. Ó jẹ́ ìkún omi tí ó burújù ní orílẹ̀-èdè Mozambique ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn. Ìjọba Mozambique pín mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún dọ́là fún àwọn ọmọ ìlú rẹ̀ láti ṣe àkọọ́lẹ̀ fún ìbàjẹ́ ohun-ìní àti ìpàdánù owó-èrè wọn.


Ìtàn ojú-ọjọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní Oṣù Kẹwàá àti Oṣù kọkànlá ọdún 1999, òjò ńlá kan pa Mozambique lára, lẹ́yìn náà ni òmíràn ní Oṣù Kìn-ín-ní ọdun 2000. [1] Nígbà tó fi máa di ìparí oṣù Kìn-ín-ní ọdún 2000, òjò náà mú kí àwọn odò Incomati, Umeluzi, àti Limpopo kọjá bèbè wọn, tí àwọn apá kan olú-ìlú Maputo sì ń farapa nínú ìkún náà. Ní Chókwè, Odò Limpopo dé ìpele ìwọ̀n mẹ́fà (6 metres (20 ft) ní ọjó kẹrìnlélógún oṣù kìn-ín-ní, lẹ́ẹ̀mejì ìpele dééde rẹ̀. [2] Díẹ̀ nínú àwọn agbègbè gba iye òjò ti ọdún kan ní ọ̀sẹ̀ méjì. [3] Àbájáde ìkún-omi yìí ni a kà pé ó jẹ́ èyí tó burú jùlọ láti pa àwọn orílẹ̀-èdè lára láti ọdún 1951. [4]

Ní ìparí Oṣù kejì, ìkún-omi yìí ti fa àwọn àlékún nínú àìsàn ibà àti ìgbuuru . Ìkún omi yìí tuń ṣe ìdálọ́wọ́dúró ìpèsè omi, ó sì tún dí ọ̀nà, [2] pẹ̀lú ọ̀nà òpópónà kéékèèké àríwá-gúúsú tó gé ní àwọn ipò mẹ́ta. [5]Ìkún omi yìí ṣẹlẹ̀ ní àwọn agbègbè tó gbòòrò, èyítí ó ṣe ìpalágbègbèpadà fún àwọn ènìyàn tó tó 220,000, [3] tí ó sì pa ènìyàn bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ṣáájú ị̀kọlù Eline. [6]

Àwọn àpapọ̀ ipa ti àwọn ìkún-omi tí ó ṣáájú wọ̀nyìí àti ipa ti Eline fi àwọn ènìyàn tó tó 463,000 sílẹ̀ nípò ìpalágbègbèpadà tàbí àìnílélórí, pẹ̀lú àwọn ọmọ ọdún márùn-ún tàbí tí kò tó bẹ́ẹ̀ tó tó 46, 000 . Lápapọ̀, àwọn ìkún-omi tí ó ṣáájú yìí àti Eline fa ikú èèyàn bí i 700, [4] ìdajì ní Chokwe. [7] pẹ̀lú ìbàjé àti ìpalára tó tó ni $500 million (2000 USD) ní ìfojúwò. [4] Ìjì-líle àti àwọn ìkún-omi yìí ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlọsíwáju ètò ọrọ̀-ajé tí Mozambique ṣe dàgbà ní àwọn ọdún 1990 láti òpin ogun abẹ́lé rẹ̀.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Frances Christie and Joseph Halon (2001). Mozambique & the Great Flood of 2000. Indianan University Press. p. 16. ISBN 0-253-33978-2. https://books.google.com/books?id=HWqjGAzoALYC&pg=PR16. 
  2. 2.0 2.1 "Mozambique: Limpopo Flood Reaches Chokwe". ReliefWeb. http://reliefweb.int/report/mozambique/mozambique-limpopo-flood-reaches-chokwe.  Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "pana124" defined multiple times with different content
  3. 3.0 3.1 "Tropical storm threatens flood-ravaged Mozambique". http://reliefweb.int/report/mozambique/tropical-storm-threatens-flood-ravaged-mozambique.  Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "dr218" defined multiple times with different content
  4. 4.0 4.1 4.2 Cyclone Season 1999–2000. Meteo-France. http://www.meteo.fr/temps/domtom/La_Reunion/webcmrs9.0/anglais/archives/publications/saisons_cycloniques/index19992000.html.  Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "report" defined multiple times with different content
  5. "Floods Cut Main Highway In Three Places". ReliefWeb. http://reliefweb.int/report/mozambique/floods-cut-main-highway-three-places. 
  6. Emelia Sithole (2000-02-23). "Mozambique's Chissano urges post-cyclone aid". Reuters. ReliefWeb. http://reliefweb.int/report/mozambique/mozambiques-chissano-urges-post-cyclone-aid. Retrieved 2014-09-04. 
  7. "Mozambique's flood death toll rises to nearly 700". ReliefWeb. 2000-04-03. http://reliefweb.int/report/mozambique/mozambiques-flood-death-toll-rises-nearly-700. Retrieved 2014-09-29.