Sarah Adebisi Sosan
Sarah Adebisi Sosan | |
---|---|
Ìgbàkejì Gómìnà ìpínlè Eko | |
In office 29 May 2007 – 29 May 2011 | |
Gómìnà | Babatunde Fashola |
Asíwájú | Femi Pedro |
Arọ́pò | Adejoke Orelope-Adefulire |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 11 Oṣù Kejì 1956 Ojo, Badagry, British Nigeria (now Ojo, Lagos State, Nigeria) |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress |
Alma mater | University of Lagos |
Sarah Adebisi Sosan jẹ́ olùkọ́ni tẹ́lẹ̀ rí àti igbákejì Gómìnà Èkó láàrin ọdún 2007 sí 2011 nígbà tí Babatunde Fashola jẹ́ Gomina ìpínlè Eko.[1]
Ìpìlẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Sarah sí ìpínlẹ̀ Èkó ní 11 Febuary 1956 sínú ìdílé Olóyè àti Ọmọọba Durosinmi ti ì̀lú Irewe ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ojo, Badagary. Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọọba Ita-Oníkòyí ní Ìdúmọ̀tà, Èkó, bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmoọ ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group(AG) àti Unity Party of Nigeria(UPN), nítorí pé Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọba, Sarah náà gba orúkọ "ọmọọba".[2]
Ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó bẹ̀rẹ̀ ìwé rẹ̀ ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Christ Assembly, Àpápá àti ìwé girama rẹ̀ ní Àwórì-Ajeromi.[3] Ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Lagos State College of Education, Ijanikin (tí a ti yí orúkọ rẹ̀ padà sí Adeniran Ogunsanya College of Education) ní ọdún 1980 níbi tó ti gba ìwé-ẹ̀rí NCE, lẹ́yìn náà, ó lọ Yunifásítì ìlú Èkó, Àkọkà, níbi tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ Bachelor of Arts ní ìmọ̀ èdè òyìnbó ní ọdún 1988, ó sì gba àmì-ẹ̀ye Master degree nínú ẹ̀kọ́ àgbà ní ọdún 1989.
Òṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Láàrin ọdún 1990 sí 1999, Sosan fi iṣẹ́ rẹ́ gẹ́gé bíi olùkọ́ni kalẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó, gẹ́gé bíi òṣìṣẹ́ tó ń rí sọ́rọ̀ ẹ̀kọ́. Gómìnà Babatunde Fashola padà yàn án gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀ ní ọdún 2007.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Sarah Adebisi Sosan". Innovations for Successful Societies. 2009-08-05. Retrieved 2022-05-30.
- ↑ "Sarah Adebisi Sosan". Academic Influence. 1956-02-11. Retrieved 2022-05-30.
- ↑ "Women You Should Know: Sarah Adebisi Sosan • Connect Nigeria". Connect Nigeria. 2020-10-08. Retrieved 2022-05-30.