Ọdún Iléyá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Ọdún Iléyá
Id al-Adha (‘Īdu l-’Aḍḥā)
Ọdún Iléyá Id al-Adha (‘Īdu l-’Aḍḥā)
Official nameLárúbáwá: عيد الأضحى
‘Īdu l-’Aḍḥā
Also calledFestival of Sacrifice,
Sacrifice Feast
TypeIslamic
SignificanceCommemoration of Ibrahim's (Abraham's) willingness to sacrifice his son Ishmael for Allah.
Marks the end of the Pilgrimage to sundown, and ask God for forgiveness.
Begins10 Dhu al-Hijjah
Ends13 Dhu al-Hijjah
ObservancesPrayer, sacrificing a goat, sheep, cow or a camel, giving to poor people as a gift.

Ọdún Iléyá (Lárúbáwá: عيد الأضحى‘Īdu l-’Aḍḥā tabi Aïd el-Kabir) "Odun Idupe-Oore" je ojo isinmi pataki ninu esin Islam ti awon Musulumi unjoyo kakiri aye lati seranti ife Abraham (Ibrahim).[1]

Ni odun 1991, Sheikh Dr. Abu-Abdullah Adelabu se alaiye nipa Ọdún Iléyá ni ori ero-sorosoro Radio Abuja wipe Odu Ileya je ajodun Ifi-emi-imoore-han Olohun ni ikose Ibrahim ti o fi emi-imoore han nigbati o fe fi omo re Ishmael sile fun ifi emi-imoorehan si Olorun ti O se adehun fun oun Ibrahim wipe oun yio bi omo ninu ogbo.

Ninu waasi Sheikh naa ti i se omobibi orile ede Nigeria, a gbo lori eto ajodun odun ti osise agba Musulumi Alhaji Guranga se olootu ati olugbalejo lori ero-sorosoro naa wipe, fifi omo bibi Ibrahim sile ko i se riru ebo. Sheikh Adelabu ti awon omo lehin re nse igbejade EsinIslam.Com lati pase ile-eko Islam Awqaf Africa ni Ilu London se alaiye ni ede Yoruba lori ero Radio Abuja wipe idanwo ni Olohun se fun awon Ibrahim lati se ifirinle jije oluse-rere, olotito, olododo ati olumo-oore.

Onimimo Yoruba yi se itumo awon ese-oro ninu Quran bayi wipe[2]:

"Oun (Ibrahim) si so wipe: "Olohun mi o! Fun mi ni omo rere" Bee naa sini Awa (Olohun Oba-Aaso) si fun ni irohin ayo wipe oun (Ibrahim) yio ri Omo kunrin (Ishmael) bi. Nitori idi eyi, nigbati oun (omo okunrin keke re naa, Ishmael) dagba de bi ti o le rin kaakiri (fun ijihin-rere) pelu Ibrahim, oun (Ibrahim) si wi fun wipe: Iwo omo mi (Ishmael) o! A ti fi han mi l'ju ran wipe mo fi o se idupe oore (niti fifeni sile fun idupe l'owo olohun), abi iwo ko ri bi nkan tiri bi - kin ero tire?! Oun (Ishmael) si da (baba re Ibrahim) lohun wipe: "Iwo baba mi o! Se gege bi A ti se pa iwo l'ase lati se, Inshâ' Allâh (Ni ti Ogo-Olohun) iwo yio si mo bi mo ti je ninu awon As-Sâbirin (Awon Olufarada ninu suuru ati oun ti o jomo bee gbogbo).

Lehin eyi, ti awon mejeeji si ti gba fun Olohun won Allah ti nwon si se ijuwo-juse sile fun Ife Olohun), ti oun (Ibrahim) si ti te ori re (Ishamel) lo sile (ni aaye iteba si iwaju);

"Bayi naa ni Awa si pe oun: "Iwo Ibrahim o!"

"Iwo (Ibrahin) ti se gege bi A ti fi han o (ni ojuran) ni otito ati ni ododo! Bayi naa si ni Awa se ma n san esan fun (gbogbo awon) Muhsinûn (oluserere lotito ati lododo) - Sheikh Adelabu se itoka si Ese-Oro Olohun ninu Quran Ori 2:112)."

Lai ko se aniani, idanwo nla ti o fi oju han gbangba ni eleyi je. Nitori idi eyi ni A wa fi se iropo (gege bi irapada) omo (Ishamael) ti oun (Ibrahim) naa pelu aguntan kan bolojo (lati fi dipo ni sise idupe oore lati Odo Olohun)

"Bayi naa si ni A wa je ki o wa nile fun un (Ibrahin) iranti rere ti o si di manigbagbe fun ati laarin awon aromodomo ti oun bo lehin titi lailai And We left for him (a goodly remembrance) among generations (to come) in later times."

"Salâmun 'alaa Ibrâhim (Abraham) i.e. Ike ati ige (Olohun) ni fun Ibrahim (Abraham)"[3].Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Diversity Calendar: Eid al-Adha University of Kansas Medical Center
  2. [http://www.esinislam.com/Quran_And_Hadith/Arabic_Engilsh_Quran/Arabic_English_Quran_Surah_37.htm Awon Aaya yi ninu Quran se ekunrere ni Surah As-Safaat 37:100-111
  3. [http://www.esinislam.com/MediaYoruba/index.php Fun ekunrere alaiye yi ni Ede Yoruba, e wo EsinIslam.Com