Ajodun odun Badagry

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Badagry Festival
Statusactive
GenreFestivals
BeginsAugust
EndsAugust
FrequencyAnnually
Location(s)Badagry, Lagos State
CountryNigeria
Previous eventAugust 2015
Next eventAugust 2016
LeaderOba Akran
Organised byAfrican Renaissance
SponsorMTN
Websitewww.badagryfestival.com

Ọdún ìbílẹ̀ Àgbádá-rìgì jẹ́ ayẹyẹ tí wọ́́n ma ń ṣe ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ́dun tí ó ma ń wáyé ní ìlú Àgbádá-r̀ig̀i  (Badagry), tí ó jẹ́ ìlú ńlá kan ní ìpínlẹ̀ Èkó, ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Àjọ African Renaissance Foundation (AREFO) ló ma ń ṣ̀agbátẹr̀u ayẹyẹ náà. Àwọn èt̀o inú ayẹyẹ náà má ń fi ip̀o ìlú náà hàn ní àsìk̀o ìkóni lẹ́rú àwón Èèbó (slave trade era). Ayẹyẹ náà má ń jẹ́ ìdàpọ̀ àṣà àjogúnbá ilẹ̀ Adúláwọ̀. Àwọn  elétò má ń mú àṣà ìbílẹ̀ tí àwọn olùfẹ́ràn àṣà jákè jádò àgbáyé ma ń wá láti bá wọn yọ̀ lásìkò ayẹyẹ náà. Èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan pàt̀akì nínú àwọn àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ilẹ̀ adúláwò tí wọ́n ma ń gbéga níbẹ̀ ni Egúngún, Ijó ìbílẹ̀, iná gbígbé-jẹ àti bẹ̣́̀e bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà ló tún ma ṣ̀agbékalẹ̀ ìdíje eré bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀-gbá, àti lílù ilù  Sato, àti ìsàmì ọjọ́ ìjàjà-ǹ-gbara .[1][2][3][4][5][6][7][8]

Ìtàn ọdún náà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n dá ayẹyẹ ọdún yìí kalẹ̀ ní ọdún 1999 láti fi ṣe ìrántí ìparí òwò ẹrú tó ti fìgbà kan wáyé rí nínú ìlú náà nígb̀a láé láé.

Ayẹyẹ àjọ̀dún ti ọdún  2015  ni wọ́n pè ní: [9]  ("Toussaint L'Ouverture: The Catalyst for the struggle for liberation of the black"). tó túmọ̀ sí "Akitiyan ìjàjà-ǹ-gbara aláwọ̀ dúdú". Ayẹyẹ náà bẹ̀rẹ̀ ní 20 August tí ó sì wá sópin ní 30 August 2015. Àjọ̀dún ná̀a fi àyè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ Àgbádá-rìgì tó wà káà kiri ilẹ̀ adúláwò tó kù láti kópa nínú ayẹyẹ náà àti láti tún rántí ilé bàbá won.[10] Àjọ̀dún tí wọ́n ṣe kẹ́yìn wáyé nínú ọgb̀a ilé ìwẹ́ girama ìlú náà ìyẹn (Badagry Grammar School), Badagry, ipinle Eko, Nàìjíríà.

Ìtàn òwò ẹrú nílu Àgbádá-rìgì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orúkọ tí ìlú náà ń jẹ́ lónìí (Badagry)  ni wọ́n fà yọ láti inú iṣẹ́ àwọn ènìyàn ìlú náà.  Lára iṣẹ́ náà ni: iyọ̀ ṣíṣe, ẹja pípa, iṣẹ́ àgbẹ̀. Bákan náà, àwọn mìíràn gbà wípé ìlú náà ni wọ́n fi sọrí ẹnìkan tí ó ń jẹ́ Agbedeh,  ẹni tị ó jẹ́ gbajú-gbajà àgbẹ̀ nílu náà tí orúkọ oko rẹ̀ ń jẹ́ Àgbádá-rìgì, tí àwọn Èèbó amúnisìn padà yí sí (Badagry).[11]

Ní àsìkò 18th century Badagry jẹ́ ọnà àrẹ́sẹ̀pa fún àwọn Èèbó tí wọ́n fi ń kó àwọn ẹrú tí wọ́n bá ti rà ránṣẹ́ sí ibi tí wọ́n bá fẹ́ kó wọn lọ. Ibẹ̀ ni ilé tí wọ́n ń pè ní; "Àlọ lámi-lámi" (Point of No Return) tí wọ́n gbẹ́ kànga kan sí tí ó jẹ́ pé ẹrú tí ó bá ti mu nínú omi kànga náà kò tún ní rántí ibi tí ó ti wá mọ́ láé láé. Ní ìparí 18th century, Badagry di ọ̀nà tí wọ́n tún ń kó ẹrú gb̀a láti Portnovo àti Dahomey .[12] Badagry náà tún ni ó jẹ́ àyè kan tí wọ́n ti ma ń dúnàá dúràá lórí iye tí wọ́n fẹ́ ta ẹrú tí wọ́n fi tipá mú nínú ogun abúlé sí abúlé tí ó bá wáyé.[13] Ni ọdún 1983, Olóyè Mobee jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóyè ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó kópa nínú òwò ẹrú lásìkò náà.

Àgbádá-rìgì ní Ilé alájà méjì àkọ́kọ́ (first two-storey building) irú rẹ̀ ní orílẹ̀ èd̀e Nàìjíríà tí wọ́n kọ́ sórí omi Màrínà, wà ní ọdún 1845.[14] Lọ́wọ́ lọ́wọ́́ báyìí, ilé náà kò fi bẹ́ẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́ látàtàrí wípé ìjọba kùnà láti tọ́jú ilé náà. Àmọ́ ìjọba gómìnà Bábátúnde Fashola ḷ́onà àti dá ògo ilé náà padà ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe ọ̀nà márosè tí ó lọ sí ìlú Àgbádá-rìgì .[15][16][17]

Ẹ tún lè wo àwọn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. Japhet Alakam (6 September 2015). "African Magic, masquerades end Badagry festival". Vanguard Nigeria. Retrieved 30 October 2014. 
 2. Japhet Alakam (31 August 2015). "2015 Badagry Festival: Calls for end to modern slavery in Africa". Vanguard Nigeria. Retrieved 30 October 2015. 
 3. Anote Ajeluorou (25 August 2015). "Badagry Festival 2015… uniting the Diaspora with motherland". The Guardian. Retrieved 30 October 2015. 
 4. PM News (31 August 2015). "Fanfare at Badagry Festival". Retrieved 30 October 2015. 
 5. Premium Times (18 August 2012). "Annual Badagry Festival Begins". Retrieved 30 October 2015. 
 6. Yinka Olatunbosun. "Lagos Black Heritage festival 2015 Beckons". Thisday News. Archived from the original on 18 May 2015. Retrieved 30 October 2015. 
 7. Daily Independent. "badagry glimpse lagos famous tourist site". Kimberly Okonkwo. Retrieved 30 October 2015. 
 8. "World mayors hail Badagry festival". Vanguard News. 26 August 2012. Retrieved 30 October 2015. 
 9. mybadagry.org. "Objective of Badagry Festival by Sewedo Balogun". viyhon awhanse. Archived from the original on 4 March 2016. Retrieved 30 October 2015. 
 10. "Badagry Festival". my badagry. Archived from the original on 14 December 2015. Retrieved 30 October 2015. 
 11. Kinberly Okonjwo. "Badagry Glimpse Lagos Famous Tourist Site". Daily Independent. Retrieved 30 October 2015. 
 12. Manuel Barcia (2014). West African Warfare in Bahia and Cuba. Oxford University Press. https://books.google.com/books?isbn=0198719035. Retrieved 30 October 2015. 
 13. Damian C. Dike (2014). "Both Sides of the Same Coin". ISBN 9781496982018. 
 14. Lizzie Williams, Mark Shenley (2012). Nigeria. https://books.google.com/books?isbn=1841623970. Retrieved 30 October 2015. 
 15. Abiose Adelaja (24 March 2014). "Badagry Slave Route faces environmental degeneration". Prime Time. Retrieved 30 October 2015. 
 16. Phillip Curtin. The African Slave Trade. University of Wisconsin Press. p. 314. https://books.google.com/books?isbn=0299054047. Retrieved 30 October 2015. 
 17. Olivier Pétré Grenouilleau. From Slave Trade to Empire. https://books.google.com.ng/books?isbn=1135765898. Retrieved 30 October 2015.