Jump to content

Ọ̀rọ̀:Malawa

Page contents not supported in other languages.
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àkíyèsí pàtàkì

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ kú iṣẹ́ takuntakun @Olaide07. Mo ṣàkíyèsí wípé ẹ ń dá àwọn àyọkà tuntun léra léra sórí Wikipedia èdè Yorùbá, èyí sì dára púpọ̀. Àmọ́ mo fẹ́ pe àkíyèsí yín sí agbékalẹ̀ akọtọ́ yín àti ìtumọ̀ àwọn àyọkà náà, wọn kò fi bẹ́ẹ̀ dára tó. Tí a bá sì wo àwọn àyọkà náà a ó ri wípé wọn kò gún rárá, ó wá yẹ kí agbékalẹ̀ wọn ó yanrantí. Láti ràn yín lọ́wọ́, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ kọ̀ọ̀kan níbẹ, àmọ́ ẹ̀yin ni ẹ ó ṣe púpọ̀ nínú rẹ̀. Ẹ wo àwọn àyọkà yí kí ẹ ṣe àtúnṣe sí wọn: Kuku Paka,Eghajira, Matapa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ẹ bá nílò ìrànwọ́ kan tàbí òmíràn, ẹ kàn sími lójú òpó ìbánisọ̀rọ̀ mi. Ẹ ṣeun. Agbalagba (ọ̀rọ̀) 10:54, 7 Oṣù Bélú 2024 (UTC)[ìdáhùn]