Jump to content

Aláàfin Òfiràn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ofinran
Alaafin Of Oyo
Reign 16th century
Predecessor Onigbogi
Born Nigeria
Died Nigeria
Burial Saki, Nigeria

Aláàfin Òfiràn jẹ́ ọba Ọ̀yọ́ àti àgbègbè rẹ̀ ní sẹ́ńtúrì 16 lápá iwọ̀-oòrùn Afrika[1][2] òun ni ó jọba lẹ́yìn Onigbogi gẹ́gẹ́ bí Alaafin lẹ́yìn tí ó ó lọ ṣe àtìpó lẹ́yìn odi pẹ̀lú àwọn Yoruba díẹ̀ láti Ọ̀yọ́ ni Borgu lásìkò náà. Lásìkọ yii ni wọ́n fi Ofinran jọba nílẹ̀ àjòjì, tí ó sì dara pọ̀ mọ́ àwọn àwọn ará ìlú lẹ́bàá odò Niger àti àwọn ìlú méjì mìíràn lágbègbè náà sì ń gbé papọ̀.

Nígbà tí ó yá, ìbágbépọ̀ àwọn Ọ̀yọ́ àti Borgu kò dán mọ́rán mọ́ bí í ti ìbẹ̀rẹ̀. Ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ láàárín wọn, lásìkò yìí ni Ofinran àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kó kúrò ní Borgu, wọn sì kọjá sí ìlú Kusu. Lásìkò tí wọ́n kúrò ìlú abínibí wọn yìí, nǹkan kò ṣe dáadáa fún wọn, wọ́n sì gbagbọ pé àìgbọràn tí wọ́n ṣe sí ifá ló fà á.

Nígbà tí wọ́n wà ní Kusu, wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní bọ ifá, wón sì pe enikan tí ó ń jẹ́ Alado láti sẹtùtù fún Àlàáfíà àti àwọn ìjòyè tó kù láti lè jẹ́ kí ìlú wà ní àlàáfíà. Bákan náà, ìtàn àhesọ Ọ̀yọ́ kan sọ pé lásìkò yìí ni wón dá ọdún Egúngún sílẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá. Wọn gbagbọ pé ọlọ́jẹ̀ Egúngún tẹ́lẹ̀ àwọn Yorùbá wá láti ìlú Borgu wá sí Kusu.

Nígbà tó pẹ́, Ofinran kú, wọn si sin ín sí ibi kan ni Ṣakí.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Aribidesi Adisa Usman; J.E. Hedges (2001). State-periphery relations and sociopolitical development in Igbominaland, North-Central Yoruba, Nigeria: oral-ethnohistorical and archaeological perspectives. 993. British archaeological reports (BAR Series): International series, University of Michigan. ISBN 978-1-841-7119-42. https://books.google.com/books?id=PDNmAAAAMAAJ&q=Ofinran+century+in+Oyo+Empire. 
  2. Folorunsho Afodunrinbi; S. O. Babayemi (1991). Topics on Oyo history. Lichfield Nigeria. ISBN 9789783049857. https://books.google.com/books?id=6X0uAQAAIAAJ&q=Ofinran+Oyo+empire+century. 
  3. Samuel Johnson; Obadiah Johnson. The History of the Yorubas, From the Earliest of Times to the Beginning of the British Protectorate. p. 159.