Ọmọ Ọlọ́run

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Miniature in Les Très Riches Heures du Duc de Berry depicting the Baptism of Jesus, when God the Father proclaimed that Jesus is his Son.

Nínú ìtàn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olórí ni wọ́n ti fún ara wọn ní orúkọ bíi "ọmọ Ọlọ́run", tàbí ọmọ ọ̀run.[1]

Ọ̀rọ̀ yìí, "Ọmọ Ọlọ́run", ni wọ́n ti kọ́kọ́ lò nínú Bíbélì èdè Hébérù, gẹ́gẹ́ bí orúkọ mìíràn tí wọ́n fi ń pe ènìyàn tí ó bá súnmọ́ Ọlọ́run tàbí ẹni tí ó bá ní ìbáṣepọ̀ tó dán mánrán pẹ̀lú Ọlọ́run. Nínú ìwé Ẹ́kísódù, wọ́n máa ń pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkọ́bí Ọmọkùnrin Ọlọ́run.[2] Kódà, Bíbélì pé Sólómọ́nì ní "Ọmọ Ọlọ́run".[3][4] Bákan náà, wọ́n máa ń pe àwọn Áńgẹ́lì, àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn ọba Ísírẹ́lì ní "Ọmọ Ọlọ́run" [5]

Nínú ìwé Májẹ̀mú Tuntun tí Bíbélì mímọ́ àwọn ẹlẹ́sìn ọmọ lẹ́yìn Jésù, Jésù ni wọ́n ń pè ní "Ọmọ Ọlọ́run" ní ọ̀pọ̀ ìgbà.[5] Níbi ìṣẹ̀lẹ̀ méjì nínú Bíbélì, a gbọ́ wípé ohùn kan ti ọ̀run wá, tí ó pe Jésù ní "Ọmọ Ọlọ́run". Jésù pàápàá fúnra rẹ̀ pe ara rẹ̀ ni "ọmọ Ọlọ́run", bákan náà ọ̀pọ̀ ènìyàn pè é ní "Ọmọ Ọlọ́run" nínú Májẹ̀mú Tuntun inú Bíbélì.[5][6][7][8] Wọ́n pe Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní "Àwọn Ọmọ Ọlọ́run"."[9] Ní ti Jésù, wọ́n ń pè é ní Ọmọ Ọlọ́run nítorí ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bí Mẹ̀sáyà, (Olùgbàlà Aráyé) tàbí Christ, Ọba ti Olódùmarè yàn.[10] (Matthew 26:63 KJV). Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, pípe Jésù ní Ọmọ Ọlọ́run tàbí Messiah ju bẹ́ẹ̀ lọ fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọ́n ṣì ń ṣe àkàwé àti ìwádìí rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣe àṣìlò ọ̀rọ̀ yìí, "Ọmọ Ọlọ́run" pẹ̀lú "Ọlọ́run Ọmọ" (Gíríkì: Θεός ὁ υἱός), èyí ẹnikejì nínú Mẹ́talọ́kan nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Christianity, àwọn atẹ̀lé Jésú. Ẹ̀kọ́ nípa Mẹ́talọ́kan ṣàlàyé pé Jésù"Ọlọ́run Ọmọ", ẹ̀kọ́ náà ṣàlàyé pé Ọlọ́run àti Ọlọ́run Ọmọ jẹ́ ẹni kan náà ṣùgbọ́n pẹ̀lú àlàyé pé ọkàn jẹ́ Ọlọ́run Baba ti èkejì sì jẹ́ Ọlọ́run Ọmọ. Ẹni kẹta wọn ní Ọlọ́run Ẹ̀mí Mímọ́. Bákan náà, àwọn ẹlẹ́sìn Kìrìsìtẹ́nì tí wọn kò gbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan gbàgbọ́ pé Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bí ó ṣe wà nínú Májẹ̀mú Tuntun tí Bíbélì.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Muller136
  2. (Exodus 4:22 HE)
  3. The Tanach - The Torah/Prophets/Writings. Stone Edition. 1996. pp. 741. ISBN 0-89906-269-5. 
  4. The Tanach - The Torah/Prophets/Writings. Stone Edition. 1996. pp. 1923. ISBN 0-89906-269-5. 
  5. 5.0 5.1 5.2 "Catholic Encyclopedia: Son of God". Retrieved 7 October 2014. 
  6. One teacher: Jesus' teaching role in Matthew's gospel by John Yueh-Han Yieh 2004 ISBN 3-11-018151-7 pages 240–241
  7. Dwight Pentecost The words and works of Jesus Christ 2000 ISBN 0-310-30940-9 page 234
  8. The International Standard Bible Encyclopedia by Geoffrey W. Bromiley 1988 ISBN 0-8028-3785-9 pages 571–572
  9. "International Standard Bible Encyclopedia: Sons of God (New Testament)". BibleStudyTools.com. Retrieved 7 October 2014. 
  10. Merriam-Webster's collegiate dictionary (10th ed.) (2001). Springfield, MA: Merriam-Webster.