Ìpàdé nípa àwọn ìwé Áfríkà àti èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Calabar

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìpàdé nípa àwọn ìwé Áfríkà àti èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Calabar tí wọ́n ń pè ní Calabar International Conference on African Literature and the English Language (ICALEL) jẹ́ ìpàdé tí òǹkọ̀wé Ernest Emenyonudá kalẹ̀ tí ó ń sì ń darí. Àwọn òǹkọ̀wé láti oríṣiríṣi àgbègbè lágbayẹ́ ni ó ma ń wá sí ìpàdé náà. Àkòrí ìpàdé àkọ́kọ́ ni “The Woman as a Writer in Africa”, ó tún mọ̀ sí "Obìnrin gẹ́gẹ́ bi òǹkọ̀wé ní orílẹ̀ Áfríkà", ìpàdé yìí wáyé ní gbọ̀ngán Yunifásítì ìlú Calabar ní oṣù karùn-ún ọdún 1981, òǹkọ̀wé Ghana, Ama Ata Aidoo sì jẹ́ ara àwọn tí ó kó àwọn ènìyàn níbi ìpàdẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbajúmọ̀ òǹkọ̀wé ní Áfríkà ní ó ti wá sí ìpàdé náà ríCyprian Ekwensi, Chinua Achebe, Wole Soyinka, Chinweizu, Dennis Brutus, Buchi Emecheta, Flora Nwapa, Elechi Amadi, Ken Saro Wiwa, Chukwuemeka Ike, Nuruddin Farah, Syl Cheney-Coker.

References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • E. N. Emenyonu, "Introduction", Goatskin Bags and Wisdom: New Critical Perspectives on African Literature, Trenton: AWP, 2000. ISBN 0-86543-670-3 (hb), ISBN 0-86543-671-1 (pb)