Adejoke Orelope-Adefulire
Adejoke Orelope-Adefulire | |
---|---|
Ígbákejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó | |
In office 29 May 2011 – 29 May 2015 | |
Gómìnà | Babatunde Fashola |
Asíwájú | Sarah Adebisi Sosan |
Arọ́pò | Oluranti Adebule |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Victoria Adejoke Orelope 29 Oṣù Kẹ̀sán 1959 Lagos State, Nigeria |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress |
Alma mater | University of Lagos |
Victoria Adejoke Orelope-Adefulire (tí a bí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ́n oṣù kẹsàn-án, ọdún 1959)[1] jẹ́ olóṣèlú ní orílè-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ igbákejì gómínà Ìpínlẹ̀ Èkó tẹ́lẹ̀rí láti ọdún 2011 sí ọdún 2015.[2] Kó tó di pé ó wọlé gẹ́gẹ́ bíi igbákejì gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, òun ni ó jẹ́ kọmíṣọ́nà fún ètọ́ àwọn obìnrin àti ọ̀nà láti mú ìṣẹ́ pòòórá láàárín ọdún 2003 sí ọdún 2011.
Ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]O lọ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Salvation Army ní Agege, ní Ìpínlẹ̀ Èkó láàárín ọdún 1965 sí 1971. Ó sì tèsíwájú láti lọ ilé-ìwé girama, ó lọ sí St Joseph's Secondary School, Mangoro tí ó wà ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Èkó[3] Ó lọ Yunifásitì ìpínlẹ̀ Èkó(LASU) láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀[4] níbi tí o ti gba àmì-ẹ̀yẹ bachelor degree nínú IMO sociology
Ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọmọ ọba Orelope, tí a bí sínú ìdílé oyè ti ọmọba Kareem-Laka ti Akeja Oniyanru. Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ láàrin ọmọ mẹ́tàlá Orelope-Adefuire tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí "Iya Alanu"[5] Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ PZ industries PLC.[3]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Orelope jẹ́ olóṣèlú, nígbà tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ òṣèlú ,a yàn án sí House of Assembly ní Ìpínlẹ̀ Èkó, láti ṣe aṣojú agbègbè apá Alimosho kìíní, kò pẹ́, kò jìnnà, wọ hn sọ ọ́ di alága ilẹ̀ náà. Ní ọdún 2022, a yàn án gẹ́gẹ́ bíi alága ìdìbò ti èka ìpínlẹ̀ èkó.
Láàárín ọdún 2003 sí ọdún 2007, a yàn án gẹ́gẹ́ bíi Kọmíṣọ́nà Èkó fún ọ̀rọ̀ obìnrin, ó tún dipò náà mú láàárín ọdún 2007 sí ọdún 2011. Ní ọdún 2011, a yàn án gẹ́gẹ́ bíi igbákejì Gómínà ìpínlẹ̀ Èkó, ó sì dipò náà mú títí di ọdún 2015
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Daka, Terhemba (2019-09-28). "Buhari rejoices with Orelope-Adefulire at 60 - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Archived from the original on 2022-02-22. Retrieved 2022-05-30.
- ↑ "How Prepared Is Adejoke Orelope-Adefulire As Deputy Governor? - P.M. News". PM News Nigeria. 2011-04-19. Retrieved 2022-05-30.
- ↑ 3.0 3.1 Nation, The (2020-09-29). "Orelope-Adefulire: A woman of grace @ 61". The Nation Newspaper. Retrieved 2022-05-30.
- ↑ "Princess Orelope-Adefulire dedicates honorary doctorate degree to Nigerian youths, women". TODAY. 2020-12-17. Retrieved 2022-05-30.
- ↑ Bolashodun, Oluwatobi (2016-03-07). "10 things to know about Buhari’s new SSA on sustainable development goals". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2022-05-30.