Shola Allyson

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Shola Allyson-Obaniyi
Oríkọ àbísọOlusola Allyson
Wọ́n bíi níIkorodu, Lagos State
Genres
Occupation(s)
Years active2003–present
LabelsGalaxy Music
Associated actsCobhams Asuquo
Websitesolaallyson.com

Shola Allyson-Obaniyi, je omo orile ede Naijiria ti o je akorin emi (soul) ati  (folk), o si tun je oluko orin. O di gbaju gbaja akorin pelu orin re kan ti o pe ni"Eji Owuro" ni odun (2003), ti orin re yi tun je orin ti won lo ninu sinima agbelewo kan ti oruko re naa n je " Eji Owuro". Leyin ti o gbe awo re yi jade, awon awo orin miiran ti o tele ni:" Gbe Je F'ori" , "Im'oore".  Ninu awo orin re "Eji Owuro" yi ni a ti ri awon ese orin bii: "Obinrin Ni Mi", "Aseye", "Isinmi", ati bee bee lo.[1] Yato si wipe Shoila je olorin , o tun je akoni lohun orin "voice coach", olugbani  nimoran.[2]

Ibere igbesi Aye re ati irin ajo eko re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Won bi Shola Allyson ni ilu Ikorodu, ni ipinle Eko ni ibere odun 1970. O lo si ile-iwe alakoobere Anglican , ti ilu Ikorodu, leyin eyi ni o te siwaju ni ile-iwe Girama Shams-el-deen, ni ilu Ikorod fun ipele eko eleekeji. Leyin eyi ni o lo si ile-iwe Gbogbonise  ti ijoba  (Technical College) ni Agidingbi Ikeja, ni bi ti o ti ko nipa imo okowo  (Business Studies) ti o si gba iwe eri  (NBTE).[3]

Ni odun 1997, o wo ile-iwe Polytechnic, Ibadan ti o si ko nipa imo Ayinike Orin (Music Technology), ti o da lori bi a se n lo ohun ninu orin. Ibe ni o ti ni iwe eri (HND) Higher National Diploma pelu ipo ti o ga julo.[3][4]

igboke-gbodo ise re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Arabinrin Shola Allyson bere igboke-gbodo ise orin re ni opin odun 1980s, nigba ti o wa ni omo odun Metala (13 yrs).[3][4] Leyin eyi ni o di elegbe to yanranti leyin awon olorin ilu-mooka bi: Yinka Ayefele, Gbenga Adeboye, Wasiu Alabi (Pasuma), Akande Abass (Obesere) ati olorin rege (Daddy Showkey). Iwonba afani ti o ri lati se awo orin tire akoko jade iyen "Eji Owuro" waye nigba ti o pade orakunrin kan ti o mu iwe eto ere ori-itage kan dani ninu oko akero, ti okunrin naa si ba Sola takuroso lori ere nise ori-itage ti won sese se laseyori ti akole re n je "Orekelewa" (You at a distance). Bayi ni okunrin naa se pe Sola Allyson lati wa korin fun ere naa, ti orin re si sokunfa bi won se yi akole ere naa pada si "Eji Owuro" (The morning Dew). Nigba ti sinima  Eji Owuro jade tan, ile ise ti o ya aworan sinima naa pinu lati gbe awo orin jade pelu akole sinima yii iye "Eji Owuro". Aseyori nla gbaa ni awo orin yii je fun ile ise ati olorin funra re "Shola Allyson" ti o si so Sola di ilu-mooka olorin ni awujo awon korin korin.[2][4]

Igbesi aye re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Shola Allyson se igbeyawo ninu osu Erena, odun 2003 (March 2003). O pade olowo ori re arakunrin, Toyin Obaniyi ninuy egbe akorin ijo won. Won si bi awon omo meta fura won: Ayobami, Mopelola and Obafunmiwo.[3][4][5]

Awon awo orin re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Albums[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Eji Owuro (2003)
  • Gbe Je F'ori (2005)
  • Ire (2007)
  • Im'oore (2009)
  • Adun (2012)

Awon Itoka si[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Akinnagbe, Akintomide (30 December 2011). "GALAXY MUSIC BOSS,AHMED ENDS 3-YEAR RIFT WITH SHOLA ALLYSON". Modern Ghana. Retrieved 27 August 2016. 
  2. 2.0 2.1 Salami, Tayo (17 February 2015). "I’m privileged to enter into people’s souls – Sola Allyson-Obaniyi". News Watch Times. Retrieved 27 August 2016. 
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 "Sola Allyson - Biography". 
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 "WHY I DON’T WEAR SKIMPY DRESSES –SOLA ALLYSON-OBANIYI". Nigeria Films. The Nigerian Voice. 6 August 2007. Retrieved 27 September 2016. 
  5. "My music heals suicide-prone minds, Says SOLA ALLYSON-OBANIYI". The Nation. Osun Defender. 15 December 2013. Retrieved 27 September 2016.