Ọbẹ̀ Ọ̀gbọ̀nọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ogbono soup
Ọbẹ̀ Ọ̀gbọ̀nọ̀
Alternative namesApon
TypeSoup
Place of originNigeria
Region or stateEdo people
Main ingredientsOgbono seeds, water, oil, leaf vegetables (bitterleaf and celosia), other vegetables, seasonings, meat
Àdàkọ:Wikibooks-inline 

Ọbẹ̀ Ọ̀gbọ̀nọ̀ (Igbo: bush mango, Yorùbá: Àpọ̀n) jẹ́ ọbẹ̀ kan ní ilẹ̀  Nàìjíríà tí wọ́n ń sè pẹ̀lú èso àpọ̀n gbị́gbẹ (the local name for Irvingia seeds),[1] àti àwọn ǹ kan óṇ́jẹ ìbílẹ̀ mìíràn. Àpọ̀n lílọ̀ náà má ń fún ọbẹ̀ ní àwọ̀ dúdú. Yàtọ̀ sí kúrú Àpọ̀n yìí, wọ́n tún ma ń fi omi, epo, ata gígún, ẹran àti àwọn ohun tó lè mú ọbẹ̀ dùn si. Wọ́n tún lè fi àwọn ẹ̀fọ́ bíi:  ẹ̀fọ́ gbúre, ẹ̀fọ́ ewúro, ẹ̀fọ́ ṣọkọ tàbí tẹ̀tẹ̀. Wọ́n tún lè fi ilá, tìmọ́ọ̀tì, àlùbọ́sà àti irú si kì ò lè dùn dára dára. Bạ́kan náà, àwọn ẹran bí: Ògúnfe, ẹran adìyẹ, ẹran àgbò, edé, ẹran ìgbẹ́, ni wọ́n tún lè fi gbé ọbẹ̀ náà là́rugẹ. Wọ́n lè jẹ ọbẹ̀ náà pẹ̀lú Fùfú, Ẹ̀bà, Iyán, Sẹ̀mò́, Túwó, Àpárán, Àmàlà Láfún tàbị́ Gbódo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n wọ́n kìí fi jẹ óúnjẹ bi Búrẹ́dì, ìrẹsì, ẹ̀wà, nítorí yíyọ̀ tàbí fífà tì ò ma ń fà bí ọbẹ̀ Ilá.

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]