Jump to content

Adájọ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
ICJ-CJI_hearing_1.jpg

Adájọ́ ni ẹni tí ó ń gbọ́ ẹjọ́ àwọn olùpẹ̀jọ́ yálà gẹ́gẹ́ bí adájọ́ kan ṣoṣo tàbí akójọ àwọn adájọ́ láti ẹnu àwọn agbẹjọ́rò tí wọ́n bá dúró fún nílé ẹjọ́. [1] Adájọ́ ni yóò gbọ́ atótónu awọn agbẹjọ́rò tabi awọn olùpẹ̀jọ́ tí ó fi mọ́ ẹjọ́ lẹ́nu àwọn ẹlẹ́rìí tàbí ẹ̀rí, yóò ṣe ọ̀rínkiniwín àgbéyẹ̀wò sí ẹjọ́ àti agbékalẹ̀ wọn lẹ́nu àwọn agbẹjọ́rò tí ó fi mọ́ àwọn ẹ̀rí máajẹ́mi nìṣó.[2]Adájọ́ yóò wá dá ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí òfin orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fẹ́ dájọ́ bá la kalẹ̀ fún irúfẹ́ ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ àti ìmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́. Ilé-ẹjọ́ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ ni adájọ́ gbọ́dọ̀ ti gbọ́ ẹjọ́ tàbí da ẹjọ́, kìí ṣe inú kọ̀rọ̀ kan. Agbára, iṣẹ́, ìyànsípò àti ìgbẹ̀kọ́ àwọn adájọ́ ni ó yàtọ̀ sírawọn jákè-jádò agbáyé. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ adájọ́ tí wọ́n jọ ń gbọ́ ẹjọ́ kan náà lè jọ wà ní abẹ́ àṣẹ agbára kan náà. Lásìkò míràn tí wọ́n bá ń ṣe Igbóẹ́jọ́ ìwà ọ̀daràn, adájọ́ lè ṣisẹ́ gẹ́gẹ́ oníwádí ẹ̀rí nílé ẹjọ́. Àmọ́ ṣá, bí adájọ́ yóò bá gbọ́ ẹjọ́, ó ní láti ri wípé ilé-ẹjọ́ wà ní ìdákẹ́-rọ́rọ́ ní ìbámu pẹ̀lú òfin ṣáájú kí Igbóẹ́jọ́ tàbí Ìdájọ́ tó wáyé. [3]


Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "judge". Cambridge Dictionary. 2024-04-17. Retrieved 2024-04-19. 
  2. "The Role of Judges". NAACP. 2023-08-21. Retrieved 2024-04-19. 
  3. "National Judicial Council". National Judicial Council. 2024-03-14. Retrieved 2024-04-19.