Ọba Síkírù Adétọ̀nà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọba Síkírù Káyọ̀dé Adétọ̀nà, Awùjalẹ̀ tí ìlú Ìjẹ̀bú pátápátá (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún ọdún 1934) ni Ọba aládé tí ó ga jùlọ nílẹ̀ Ìjẹ̀bú ni ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Awùjalẹ̀ gorí ìtẹ́ àwọn bàbá rẹ̀ lọ́dún 1960.[1] [2]

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, wọ́n bí Ọba Síkírù Káyọ̀dé Adétọ̀nà lọ́jọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún ọdún 1934 sì ìdílé ọlọ́ba Aníkìláyà ti Ọmọba Rùfáí Adétọ̀nà, bàbá rẹ̀, àti Àlájà Ajíbábi Adétọ̀nà. Ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Ògbéré United Primary School, ní Òkè Agbo, Ìjẹ̀bú Igbó àti Ansar-Ud-Deen School, Ìjẹ̀bú-Òde láàárín ọdún 1943 sí 1950. Fún ìpele kejì ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó lọ sí Olú Ìwà College, (tí wọ́n ń pè ní Adéọlá Odùtọ́lá College báyìí). Ní kété tí ó ṣèyí, àwọn òyìnbó tí ń ṣàkóso orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbà á sí isẹ́ ní ìlú Ìbàdàn lọ́dún 1957. Ọmọba Adétọ̀nà kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1958 láti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní orílè-èdè Gẹ̀ẹ́sì nínú ìmọ̀ ìṣirò owó.[3]

Bí Ọba Síkírù Káyọ̀dé Adétọ̀nà ṣe jọba[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Gẹ̀ẹ́sì ni Ọmọba Adétọ̀nà wà tí ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fi fọwọ́ sí ìwé àṣẹ láti fi í jọba lọ́jọ́ kẹrin oṣù kìíní ọdún 1960. Ó jọba lọ́jọ́ karùn-ún oṣù karùn-ún lọ́dún 1960. [4] [5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Awujale : the autobiography of Oba Sikiru Kayode Adetona Ogbagba II - Catalog Search Results - IUCAT Bloomington". Welcome to the Indiana University Library Catalog (IUCAT) | Indiana University Libraries. Retrieved 2019-12-01. 
  2. "Seven interesting facts about Awujale of Ijebu at 85". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2019-05-10. Retrieved 2019-12-01. 
  3. "About HRM. Oba (Dr.) Sikiru Kayode Adetona (Ogbagba II) – Home". Oba Adetona Professorial Chair. 1934-05-10. Retrieved 2019-12-01. 
  4. "Awujale : the autobiography of Oba Sikiru Kayode Adetona Ogbagba II in SearchWorks catalog". SearchWorks catalog. 2019-11-16. Retrieved 2019-12-01. 
  5. "How I became The Awujale Of Ijebuland - The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2017-01-15. Retrieved 2019-12-01.