Jump to content

Babatunde Fashola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
His Excellency

Babatunde Raji Fashola

SAN
Minister of Works and Housing
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
11 November 2015
ÀàrẹMuhammadu Buhari
13th Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó
In office
May 29, 2007 – May 29,2015
AsíwájúBola Tinubu
Arọ́pòAkinwunmi Ambode
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí28 Oṣù Kẹfà 1963 (1963-06-28) (ọmọ ọdún 60)[1]
Lagos State, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressive Congress
(Àwọn) olólùfẹ́Abimbola Emmanuela Fashola
Occupationlawyer, Politician

Babatunde Raji Fashola (tí a bí ní 28 June, 1963) jẹ́ agbẹjọ́rò àti olóṣèlú órílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2] Ó ti fìgbà kan jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó fún sáà méjì láti ọdún 2007 sí ọdún 2015 lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́-òṣèlú All Progressives Congress. Olóyè Bola Tinubu ni ó jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó ṣáájú rẹ̀.[3][4] Lodun 2015, Ààrẹ Muhammadu Buhari yàn-án gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fún ètò iná-mọ̀nàmọ́ná, ilé ìgbé, àti iṣẹ́. Ààrẹ tún tún-un yàn lọ́dún 2019 sí ipò yìí kan náàsí ipò Mínísítà fún Agbára àti ìná mọ̀nàmọ́ná.[5]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Fashola ní ọjọ́ 28 June, ọdún 1963,[6]Ìpínlẹ̀ Èkó, ní Island Maternity Hospital, sínú ìdílé Ademola Fashola, tó fìgbà kan jẹ́ akọ̀ròyìn fún ìwé-ìròyìn Daily Times ti Nàìjíríà, àti Olufunke Agunbiade, to jẹ́ nọ́ọ̀sì.[7]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Amòfin[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-ẹjọ́ gíga[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n pè é sí ilé-ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bíi agbẹjọ́rò àti onídùúró ti ilé-ẹjọ́ gíga ní November 1988[8] lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Nigerian Law School, ní ìpínlẹ̀ Èkó láàárín ọdún 1987 àti 1988.[9]

Àmi-ẹ̀yẹ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fashola, tó jẹ́ ènìyàn kan tó gbajúmọ̀ ní Ilé-ẹjọ́ Gígajùlọ ilẹ̀ Nàìjíríà, ti gba àmì-ẹ̀yẹ àti ìwé-ẹ̀rí títayọ bíi Distinguished Alumnus Award tí ìgbìmọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gboyè ti Yunifásítì ìlú Benin fún un.[10] Ó tún gba àmì-ẹ̀ye ti Lagos State public service club Platinum Award fún iṣẹ́ títayọ rẹ̀ sí ìdàgbàsókè. Bẹ́ẹ̀ náà ni ti Alliance for Democracy, "àmì-ẹ̀yẹ ti ìjọba ìbílẹ̀ Igbogbo Bayeku" ní ìbámu pẹ̀lú ìfarahàn àti iṣẹ́ rẹ̀ sí ẹgbẹ́ náà.

Babatunde Fashola tún jẹ́ alábòójútó àwọn akẹ́kọ̀ó ìmọ̀-òfin, tí Yunifásítì ìlú Benin, òun sì ni akẹ́kọ̀ọ́ kejì tó máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀-òfin ní Yunifásítì ìlú Benin, àti ọmọ ẹgbé Nigerian Law School àkọ́kọ́ tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 1988, tí wọ́n fi joyè Senior Advocate of Nigeria.[11] Fashola náà ni Chief of Staff àkọ́kọ́ tó gba irú oyè bẹ́è. Babatunde Fashola jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Nigerian Bar Association, International Bar Association àti Chartered Institute of Taxation of Nigeria.

Ní oṣù kẹwàá ọdún 2022, oyè ńlá tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí a mọ̀ sí oyè Commander of the Order of the Niger (CON) ni a tún fi dá a lọ́lá láti ọwọ́ Ààrẹ Muhammadu Buhari.[12]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "HIS EXCELLENCY, BABATUNDE RAJI FASHOLA (SAN), GOVERNOR OF LAGOS STATE, NIGERIA". Commonwealth Business Council. Archived from the original on 2010-07-22. Retrieved 2010-02-14. 
 2. "Governor Babatunde Raji Fashola - Profile". Africa Confidential. 2019-10-03. Retrieved 2019-10-03. 
 3. "His Excellency Mr. Babatunde Raji Fashola, SAN". lagosstate.gov.ng Lagos State Government. Archived from the original on 10 December 2009. Retrieved 27 January 2010.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 4. "FG, agencies to construct 1,800km road at N621b". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-12-22. Retrieved 2022-02-22. 
 5. Toromade, Samson (2019-08-21). "Fashola loses Power ministry, retains Works and Housing". Google. Retrieved 2019-10-03. 
 6. John M. O. Ekundayo (2013). Out of Africa: Fashola: Reinventing Servant Leadership to Engender Nigeria's Transformation. AuthorHouse. p. 18. ISBN 978-1-481-7904-06. https://books.google.com/books?id=WjhKyg8OjBUC&q=fashola+yoruba&pg=PA18. 
 7. "Babatunde Fashola biography, net worth, age, family, contact & picture". www.manpower.com.ng. Retrieved 2022-01-18. 
 8. "Ministerial nominee, Babatunde Raji Fashola's CV". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-10-12. Retrieved 2022-02-28. 
 9. Ajumobi, Kemi (2015-07-05). "Babatunde Raji Fashola, the irrefutably astounding transformational leader". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-04. 
 10. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :12
 11. Lagos State Government. "Babatunde Raji Fashola (2007 – 2015)". 
 12. "FULL LIST: 2022 National Honours Award Recipients The Nation Newspaper" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-10-09. Retrieved 2022-10-31. 

Ìkìlọ̀: Bọ́tìnì ìtò àkọ́kọ́ṣe "Fáṣọlá, Babátúndé" dípò Bọ́tìnì ìtò àkọ́kọ́ṣe "Fashola, Babatunde" tẹ́lẹ̀.