Jump to content

Adamu Abdu-Kafarati

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Adamu Abdu-Kafarati
Adájọ́ àgbà, Federal High Court ti orílẹ̀ ẹ̀dẹ̀ Nàíjíría
Justice
In office
2018–2019
Arọ́pòJustice John Tsoho

Adamu Abdu-Kafarati (ọdún 1954–2021) jẹ́ adájọ́ ọmọ orílẹ̀ ède Nàìjíríà nígbà ayé rẹ̀. Ó fi ìgbà kan jẹ́ adájọ́ àgbà ti ilé ẹjọ́ àgbà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1]

Ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Kafarati ní ọdún 1954 sí Kwami, ìjọba ìpínlẹ̀ kan ní Ìpínlẹ̀ Gombe. Ó kàwé Prámárì ní ilé ìwé Kafarati Primary School ní áàrín oṣù Kínní ọdún 1962 sí oṣù Kejìlá ọdún 1968. Ó tún kàwé Government Secondary School, Gombe, láàrin ọdún 1969 àti 1973. Ó sì tún kàwé ní Northeast College of Arts & Science (NECAS), Maiduguri, láàrín oṣù Kẹ̀wá ọdún 1973 sí oṣù kẹfà ọdún 1975. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní Yunifásítì Àmọ́dù Béllò, Zaria, láti oṣù kẹwàá ọdún 1975 sí oṣù kẹfà ọdún 1978, ó kàwé gboyè nínú ìmò òfin ní Nigerian Law School, Lagos, ní ọdún 1979.[2]

Kafarati bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí State Counsel II ní Ministry of Justice ti Bauchi State. Ó jẹ́ principal state counsel ní ọdún 1987 ó sì jẹ́ igbá-kejì administrator-general kí ó tó di adájọ́ ní Federal High Court ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù kẹẹ̀wá ọdún 1991. Ó di adájọ́ àgbà ní Ilé ẹjọ́ àgbà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọjọ́ keje oṣù kẹfà ọdún 2018.[3] Adam Abdu-Kafarati fẹ̀hìntì lẹ́hìn oṣù mẹ́tàlá tí a yàn án sípò, ìyẹn nígbà tí ó pé ọmọ ọdún márùnlélọ́gọ́tá ní ọjọ́ karùnlélọ́gọ́tá oṣù keje (July 25) ọdún 2019.[4]

Adamu Abdu Kafarati fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ kàrúnlélógún oṣù kejì (February 25) ọdún 2021, ní ìkan bi ago méje àbọ̀ ìrólẹ́ (7:30pm)

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Ex-Federal High Court Chief Judge, Kafarati, is dead". The Guardian Nigeria News – Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-02-26. Retrieved 2022-03-26. 
  2. "Kafarati: The man, the tasks – The Nation Newspaper". thenationonlineng.net. Retrieved 2022-03-26. 
  3. "Buhari appoints Chief Judge of Federal High Court" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-06-05. Retrieved 2022-03-27. 
  4. "Ex- Nigerian Chief Judge, Adamu Abdu-Kafarati, is dead." (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-02-26. Retrieved 2022-03-26.