Ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn (Ọ̀lọ́pàá Ìlẹ̀ Oòduà)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Àmọ̀tẹ́kùn jẹ́ ẹ̀ṣọ́ aṣọ́lùú tí àwọn Gómìnà mẹ́fà tí ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kìíní ọdún 2020 (9th January 2020) láti kún ìjọba àpapọ̀ lọ́wọ́ láti mójú tó ètò ààbò gbogbo ilẹ̀ káàárọ̀-ó-jíire tí ó dàbí pé ó ń mẹ́hẹ. Àwọn Gómìnà Ìpínlẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó wà ilẹ̀ Yorùbá fi Ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn lọ́lẹ̀ ni ìlú Ìbàdàn, tí ń ṣe Olú-ìlú Ìlẹ̀ Oòduà.

Iṣẹ́ Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Èkó, Ọ̀ṣun, Èkìtì, Oǹdó àti Ògùn ní wọ́n parapọ̀ tí wọ́n sìn dá ẹ̀ṣọ́ aàbò yìí sílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí ní dá aábò gbogbo ènìyàn àti ilẹ̀ Yorùbá pátápátá. Ìgbàgbọ́ wọn ní wípé, iṣẹ́ àbò ìlú, pàápàá jùlọ lásìkò yìí kọjá Ọ̀lọ́pàá ìjọba Àpapọ̀ nìkan, ìdí nìyí tí wọ́n fi dá ẹ̀ṣọ́ ààbò Àmọ́tẹ̀kún sílẹ̀ láti kún ìrànlọ́wọ́ fún àwọn agbófinró nílẹ̀ Yorùbá. [1] [2] [3] [4]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Amotekun: Constitutional implication of South-west regional security initiative". Premium Times Nigeria. 2020-01-09. Retrieved 2020-01-09. 
  2. Mutum, Ronald (2020-01-09). "IGP okays S/west security outfit, Amotekun – Daily Trust". Daily Trust. Retrieved 2020-01-09. 
  3. Published (2015-12-15). "Operation Amotekun: South-West to train OPC, hunters, others". Punch Newspapers. Retrieved 2020-01-09. 
  4. "How Southwest security outfit Amotekun will tackle crime". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2020-01-08. Retrieved 2020-01-09.