Jump to content

Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Muṣin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Agbegbe Ijoba Ibile Mushin)
Location of Mushin within Lagos Metropolitan Area

Muṣin jẹ́ Ìjọba ìbílẹ̀ kan ní in Ìpínlẹ̀ Èkó.[1] ó jẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ tí ó wà ní apá Gúúsù Ìpínlẹ̀ Èkó ní ẹ̀gbẹ́ Ìlú Ìkẹjà. Muṣin jẹ́ ìlú tí èrò pọ̀ sí jùlọ, látàrí apáọ̀jù èrò yí, ó jẹ́ kí ìwà ọ̀bùn àti ẹ̀gbin ó rẹ̀sẹ̀ walẹ̀ láàrín àwọn olùgbé ibẹ̀, àwọn ilé tí ó wà níbẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ kájú òṣùwọn. Gẹ́gẹ́ ètò ìkànìyàn ọdún 2006 ṣé ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wipe àwọn olùgbé Muṣin tó 633,009 níye.

Ètò ọrọ̀-ajé ati ààtò ìlú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn tí ìjọba àwọn Gẹ̀ẹ́sì wó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, oríṣiríṣi ìdàgbà-sókè ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ń de bá agbègbè Muṣin. Lára rẹ̀.ni bí àwọn ènìyàn ṣe ń kúrò ní abúlé tí wọ́n sì ń kò lọ sí àárín ìgboro Èkó, pàá pàá jùlọ agbègbè Muṣ. Látàrí àpọ̀jù èrò yí, ilé gbígbé ati iṣẹ́ ṣíṣe le koko. Amọ́ sa,ìlú Muṣin tún ní ànfaní láti ní àwọn ilé-iṣẹ́ oríṣiríṣi. Lára àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀ ni ilé-iṣẹ́ aṣọ àti òwú, ilé-iṣẹ́ bàtà, ilé-iṣẹ́ tí ó ń pèsè kẹ̀kẹ́ ológere ati Kẹ̀kẹ́ Alùpùpù àti ilé-iṣẹ́ tí ó ń pèsè mílíkì

Ìlú Muṣin ní àwọn ohun amáyéderùn bíi ilé ìwòsàn àti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀ tí tí dé ilé ẹẹ̀kọ́ girama pẹ̀lú ohun èlò tìgbà lo de fún àwon akẹ́ẹ̀kọ́. Ìlú Muṣin tún ní àwọn ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a lè gbà wọ inú ìlú yìí, àwọn ọ̀nà náà ni, ọ̀nà Èkó, Ṣómólú àti Ìkẹjà. Àwọn ẹ̀yà Yorùbá ni ó pọ̀jù nínú àwọn olùgbé agbègbè yí, tí ó sì jẹ́ èdè abínibí Yorùbá ni wọ́n ń sọ jù níbẹ̀ [2]

Àwọn Ìlú tó pààlà pẹ̀lú Muṣin[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ojú-ọ̀nà márosẹ̀ apá Gúúsù - Oṣòdì sí Àpápá láti Orí afárá Oṣòdì lọ sí ojúnà ọkọ̀ òfurufú tí a bá ń jáde láti inú Oṣòdì lọ sí òpópónà márosẹ̀ Agége ní apá Àríwá - tó pààlà pẹ̀lú Ìjọba Ìbílẹ̀ Súrùlérè, léyìí tí ó tún pààlà pẹ̀lú àwọn òpópónà wọ̀nyí: òpópónà Bishop, Àkọ́bí, LUTH, Ìdí-Àràbà, àti àwọn ní agbègbè Ìlà-oòrùn tó tún lọ sí ojúnà Agége láti Oṣòdì òpópónà Bishop lápáa Ìwọ̀-oòrùn tó lọ sí ojúnà márosẹ̀ Oṣòdì/Àpápá tó wà forí sọ oríta agbègbè Ìtìrẹ́-Ìjèṣà léyìí tí Ìlú Ìtìrẹ́-Ìjèṣà wà lábẹ́ Ìjọba Ìbílẹ̀ Muṣin tẹ́lẹ̀rí.


Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Mushin". NigeriaCongress.org. Retrieved 2007-04-08. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  2. "Mushin | Nigeria". Retrieved 2015-05-22.