Jump to content

Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Egbeda

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Egbeda
LGA and town
Egbeda bus stop
Egbeda bus stop
Egbeda is located in Nigeria
Egbeda
Egbeda
Coordinates: 7°22′53″N 3°57′59″E / 7.3813°N 3.9665°E / 7.3813; 3.9665Coordinates: 7°22′53″N 3°57′59″E / 7.3813°N 3.9665°E / 7.3813; 3.9665
Country Nigeria
StateOyo State
Government
 • Local Government Chairman and the Head of the Local Government CouncilOyedele Sikiru Sanda (PDP)
Time zoneUTC+1 (WAT)

Egbeda jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Olú-ìlú rẹ̀ wà ní ìlú Egbeda. Wọ́n gé agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Egbeda kúrò nínú agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Lagelu, ní ọdún 1989. Kóòdù ìfíwéránṣẹ́ ìlú náà ni 200109[1]

Ìlú yìí ní ilẹ̀ tó tóbi tó 191 km2 ài iye ènìyàn tó tó 281,573 ní ìka orí tí ó wáyé ní ọdún 2006.

Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Egbeda pín sí ìpín mọ́kànlá (11), àwọn ni: Erunmu, Ayede/Alugbo/Koloko, Owo Baale/Kasumu, Olodan/Ajiwogbo, Olodo/Kumapayi I, Olodo II, Olodo III, Osegere/Awaye, Egbeda, Olode/Alakia, àti Olubadan Estate.

Alága kan tí wọ́n yàn sípò àti káńsẹ́lọ̀ mọ́kànlá lọ́ ń sẹ̀jọba ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ náà.

Oyè olùṣàkóso ìbílẹ̀ náà ni Elegbeda ti Egbeda, èyí ti Oba Victor Sunday Olatunde Okunola jẹ́ olórí náà lọ́wọ́lọ́wọ́. Wọ́n sì tún jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn lọ́balọ́ba àti ìjòye ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Oṣù tó gbóná jù tí oòrùn sì máa ń yọ jù ni oṣù Ẹ̀rẹnà (March), oṣù tó sì tutù jù ni oṣù Ògún (August). Ìwọn ojú ọjọ́ ìlú Egbeda máa ń ṣe ségesège, láti ìgbà tó kéré jù lọ àti ìgbà tó ga jù lọ.[2][3]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Post Offices- with map of LGA". NIPOST. Archived from the original on 2009-10-07. Retrieved 2009-10-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Egbeda Climate, Weather By Month, Average Temperature (Nigeria) - Weather Spark". weatherspark.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-09-15. 
  3. "Egbeda, Oyo, Nigeria - City, Town and Village of the world". en.db-city.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-09-15. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]