Òjó Adé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ojo Ade
Ọjọ́ìbíOctober 10, 1959
Ikeji Ile, Ipinle Osun, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
  • gospel singer
  • songwriter
  • evangelist
Ìgbà iṣẹ́1977 - present

Òjó Adé ni wọ́n bí ní (Ojo kewa, Osu Kewa Odun 1959) , Ó jẹ́ olórin, olùkọ orin-ẹ̀mí gósípẹ́ẹ̀lì àti Olùṣọ́ Àgùtàn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1]

ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bi ní ọjọ́ Kẹ́wàá oṣù Kẹwàá ọdún 1959 (October 10, 1959) ní ìlú Ìkeji-Ilé, ìlú ńlá kan ní  ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó kẹ́kọ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ St. Judges Anglican Church tí ó wà ní Ìkeji-Ilé ṣáájú kí ó tó darí lọ sílùú Èkó fún ìkọ́ṣẹ́ ọwọ́ Electronics. [2]

Ní ọdún 1987, Ó tún tẹ̀ síwájú láti kẹ́kòọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Bíbélì (Calvary International Bible College) lábẹ́ àkóso Olùṣọ́ Àgùtàn Rev. Àńjọọ́rìn, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìwáàsù àti ìhìn-rere ní ìlú Ìbàdàn .[3]

Iṣẹ́ Òòjọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀ ní ọdún 1977 nígbà tí ó dara pọ̀ mọ́ àwọn akorin ìjọ, ṣùgbọ́n tí ó dá ẹgbẹ́ akọrin tirẹ̀ kalẹ̀ ní ọdún 1979. Ní ọdún 1981, tí ó jẹ́ ọdún méjì lẹ́yìn tí ó dá ẹgbẹ́ akọrin ẹ̀mí tirẹ̀ sílẹ̀, ó kọ orin ẹmí kan jáde tí ó sọọ́ di ìlú-mọ̀ọ́ká tí àkọ́lé rẹ ń jẹ́ 'Jésù Tó Fúnmi' , tí ó sì tún gbé òmíràn jáde tí ó  tún pè àkọ́lé rẹ̀ ní Sátạ́nì Kò Sinmi. [4]

Ó wà lára àwọn olórin ẹ̀mí ti ìlànà Krìstẹ́nì tí ó ti lààmì-laaka ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pẹ̀lú iṣé takun takun rẹ̀. [5]


Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. our reporter. "God Warrior Congress holds programme". The Nation. Retrieved 14 March 2015. 
  2. Super User. "About Evangelist Ojo Ade". christgiftrevivalministries.org. Archived from the original on 2 April 2015. Retrieved 14 March 2015. 
  3. Empty citation (help) 
  4. Eloti tV. "Gospel singer lauds Tribune management". elotitv.com. Retrieved 14 March 2015. 
  5. Akinola Olumide. "Classification of Classification of Nigerian gospel music styles igerian gospel music styles". academia.edu. Archived from the original on 28 December 2014. Retrieved 14 March 2015.