Abiodun Olujimi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Abiodun Christine Olujimi
Nigerian Senator for Ekiti South
Lórí àga
2015 – Till Date
Personal details
Ọjọ́ìbí25 Oṣù Kejìlá 1958 (1958-12-25) (ọmọ ọdún 61)
Ẹgbẹ́ olóṣèluPeoples' Democratic Party (PDP)
Alma materUniversity of Abuja, 2011
Nigerian Institute of Journalism, 1976, 1994

Ab́iọ́dún Christine Olújìmí jẹ́ olósèlú Nàìjíríà, a bi ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 1958.[1] Ó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin orílẹ̀ Ẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà, tí ó sojú fún agbègbè Gúúsù Ẹ̀kìtì àti olórí ìpín kékeré ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin ní Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ ti àjọ ìbáraenisọ̀rọ̀ ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìgbèsì ayé àti ètò-ẹ̀kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí ní Òmùò Ẹ̀kìtì ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní Ilé ìwé Àpóstélì ti obìnrin ní ìlú Ìbádán, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ó tún tẹ̀síwájú lọ sí Ilé ẹ̀kọ́ Oníròyìn ti Nàìjíríà láti gba dípọ̀n ni ọdún 1976. Bíọ́dún Olújìmí tún kàwé jáde gboyè dìgirì ní ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Òsèlú àti oyè dìgírì gíga ní ètò ìbátan àti ọjà títà ní Ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Àbújà.[2]

Isẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Isẹ́ Bíọ́dún gégé bí agbóhùn sáfẹ́fẹ́ àti ońiróyìn gbèé, bótilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe isẹ́ tí ó wùú láti ṣe.[3] Gẹ́gẹ́ bíi oníròyìn, ó ṣiṣẹ́ ní ilé ìwé ìròyìn Tribune, Ilé iṣẹ́ ̀ibáraenisọ̀rọ̀ àti if̀ìwéráńṣẹ́ ti Nà̀ijíríà, Ilé iṣẹ́ Telifísàn ti Nàìjíríà Ilé iṣẹ́ irin ní ìpínlẹ̀ Delta, Ovwian Aladja, Rífílẹ́sì, Tẹlifísàn DBN [2] àti alákóso ti Tẹlifísàn DBN lati 1993-1997.

Ó darapọ̀ mọ́ ọkọ rẹ̀ nínú òsèlù[3] ní ọdún 1997 gẹ́gẹ́ bií akọ̀wé àgbáyé ti ìjoba àpapọ̀ ti NCPN, Ó kọjá lọ sínú ẹgbẹ́ APC , ẹgbẹ́ onígbálẹ̀ lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ titẹ́lẹ̀ parun, ó tún jẹ akọ̀wé àpapò fún egbẹ́ APC. [2]

Ní ọdún 2002, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ aláburadà (PDP) leyíi tí ó bẹ̀rẹ̀ àseyorí rẹ̀ nínú òsèlú. Ọdún 2003 ni wọ́n yàn àn gẹ́gẹ́ bií Olùrànlọ́wọ́ sí Gòmìnà ìpínlẹ̀ Ẹ̀kìtì, láti ibẹ̀ wọ́n dìbò yan gẹ́gẹ́ bí omo ilé ìgbìmọ̀ asòfin àpapò. Ó di igbákejì Gómìnà pèlú Gómìnà Ayò Fáyose ní ọdún 2005. Olùjìmí dé ipò giga nínú òsèlú, láti ipò `komísáńná tí ó wà fún iṣẹ́ àti ohun amú ayé derùn àti ọ̀gá àgbà olùdárí. O díje fún ipò sénétò ti o n sojú fún ẹkùn gúúsu Èkì̀tì ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin lábé asìá ẹ̀gbẹẹ alábùradà.[2]

Abíọdún Olújìmì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olósèlú tí ó ní ìrírí jùlo ní orílè èdè Nàíjíríá.

Ẹgbẹ́ alábùradì (PDP) ẹ̀ka ti Ẹ̀kìtì yà án sí ipò adarí ẹgbẹ́, ní ọdún 2018 láti jẹ́ kí ẹgbẹ́ náà gbaradì fún ìdìbò ọdùn 2019. Ojomoyele, Rotimi. “ A dúró tí Olújìmí gẹ́gẹ́ bíi adarí wà ní Ìlú Ẹ̀kìtì fùn egbé a~lábúràdà (PDP)” Iwe Ìròyìn Fàngàdì ti Nàìjíríà, Nàìjíríà. Gba ní ỌjỌ́ kokànlá,osù keta, Ọdún2019.

Nínú ìdìbò gbogbo gbòò ti ọdún 2019, ó fi ìdí rẹmi gẹ́gẹ́ bíi asojú fún gúúsù Ẹ̀kìtì fún ẹgbẹ́ APC. Síbẹ̀síbẹ̀, Ilé ẹjọ́ kotẹ́milọ́rùn polongo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó jáwé olúborí asojú gúúsù Ẹ̀kìtì ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin. Nítorínáà, Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin búra fún un ní ọjọ́ kẹrìnlá, osù kọkànlá ọdún 2019.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]