Jump to content

Adunni Oluwole

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Adunni Oluwole (1905-1957) jẹ́ Òṣèlú Nàìjíríà kí wọ́n tó gba òmìnira àti ẹni tó máa ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn tó wí pé ó lòdì sí òmíràn nígbà náà.[1] Wọ́n bi ní ìlú Ibadan, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti dàgbà sí Aroloyo, Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó jẹ́ Oníwàásù tó máa ń jáde kiri tí ó sì ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ dáadáa láwùjo, èyí wà lára àwọn nǹkan tó jẹ́ kó gbajúmọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Ó darapọ̀ mọ́ Ìṣèlú ní ọdún 1954, àti jẹ́ olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Nigerian Commoners Liberal. Ó kú ní ọdún 1957 lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́ tó ṣe é.[2]

Ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Adunni Oluwole ní ìlú Ìbàdàn ní ọdún 1905 sí ìdílé ológun ní Ìbàdàn. Lẹ́yìn ìjà ráńpẹ́ ní ẹbí wọn ní ẹbí wọn, ìyá rẹ̀ kúrò pẹ̀lú òun àti àwọn ìbátan rẹ̀ lọ sí Aroloya, Ìpínlẹ̀ Èkó níbi tí ilé wọn súmọ́ St. John's ṣọ́ọ̀ṣì. Adolphus Howells, Alàgbà náà ṣíṣe ìdàgbàsókè sí ẹbí náà nígbà tí wọ́n gbé ní ibẹ̀. Ó gbé pẹ̀lú Howells, tí ó fi sí ilé-ìwé St. John's ní Aroloya.[3] ó padà ọ sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ lẹ́yìn tí ó parí ilé-ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. ."Adunni Oluwole warned against this independence". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-01-09. Retrieved 2019-07-27. 
  2. "Adunni Oluwole". Litcaf (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-01-27. Archived from the original on 2021-06-25. Retrieved 2019-07-27. 
  3. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Litcaf2