Ẹ̀sìn Islam
Ẹ̀sìn Ìmàle tabi Ẹ̀sìn Islàm (Lárúbáwá: الإسلام al-’islām, pronounced [ʔislæːm] ( listen)[note 1])[1] jẹ́ ẹ̀sìn àlááfíà,ìrọ̀rùn àti ìjupá-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Ọlọ́run aṣẹ̀dá gbogbo ayé nípa ṣ́iṣe ìfẹ́ àti títèlé àṣẹ rẹ̀ yálà o tẹ́ ọ lọ́rùn tàbí kò tẹ́ ọ lọ́rùn. Ó tún jẹ́ ẹ̀sin tí Ọlọ́run tún fi ránṣẹ́ sí gbogbo ayé látọwọ́ àwọn òjíṣ̣́e rẹ̀ tó ti rán wá ṣáájú ànọ́bì Muhammad ọmọ Abdullah (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun ó ma bá a). Òun sì ni ẹ̀sìn òtítọ tí ẹ̀sìn mìíràn kò lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gb̀a ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun (Allah) yàtò sí òun nìkan. Ọlọ́hun (Allah) sì ti ṣe é ní ẹ̀sìn ìrọ̀rùn tí kò sí ìṣòro kankan tàbí wàhálà níbẹ̀. Kò si ohun tí ó kọjá agbára wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìjẹni nípá fún àwọn tí wọ́n gba èsìn náà. Bẹ́è sì tún ni ẹ̀sìn náà kò la ohun tí ó kọjá agbára wọn bọ̀ wọ́n lọ́rùn. Ìsìlámù ni ẹ̀sìn tí ó ṣe pé ìmọ̀-Ọlọ́hun ni (al- Taoheed) ní ìpìl̀ẹ rè, òdodo ni òpó rẹ̀, ó dá lórí déédé,otito. Òhun sì ni ẹ̀sìn tí ó gbópọn tí ó jẹ́ pé ó ń darí gbogbo ẹ̀dá sí ibi gbogbo ohun tí yó̀o jẹ́ ànfààní fún wọn ní ọ̀run àti ayé wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì tún ń kì wọ́n nílọ̀ nípa gbogbo ohun tí yó̀o ṣaburú fún wọn yálà láyé ni tàbí ọ̀run. Òhun ni ẹ̀sìn tí Ọlọ́hun (Allah) fi ṣe àtúnṣe àwọn àdì-ọ́kàn àti àwọn ìwà àìdáa kan. Òhun náà ni Ó fi ṣe àtúnṣe ìsẹ̀mí ayé àti ti ọ̀run. Òun ni Ọlọ́hun (Allah) fi ṣe ìrẹ́pọ̀ láàrin àwọn ọkàn tí ó kẹ̀yìn sí ara wọn àti àwọn ojúkòkòrò tí ó fọ́nká. Nípasẹ̀ èyí ni Ó fi yọ àwọn ohun tí a kà sí iwájú yìí nínú òkùnkùn biribiri ìró, tí Ó sì ṣe ìfinimọ̀nà rẹ̀ lọ sí ibi òtítọ́, tí Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà lọ sí ibi ọ̀nà tí ó yè kooro[2].
- Ẹ̀sìn Islam jẹ́ orúkọ iṣẹ́ ayélujára gbajúgbajà tí Sheikh Dr. Abdul-Fattah Adelabu ẹni tí í ṣe olórí àti olùdásílẹ̀, Awqaf Africa àti Asíwájú Ẹ̀sìn fún àwọn aláwọ̀ dúdú ní ilẹ̀ Geesi dá sílẹ̀ láti ipaṣẹ̀ EsinIslam.com fún ẹ̀kọ́ nípa Ẹ̀sìn Islam pẹ̀lú Awqaf Africa Muslim Open College ní ìlú London.
Ẹ̀sìn Islam Ní Ṣókí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]ISLAM ni esin ti o duro to, eyi ti a gbe kale ni ona ti o dara de opin ninu gbogbo awon iro ti o muwa ati ninu gbogbo awon idajo re pata.Ko si iroyin kankan ninu re ayafi otito ati ododo be e si ni ko si idajo kankan ninu re ayafi rere ati deede. Ninu re ni a o ti ri awon adisokan ti o ni alaafia, awon ise ti o duro to ,awon iwa ti o dara pari pelu awon eko ti o ye kooro.[3].
Ni soki, ise ISLAM wa lati se aseyori awon ohun ti o n bo wonyii[4]:
- Sise alaye Olohun ti I se oluda awon eniyan fun won pelu (ifosiwewe alaye) awon oruko Re ti o dara julo ati awon oriki Re ti o ga pari pelu awon ise Re ti o pe perepere ati awon ohun ti o to si I lohun nikan soso.
- Pipe awon eru Olohun (awon eda) lo si ibi jijosin fun Olohun (Allah) ni kan soso laiko mu orogun kankan mo o. Eyi yo o je be e nipa sise ohun ti O se ni oranyan le won lori ninu awon ase ati (jijinna si) awon ohun ti O ko fun ni lati se. Eyi ti o se pe daradara won ni igbesi aye won ati ti orun won wa ni ibi titele awon ase Re yii.
- Riran awon eda leti iwasi won ati ibuseri-padabosi won leyin iku won ati ohun ti won yo o pade ninu saaree won ati nigba igbehinde won ati isiro ise won ati ibumorile won leyin eleyii; eyi ti ise ogba idera alujonna tabi ina ti o n jo geregere.
Ni akotan, a lee rokirika awon ohun ti esin islam pe ni lo si ibe ninu awon koko ti o n bo wonyii:
IKINNI: Adisokan (akiidah)
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Eleyin da lori igbagbo pelu awon origun igbagbo mefeefa[5]:
(1) Gbigba Olohun (Allah) gbo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Eyi le e je be e pelu awon nikan ti o n bo wonyii:
- (i) Nini igbagbo pe Olohun (Allah) nikan ni Oba Eleto. Eyi tumo si pe Oun ni Oba,Oluda, Oluni ati Olusakoso gbogbo awon eto (aye ati ti orun ).
- (ii) Nini igbagbo pelu pe Olohun (Allah) nikan ni Atoosin. Eyi tumo si pe Oun nikan ni O ni eto lati maa gba ijosin ati pe elomiran ti a ba dari ijosin si yato si Oun jasi igbese-ikuna ti ko to.
- (iii) Nini igbagbo ninu awon oruko Re ati awon oriki Re. Eyi tumo si pe Oun ni o ni awon oruko ti o dara julo ati awon oriki ti o pe perepere ti o si ga julo gege bi o ti wa ninu tira Re (Al -quran) ati sunah (Ilana) ojise Re (ki ike ati ola Olohun ki o ma a baa).
(2) Nini igbagbo ninu awon molaaika
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Awon molaaika ni awon eru Olohun kan ti won je eni aponle gegebi won ti je eda Olohun (Allah). Bakannaa, won je oluse ibaada (ijosin) fun Olohun de oju ami won si tun je atele ase re ni perepere. Olohun (Allah) fi awon ise (ojuse) orisirisii fun okookan won. Ninu won ni Jibiriilu eni ti a se afiti ise mimo ti o ba n waye lati odo Olohun (Allah) si odo eni ti O ba fe ninu awon anabi Re ati awon ojise Re ti si. Ara won si tun ni Miikailu eni ti o wa fun alaamori riro ojo ati awon koriko ti n hu. Bee naa ni ara won ni Isiraafiilu eni ti o wa fun fifon fere ni asiko ti Olohun (Allah) ba fe ki gbogbo eda o sun oorun asun- fonfon- n-tefon ti yoo kase ile aye nile ati nigba ti o ba tun fe ki won dide (lati jabo nipa igbesi aye won). Ara won si tun ni molaaika iku eni ti ojuse re je gbigba awon emi ni asiko ti Olohun (Allah) ba ti ni asiko re to.
(3) Nini igbagbo si awon iwe mimo Olohun (tira)
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Olohun (Allah), Oba ti o tobi ti o si gbon-un -gbon julo so awon iwe kale fun awon ojise Re eyi ti ona mimo, rere ati daradara wa ninu re. Awon ti gbedeke re waye ninu awon tira yii ni wonyii:
- (i) Taoreeta eyi ti Olohun (Allah) so kale fun anabi Muusa eni ti awon kan mo si Moose -(ki ike ati ola Olohun o ma a baa). Tira yi ni iwe ti o tobi julo ti o so kale fun awon omo isireeli.
- (ii) Injiila (bibeli) ti Olohun (Allah) so kale fun anabi Isa eni ti awon kan mo si Jeesu- (ki ike ati ola Olohun o ma a baa).
- (iii) Sabuura ti Olohun (Allah) so kale fun anabi Dauda -eni ti awon kan mo si Dafiidi - (ki ike ati ola Olohun o maa baa)
- (iv) Awon takaada (ewe 'tira) ti Olohun (Allah) so kale fun ekeni -keji anabi Iburaimo - eni ti awon kan mo si Aburahaamu - ati anabi Musa. (Ki ike ati ola Olohun o maa ba awon mejeeji).
- (V) Alukuraani alaponle eyi ti Olohun (Allah) ti ola Re ga julo so kale fun anabi Re ti n je Muhammad eni ti i se olupinnu awon anabi .Tira alaponle yii ni Olohun (Allah) fi fagile gbogbo awon iwe mimo ti o ti so kale siwaju re. Idi abajo eyi ni o mu ki Olohun funraare mojuto siso tira naa (kuro nibii afikun tabi ayokuro omo adarihunrun tabi sisonu) nitoripe oun ni yoo seku gegebi awijare ti o fese mule gbon- in -gbon-in fun gbogbo eda titi di ojo igbehinde (alikiyaamo).
(4) Nini igbagbo si awon ojise Olohun pata laiko da enikan si
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Olohun (Allah) ti ran awon ojise kan si awon eda Re.
Eni akoko ninu awon ojise naa ni anabi Nuhu nigbati anabi Muhmmad (ki ike ati ola Olohun o ma a baa ati gbogbo awon ojise ti o siwaju re)si je olupinnu won. Gbogbo awon ojise Olohun pata -ti o fi mo anabi Isa- je eda abara ti ko si nkankan ninu jije Olohun ni ara won. Awon paapaa je eru Olohun (Allah) gegebi awon eda yoku naa ti je eru Olohun sugbon ti Adeda won se aponle fun won pelu riran won ni ise mimo si awon eda abara yoku. Ni akotan, Olohun (Allah) ti pari gbogbo ise ti o fe ran si aye pelu ise-imona ti o fi ran anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa).O si ti ran an si gbogbo eniyan laiko da enikan si. Nitori naa, ko si anabi kankan mo leyin anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa).
(5) Nini igbagbo nipa ojo ikehin
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ojo agbehinde ni ojo ikehin ti ko ni si ojo kankan leyin ojo naa mo. Ojo naa ni Olohun (Allah) yoo gbe gbogbo eniyan dide ni aaye pada lati seku titi ayeraye ninu ile onidera (alujonna)tabi ninu ile iya (ina) atanijoni.
Ninu igbagbo si ojo ikehin jasi nini igbagbo si gbogbo ohun ti yoo sele leyin iku ni eyi ti o ko ibeere (fitino) saaree ati idera pelu ijiya re sinu. Ati ohun ti yoo tun sele leyin eleyii gegebi agbehinde, iseripadabo si odo Olohun ati isiro ise ti eda gbe aye se. Leyinwa-igba-naa, ni imorile ile ibugbe ayeraye eyi ti i se alujonna tabi ina.
(6) Nini igbagbo si kadara(akoole)
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ohun ti oun n je kadara ni nini igbagbo pe Olohun (Allah) ni O pebubu gbogbo ohun ti n be, Ohun ni O si da gbogbo eda ni ona ti mimo Re ti siwaju re ti ariwoye Re si fe bee. Gbogbo awon alaamori ni o ti je mimo ni o si ti wa ni akoole ni odo Re. Olohun (Allah) fe gbogbo ohun ti n sele ni o je ki o maa sele bee, Oun paapaa ni o si daa.
IKEJI: Awon òpó Ẹsin Imale[6]
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Esin ISLAM je ohun ti a mo lori awon origun marun kan to je pe eniyan ko lee je musulumi tooto ayafi ti o ba ni igbagbo ninu awon origun naa ti o si n se okookan ninu re. Awon origun naa ni wonyi :
Ijeri
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ijeri (igba-tokantokan) pe Olohun (Allah) nikan ni Oba (ti a a josin fun) ati pe ojise Olohun ni anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa) i se. Ijeri yii ni kokoro ISLAM ati ipilese re ti gbogbo eka yoku duro le lori.
Itumo a i si oba miran leyin Olohun (Allah) ni pe ko si eni ti o leto pe ki a ma a se ijosin fun ju oun nikan lo.Oun nikan ni apesin tooto. Gbogbo elomiran ti a ba n dari ijosin si odo re yato si Oun je iwa ibaje ti ko si lese nile bi o ti wu ki o mo. Ohun ti o n je Olohun Oba ninu agboye awa musulumi ni eni ti a a josin fun.
Itumo ijeri (ifaramo) pe anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa) je ojise Olohun ni gbigba a ni ododo ninu gbogbo ohun ti o fun ni ni labare re, titele e ninu gbogbo oun ti o pa lase ati jijinna si gbogbo ohun ti o ko fun ni lati se ti o si jagbe mo a i fe be e.
Irun kiki
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Eyi ni awon irun ti a ma a n paara kiki re ni eemarun lojumo. Olohun (Allah) se e ni ofin lati lee je ifun Olohun ni iwo o Re lori awon eru Re, idupe fu Un lori ideraa Re ati okun idapo laarin musulumi ati Olohun Adeda re. Eyi ti yoo ma a ba A ni gbolohun ninu re ti yoo si ma a gbadura si I ninu re. Ti awon irun yii yo o si je akininlo fun un nipa sise ibaje ati sise aburu.
Olohun (Allah) si ti se imudaniloju daradara esin, igunrege igbagbo ati laada aye ati ti orun fun eni ti o ba n ki irun wakati maraarun daadaa. Ni ipase awon irun yii ni ibale-okan ati ibale-ara ti yoo je okunfa orire aye ati ti orun yoo fi sele fun eni ti o ba n kii deede.
Itore aanu (Saka)
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Eyi ni ore atinuwa kan ti eni ti o ba ni owo ti o ti wo gbedeke ti ilana ISLAM se afilele re yoo ma a san ni odoodun fun awon eni ti o leto si gbigba re ninu awon alaini ati awon miran. A ni lati mo daju gbangba pe itore aanu yi i ko je dandan fun alaini ti ko si gbedeke owo yii ni owo re. Eni ti o je dandan fun ni awon oloro ti yoo je pipe fun esin won ati ifaramo ISLAM won .Ti yoo si tun mu ilosiwaju ba iwasi won ati ihuwasi won pelu. Eyi si tun je ona kan pataki lati mu iyonusi ati iyojuran aye kuro lara won ati lara dukia won. Ati lati se afomo fun won kuro nibi aburu pelu lati se ikunlowo fun awon talaka ati awon alaini lawujo ati lati se igbeduro ohun ti yoo mu nkan tubatuse fun awon gan an alara paapaa. Paripari gbogbo re, oore aanu yii ko koja ebubu kan kinkinni ninu ohun ti Olohun (Allah) se fun won ninu owo ati ije- imu.
Aawe gbigba
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Eleyi yoo ma a je ohun ti yoo ma a sele ninu osu kan soso lodoodun. Osu yen si ni osu Ramadan alaponle, eyi ti se osu kesan an ninu osu odun hijira (odun ti a n fi osupa mu ka). Ninu osu yii ni gbogbo awon musulumi yoo se ara won ni osusu-owo ti won yoo si kora duro nibii kosee-mase-kosee-mato won gegebi i jije, mimu ati wiwole to aya eni ni asiko osan. Iyen ni pe kikoraduro yo o wa lati asiko idaji hai (yiyo alufajari) titi di irole pata (asiko wiwo oorun). Olohun (Allah) yoo wa a fi pipe esin won ati igbagbo ati amojukuro nibi laifi won jiro ikoraduro yii fun won. Bee si ni pipe won yoo si lekun gegebi nkan daradara miran yoo ti je tiwon ninu awon oore lantilanti ti o ti pa lese sile fun eleyii ni ile aye nihaayin ati ni orun.
Irinajo si ile mimo (haji)
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ohun naa ni imura giri lo si ile Olohun (Allah) Olowo lati lo josin fun Un ni asiko kan pato gegebi o tise wa ninu ilana Islam. Olohun (Allah) ti see ni oranyan fun eni ti o ba ni ikapa bee ni igba isemi ni eekan soso. Ninu asiko haji yii ni gbogbo musulumi jakejado aye yoo kojo si aaye ti o loore julo lori ile, ti gbogbo won yoo maa se ijosin fun Olohun kan soso nibe ,ti won yoo si gbe ewu orisikan - naa wo. Ko ni i si iyato laarin olori ati ara ilu, olowo aye ati mekunnu pelu funfun ati dudu ninu won.
Gbogbo won yo o ma a se awon ise ijosin mimo kan ti o ti ni akosile. Eyi ti o se koko julo ninu re je kikaraduro ni aaye ti a mo si Arafa ati rirokirika ile Oluwa (Kaaba) abiyi ti o je adojuko gbogbo Musulumi ni asiko ijosin won pelu ilosoke-losodo laarin oke Safa ati Moriwa. Awon anfaani aye ati orun olokan -o - jokan ti ko se e ka tan ni o wa ninu re.
IKETA : IHSAN[7]
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Eleyi tumo si pe ki Musulumi maa sin Olohun re pelu igbagbo ati esin ododo gegebi eni-wipe o n wo Olohun Adedaa lojukoroju, bi o tile je pe ire kori I dajudaju Oun n ri o. Bakanaa, ki o rii daju wipe oun se ohun kohun ni ibamu pelu ilana (Sunnah) ojise e Re; annabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun ki o baa).
Bakan- naa ni ISLAM tun feto si igbesi aye awon eni ti o gba a lesin yala ni iwasi won ni eyo kookan ni o tabi nigbati won ba wa nijonijo ni ona ti oriire aye ati torun yo o fi je tiwon. Nitori idi eyi ni o fi se fife iyawo ni eto fun awon atele re ti o si se won lojukokoro lo sibe. O si se sina sise ati iwa pansaga ni eewo fun won ati awon isesi-i-laabi miran. Bee ni o si se dida ibi po ati sisaanu awon alaini ati talika ni oranyan pelu amojuto won. Gegebi o ti senilojukokoro lo si ibi gbogbo iwa to dara ti o si se e ni oranyan, bee gege ti o si kininilo nipa gbogbo iwa buruku ti o si se e ni eewo. Siwaju sii, o se kiko oro jo lona mimo gegebii owo sise tabi yiyafunnilo ati ohun ti o fara pe eleyii ni eto. Ni idakeji ewe, o se owo ele (riba) ati gbogbo owokowo ati ohun ti o ba ti ni modaru ati awuruju ninu ni eewo.
Alaiye Ipari Nipa Esin Islam Ni Soki
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Yato si ohun ti a ka siwaju yii, ISLAM se akiyesi aidogba awon eniyan ninu diduroto si oju ona ilana re ati siso eto awon eniyan miran[8]. Nitori-idi-eyi ni o fi gbe awon ijiya amunisakuro-nibi-ese kale fun awon itayo -aala ti o ba waye ninu awon iwo Olohun (Allah ) Mimo; gegebii kikoomo (pipada sinu keferi leyin igba ti a ti gba ISLAM), sise sina, mimu oti ati bee bee lo.Gege bee naa ni o gbe awon ijiya adanilekun kale fun titase agere lori awon eto awon eniyan gegebii pipaayan, ole jija, piparo agbere mo elomiran, titayo aala nipa lilu elomiran tabi si see ni suta ati bee bee lo. O se pataki lati fi rinle pe awon ijiya kookan ti o fi lele yii se weku irunfin kookan la i si aseju tabi aseeto nibe. ISLAM tun seto, o si tun fi ala si ibasepo ti o wa laarin awon ara ilu ati awon adari won. O si se titele awon adari ni dandan fun awon ara ilu ninu gbogbo ohun ti ko ba si sise Olohun (Allah) ninu re. O si se yiyapa si ase won ati aigbo- aigba fun won ni eewo nitori ohun ti o le tara eyi jade ninu aapon ati rukerudo fun terutomo.
Ni akotan , a le e fowogbaya re pe ISLAM ti kakoja mimo asepo ti o yanran-un-tan ati ise ti o ye kooro laarin eru Olohun (eda) ati Adeda re ni abala kan, ati laarin omo eda eniyan ati awujo ti o n gbe nibe ninu gbogbo alaamori re ni abala miran. Ko si rere kan ninu awon iwa ati awon ibalo ayafi ki o je pe o ti se ifinimona awon atele re sibe ti o si se won lojukokoro nipa diduro tii gboin -gboin. Bee si ni ko aburu kan ninu awon iwa ati awon ibalo ayafi ki o je pe o ti ki won nilo gidigidi nipa atimasunmo o ti o si ko o fun won. Eyi ni o fi wa n han wa gedegbe pe esin ti ko labujeku kankan ni ISLAM je, esin ti o si dara ni pelu ti a ba gbe yiri wo ni gbogbo ona[9].
Ikiyesi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ There are ten pronunciations of Islam in English, differing in whether the first or second syllable has the stress, whether the s is /z/ or /s/, and whether the a is pronounced /ɑː/ as in father, /æ/ as in cat, or (when the stress is on the i) /ə/ as in the a of sofa (Merriam Webster). The most common are /ˈɪzləm, ˈɪsləm, ɪzˈlɑːm, ɪsˈlɑːm/ (Oxford English Dictionary, Random House) and /ˈɪzlɑːm, ˈɪslɑːm/ (American Heritage Dictionary).
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Alaiye nipa Esin Islam yi wa lati Alantakun Esin Islam ni ede Yoruba ti awon omo leyin Sheikh Dr. Abu-Abdullah Adelabu da sile nipase ijo Sheikh naa ti ise Awqaf Africa ni Ilu London > at EsinIslam.Com
- ↑ EsinIslam.Com jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ojú-ewé púpọ̀ tí ó ṣàlàyé nípa èyí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, ṣe àbẹ̀wò sí ìtàkùn Yorùbá náà nípa Islam [1]
- ↑ Iwa ti o dara ninu EsinIslam [2]
- ↑ Igbagbo ninu Esin Islam [3]
- ↑ Igbagbo Mefa naa ninu Esin Islam [4]
- ↑ Origun Esin Islam [5]
- ↑ Alye nipa Ihsaan [6]
- ↑ Awon alaiye Esin Islam miran [7]
- ↑ Esin Islam ni ede Yoruba ti Sheikh Dr. Abu-Abdullah Adelabu da sile ni Ilu London > at EsinIslam.Com