Ọlátúbọ̀sún Ọládàpọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Olatubosun Oladapo
Ọjọ́ìbí Ọlátúbọ̀sún Ọládàpọ̀
(1943-09-19)19 Oṣù Kẹ̀sán 1943
Ibadan, Oyo State, Nigeria
Orílẹ̀-èdè Nigerian
Orúkọ míràn Tubosun Oladapo, Olatunbosun Oladapo
Alma mater University of Lagos
Iṣẹ́ Poet, Writer, Record Producer
Parent(s) Daniel Akanji Oladapo, Segilola OladapoWon bi Olatubosun Oladapo, ti won tun mo si Tubosun Oladapo, tabi "Odidere Aiyekooto" ni ojo kokandinlogun odun 1943  (born 1 9 September 1943).o je akewi ede  Yoruba (folk poet),[1][2] olukotan, olugbe orin jade, olusewadii imo ijinle, akaroyin onkowe ti awon olugbo re je Yoruba ti won wo po ni agbegbe iwo-oorun ile Naijiria.

Igbesi aye re, ati ise igbohun-safef re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Abraham Olatubosun Oladapo lo si ile-iwe alakoobere ti Phillip's Primary School ni Araromi Owu ni odun 1950, leyin eyi ni o lo si St James’ Olanla ni Akinyele, ni ilu Ibadan ni odun 1951 si 1954, ti o si tun lo si ile eko agba ti ilu-Eko University of Lagos.[3]

O kekoo gegge bi akose-mose oluko ni ile-iwe  St. Luke’s Teachers’ Training College, ni Ibadan, ni bi ti o ti bere ise atinuda nipa ewi kiko ati kikewi re nibi ayeye apijopo kan ni gbangan ile-eko naa ni odun 1965 ni  bi ti o ti ke Ijala-ode.[4] leyin ti o pari ise re nile-eko yii ni 1967, won gbe lo sii St. David's School, ni  Kudeti ni igboro Ibadan. o so ninu iforowero kan wipe: "Ile-iwe St Luke’s ni ebun ere  onise mi ti fara han ti won si ran mi lo si ile-eko agba nilu Eko iyen University of Lagos wipe ki n lo keko-ofe Diploma in Yoruba si ti mo si mu esi ipele kini to ga julo jade nile eko naa."

Ni odun 1969 o dara po m iwe iroyin "The Sketch newspaper", ati GbounGboun, iwe iroyin Yoruba kan ni bi ti o ti sise titi ki o to dara po mo Western Nigeria Television (WNTV) ati  Western Nigeria Broadcasting Service (WNBS) ni odun 1970. Ibe ni o ti pade awo eyan bii: Adebayo Faleti,eni ti oun  ran an lowo gidi gidi ati Aremo  Adebayo Sanda, eni ti o je atoku eto Kaaro Ooojiire ati Tiwa N’tiwa lasiko naa. Oladapo  feyin ti lenu ise ni odun 1977 to si da ile ise agbohun-sile tire sile record company, ile ise naa gberu ti o si n gbe awon elebun opolo lorisi risi jade paa paa julo ni ede abinibi re Yorùbá.

Ile ise re naa gbe awon awo to ju okanle-laadota 51 jade ti o si gbe igba awon osere jade abe ile ise naa. Lara won ni  oloogbe Ojogbon Ogundare Foyanmu ti o je ono bibi ilu Ogbomoso, Odolaye Aremu ti o je omo bibi ilu Ilorin ni ipinle Kwara, Ayanyemi Atokowa gbowo nile, eni ti o je Aayan afilu dara,  Alabi Ogundepo, ati Duro Ladipo  ati awo gbaju gbaa osere to ti di laami laaka ake jado agbaye loni. Awon awo ewi re ti o gbe jade paa paa julo ewi Yoruba re to ti so dorin lo wa lori igba kaa-ka-kiri. Bakan naa ni o tun se egbe fun awon akorin emi onigbabgo kan ti won n je "K-12 Voices"  ti Diipo Sodiipo je adari orin naa

Awon ise apileko re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oladapo ti gbe awon olokan o jokan ise apileko ti o to bi mokandinlogun ade saaju iku re. Lara awon ise ni ijoba fonte lu pe ki awon omo pe ki awon omo ile-eko alakoobere titi de fasiti o ma lo gege bi iwe ise won ninu ede Yoruba ile yii ati loke-okun.

Olatubosun o ko awon iwe Ewi aladun bii: Aroye Akewi (1 & 2) , Arofo Awon Omode.  bakan naa ni ere onise onitan re 'Ogun Lakaaye' ati 'Egbade Falade' lapapo ni won fun ni ami eye nibi idije ere onise oei-tage ni Oxford University Press ni 1970

Awon oye ibible ti won fi da lola[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Won fi je oye ni igboro ilu  Ibadan ni (Oyo State) ati Ire-Ekiti ni (Ekiti State)

Awon ebi re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olatubosun bi awon omo ti awon naa je akewi ati onimo eda ede paa paa julo Kola Tubosun, ati Yemi Adesanya ti oun naa je onimo isiro ati onkowe

References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Washington, Teresa N. (2005). Our mothers, our powers, our texts: manifestations of Àjé in Africana literature. Indiana University Press. pp. 276–. ISBN 978-0-253-34545-5. https://books.google.com/books?id=q_WoU41r8I4C&pg=PA276. Retrieved 29 April 2011. 
  2. Abiodun, Taiwo (2015). "Sycophants are Taking the Shine Off Ewi". The Nation. 
  3. Taiwo Abiodun, "‘Sycophants are taking the shine off Ewi poetry’", The Nation, 26 July 2015.
  4. "Abraham Olatubosun Oladapo". Dawn Commission. 25 February 2016.