Jump to content

Adekunle Gold

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Adekunle Gold
Orúkọ àbísọAdekunle Kosoko
Ọjọ́ìbí28 Oṣù Kínní 1987 (1987-01-28) (ọmọ ọdún 37)
Lagos State
Irú orin
Occupation(s)
Instruments
Years active2010–present
Associated acts
Websiteadekunlegold.com

Adekunle Almoruf Kosoko (tí a bí ní Oṣù Kìíní Ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, Ọdún 1987), tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Adekunle Gold àti AG Baby, jẹ́ olórin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, akọrin sílẹ̀ ati ayàwòrán. [1] Ó di ìlúmọ̀ọ́ká olórin lẹ́yìn tí ó kọ orin kan tí a mọ̀ sí “Ṣadé” ní ọdún 2015. Ní ọdún 2015, ó fọwọ́síwèé àdéhùn ìgbàsílẹ̀ pẹ̀lú YBNL Nation tí ó sì gbé orin [[studio]] kan jáde tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Gold, èyí tí ó wà ní ipò keje ti Billboard àgbáyé. Ṣáájú Gold ni ó ti kọ àwọn orin mẹ́ta kan tí àkọ́lé wọn ń jẹ́ "Sade", "Orente" ati "pick up". Adekunle Gold fi hàn sí Ilé Ìdanilárayá Nàìjíríà lónìí pé ṣáájú kí ó tó f'ọwọ́ sí pẹ̀lú YBNL, ó ṣe àpẹẹrẹ aami ti ilé-iṣẹ́ náà àti pé ó parí àwọn àpẹẹrẹ mìíràn fún Lil Kesh, Viktoh àti Olamide.[2]

Adekunle Gold

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adékúnlé Kòsókó tí a bí sí ìdílé Ọba Kòsókó ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà ní ọjọ́ kejì-dín-lọ́gbọ̀n ọdún 1987.

Ètò Ẹẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó gboyè HND ní ilé-ẹ̀kọ́ giga ti ìpínlẹ̀ Èkó. [3]

Adekunle gbé Simi níyàwó nínú ayẹyẹ ìsọkan tí wọn kò jẹ́ kí ìlú tàbí àgbáyé mọ̀ sí ní oṣù kìíní ọdún 2019.[4] Ó fi hàn lẹ́hìn náà pé wọ́n ti ní ìbáṣepọ̀ fún ọdún márùn-ún.[5] Wọ́n ṣe ìtẹwọ́gbà ọmọbìnrin tí wọ́n bí ní oṣù kárùn-ún ọdún 2020.[6]

Lákòókò tí ó ń dàgbà, Adékúnlé bẹ̀rẹ̀ sí ní nífẹ̀ẹ́ sí orin nígbà tí ó ń tẹ́tí sí àwọn orin King Sunny Ade àti Ebenezer Obey. Nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ọ́, ó dára pọ̀ mọ́ àwọn akọrin ìjọ rẹ̀. Ó sì kọ orin àkọ́kọ́ rẹ̀ nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún. Ní ọdún 2014, Adékúnlé pinnu àti dá dúró lẹ́yìn tí ó yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ kan tí ó dara pọ̀ mọ́ nígbà tí ó wà ní ilé-ìwé. Ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kejìlá ọdún 2014, ó gbé orin kan jáde tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Sade", "one's direction" àti "story of my life" Orin náà tàn ká lè a sì yàn-án bí i orin tí ó dára jù lọ ní ọdún 2015.[7]

Àtòjọ díẹ̀ nínú àwọn orin rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • "Sade" (2014)
  • "Temptation" (2014)
  • "Orente" (2015)
  • "Pick Up" (2015)
  • "No Forget" feat Simi (2016)
  • "Ariwo Ko" (2016)
  • "Friend Zone" (2016)
  • "Nurse Alabere" (2016)
  • "Ready" (2016)
  • "My Life" (2016)
  • "Nurse Alabere" (2016)
  • "Friend Zone" (2016)
  • "Work" (2016)
  • "Beautiful Night" (2016)
  • "Fight For You" (2016)
  • "Sweet Me" (2016)
  • "Paradise" (2016)
  • "Call on me" (2017)
  • "Only Girl" feat Moelogo (2017)
  • "Money" (2017)
  • "Ire" (2018)
  • "Damn Delilah" (2018)
  • "Before You Wake Up" (2019)
  • "Young love" (2019)

Àwọn àmìn ẹ̀yẹ tó gbà àti àwọn tí wọ́n yàn án díje fún

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Year Award ceremony Prize Recipient/Nominated work Result
2016 Nigeria Entertainment Awards Best Song Pick Up Gbàá
Best New Act to Watch Himself Gbàá
2016 The Headies Best Alternative Song "Sade" Gbàá
2015 Nigeria Entertainment Awards Best New Act "Himself" Gbàá
2017 City People Entertainment Awards Album of the Year "Himself" Gbàá
2017 City People Entertainment Awards Collabo of the Year "Himself and Simi" Gbàá
2017 IARA Best African Music Artist "Himself" Gbàá

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "I didn’t lobby to be signed by Olamide – Adekunle Gold". 12 August 2015. http://www.vanguardngr.com/2015/08/i-didnt-lobby-to-be-signed-by-olamide-adekunle-gold/. Retrieved 29 October 2015. 
  2. Kayode Badmus (21 August 2015). "I was involved with YBNL before Olamide signed me – Adekunle Gold". Nigerian Entertainment Today. Archived from the original on 21 August 2015. 
  3. Alli, online (25 September 2015). "Adekunle Gold: From Royalty To Music". Daily Times of Nigeria. http://www.dailytimes.com.ng/adekunle-gold-royalty-music/. Retrieved 29 October 2015. 
  4. Ademola Olonilua; Timileyin Akinkahunsi (12 January 2019). "Adekunle Gold, Simi's white wedding date yet to be fixed –Manager". Punch. Retrieved 24 February 2019. 
  5. Olowolagba, Fikayo (2019-01-17). "We dated for 5 years - Adekunle Gold confirms getting married to Simi". Daily Post Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-10-22. 
  6. "Adekunle Gold, Simi welcome first child | Premium Times Nigeria". 7 June 2020. 
  7. "Adekunle Gold – Official Site". Adekunle Gold – Official Site (in Èdè Ítálì). Retrieved 2020-01-04.