Ṣọ̀ún ìlú Ògbómọ̀sọ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ṣọ̀ún ìlú Ògbómọ̀sọ́, tàbí Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́ lásán, jẹ́ orúkọ oyè ọba aládé tí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ọba Ọládùnǹní Oyèwùnmí III ní ó wà lórí ìtẹ́ ṣọ̀ún tí Ògbómọ̀ṣọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́. Ó gorí ìtẹ́ àwọn babańlá baba rẹ̀ lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹwàá ọdún 1973.[1] [2]

Àtòjọ àwọn ṣọ̀ún tí Ògbómọ̀ṣọ́ tí wọ́n ti jẹ́ láti ọdún 1770 títí di 2020[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Ọba Kúmóyèdé Àjàó 1770 - 1797
  • Ọba Tóyèjẹ Àkànní (Ààrẹ Ọ̀nà-kakanfò) 1797 - 1825
  • Ọba Olúwùsì Àrẹ̀mú. 1826 - 1840
  • Ọba Báyéwùwọ́n Kélèbí. 1841 - 1845.
  • Ọba Ìdòwú Bọ́láńta. 1845 - 1848
  • Ọba Ọdúnaró Apáebi. 1850 - 1864
  • Ọba Òjó Aburúmákú. (Ààrẹ Ọ̀nà-kakanfò) 1865 - 1869
  • Ọba Gbágun Oǹdùgbẹ̀ Ajagungbadé I. 1870 - 1877
  • Ọba Láoyè Òrumọgẹ̀gẹ̀. 1877 - 1901
  • Ọba Májẹ́ngbásàn Elépo. 1902 - 1908
  • Ọba Àtàndá Ọláyọdé I. 1908 - 1914
  • Ọba Àńdé Ìtabíyì. 1914 - 1915
  • Ọba Oyèwùnmí Ajagungbadé II. 1916 - 1940
  • Ọba Àmàó Oyètúndé. 1940 - 1944
  • Ọba Òkè Ọlánípẹ̀kun 1944 - 1952
  • Ọba Ọ̀látúnjí Elépo II 1952 - 1966
  • Ọba Olájídé Ọláyọdé II. 1966 - 1969
  • Ọba Ajíbóyè Ìtabíyì. 1972 - 1973
  • Ọba Oyèwùnmí Ajagungbadé III. 1973 - títí di àkókò yìí. [2]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "At 90, Oba Oyewumi opens up… My life as Soun of Ogbomoso". The Sun Nigeria. 2016-05-27. Retrieved 2020-05-26. 
  2. 2.0 2.1 "Soun Dynasty". AGA 2019 Announcement. Archived from the original on 2020-08-03. Retrieved 2020-05-26.