Ṣọ̀ún ìlú Ògbómọ̀sọ́
Ìrísí
Ṣọ̀ún ìlú Ògbómọ̀sọ́, tàbí Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́ lásán, jẹ́ orúkọ oyè ọba aládé tí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ọba Ọládùnǹní Oyèwùnmí III ní ó wà lórí ìtẹ́ ṣọ̀ún tí Ògbómọ̀ṣọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́. Ó gorí ìtẹ́ àwọn babańlá baba rẹ̀ lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹwàá ọdún 1973.[1] [2]
Àtòjọ àwọn ṣọ̀ún tí Ògbómọ̀ṣọ́ tí wọ́n ti jẹ́ láti ọdún 1770 títí di 2020
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ọba Kúmóyèdé Àjàó 1770 - 1797
- Ọba Tóyèjẹ Àkànní (Ààrẹ Ọ̀nà-kakanfò) 1797 - 1825
- Ọba Olúwùsì Àrẹ̀mú. 1826 - 1840
- Ọba Báyéwùwọ́n Kélèbí. 1841 - 1845.
- Ọba Ìdòwú Bọ́láńta. 1845 - 1848
- Ọba Ọdúnaró Apáebi. 1850 - 1864
- Ọba Òjó Aburúmákú. (Ààrẹ Ọ̀nà-kakanfò) 1865 - 1869
- Ọba Gbágun Oǹdùgbẹ̀ Ajagungbadé I. 1870 - 1877
- Ọba Láoyè Òrumọgẹ̀gẹ̀. 1877 - 1901
- Ọba Májẹ́ngbásàn Elépo. 1902 - 1908
- Ọba Àtàndá Ọláyọdé I. 1908 - 1914
- Ọba Àńdé Ìtabíyì. 1914 - 1915
- Ọba Oyèwùnmí Ajagungbadé II. 1916 - 1940
- Ọba Àmàó Oyètúndé. 1940 - 1944
- Ọba Òkè Ọlánípẹ̀kun 1944 - 1952
- Ọba Ọ̀látúnjí Elépo II 1952 - 1966
- Ọba Olájídé Ọláyọdé II. 1966 - 1969
- Ọba Ajíbóyè Ìtabíyì. 1972 - 1973
- Ọba Oyèwùnmí Ajagungbadé III. 1973 - títí di àkókò yìí. [2]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "At 90, Oba Oyewumi opens up… My life as Soun of Ogbomoso". The Sun Nigeria. 2016-05-27. Retrieved 2020-05-26.
- ↑ 2.0 2.1 "Soun Dynasty". AGA 2019 Announcement. Archived from the original on 2020-08-03. Retrieved 2020-05-26.