Jump to content

Aloe Vera (fíìmù)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

 

AloeVera
AdaríPeter Sedufia
Olùgbékalẹ̀Manaa Abdallah
Anny Araba Adams
OrinReynolds Addow (Worlasi)
Ìyàwòrán sinimáRichard Kelly Doe
Isaac A. Mensah
OlóòtúAfra Marley
Peter Sedufia
Déètì àgbéjáde
  • 2020 (2020)
Orílẹ̀-èdèGhana

Aloe Vera jẹ́ fíìmù Ghana tí ọdún 2020, èyí tí Manaa Abdallah àti Anny Araba Adams ṣe àgbéjáde, tí Peter Sedufia sì jẹ́ olùdarí fíìmù náà.[1][2][3][4]

Ní ìlú kan, ọ̀wọ́ méjì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé níbẹ̀, ìyẹn àwọn Aloe àti Vera. Ìṣorogún wà ní àárín àwọn méjèèjì, èyí tó dẹ́ orí àwọn ọmọ wọn náà. Nígbà tí àwọn ọmọ adarí ìlú naà bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ ara wọn, ìyẹn Aloewin àti Veraline, wọ́n ní láti wá ọ̀nà láti yanjú ìṣorogún tí ó wà láàárínn ìlú méjèèjì. Lẹ́yìn gbogbo rẹ̀, wọ́n padà di oṣùṣù ọwọ̀ kan ní ìlú náà látàri àwọn olólùfẹ́ méjèèjì.[5]

Àwọn òṣèré tó kópa

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Aaron Adatsi bí i Aloewin
  2. Ngozi Viola Adikwu bí i Verari
  3. Benjamin Adaletey bí i Paa Vera
  4. Kofi Adjorlolo bí i Papa Aloe
  5. Ben Affat bí i Aloeway
  6. Eric Agyemfra bí i Vera Man 1
  7. Kobina Amissah-Sam bí i Father
  8. Rhoda Okobea Ampene bí i Vera Woman 1
  9. Fred Amugi bí i Mr. Aloemele
  10. Adjetey Anang bí i Aloedin
  11. Akofa Edjeani Asiedu bí i Mama Aloe
  12. Edinam Atatsi bí i Midwife
  13. Mawuko Awumah bí i Mr. Aloegede
  14. Alexandra Ayirebi-Acquah bí i Veralin
  15. Grace Omaboe
  16. Nana Ama McBrown bí i Maa Vera
  17. Peter Ritchie bí i Vera Man 2
  18. Priscilla Opoku Agyemang bí i Aloemaria
  19. Fiifi Coleman
  20. Gloria Sarfo bí i Verani
  21. Roselyn Ngissah bí i Aloemay
  22. Beverly Afaglo bí i Mother
  23. Naa Ashorkor bí i Veranda
  24. Solomon Fixon Owoo bí i Aloekay
  25. Adamu Zaaki bí i Aloebay

Ní ọdún 2019, wọ́n ṣe ìkéde pé fíìmù náà á jáde, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n fi tó àwọn ará ìlú léti pé Olùdarí fíìmù náà tí í ṣe Peter Sedufia ń kọ àwọn ilé tó ń lọ bí i ọgọ́rùn-ún sí àwọn ìlú kéréje-kéréje ní ìlú Dabala, ní agbègbè Volta ní orílẹ̀-èdel̀ Ghana, láti fi ṣe ibùdó-ìtàn fíìmù náà. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kéde pé àwọn òṣèré bí i Priscilla Opoku Agyemang Nana Ama Mcbrown, ati Roselyn Ngissah á kópa nínú fíìmù náà.[6] Worlasi ni ó ṣiṣẹ́ lórí ohùn orin fiìmù náà.[7] Sedufia ṣe àpèjúwe fíìmù náà gẹ́gẹ́ bí i àtúnṣe sí iṣẹ́ ìṣáájú rẹ, èyí tí ó máa fún àwọn ènìyàn ní iyelórí fún owó wọn.[8]

Aloe Vera ní ìṣúná owó kan tó tó N58,204,500 àmọ́ owó náà padà wọ N77,606,000 nítorí wọ́n lo jú iye ọjọ́ tí wọ́n lérò wí pé wọ́n máa lò lọ, nítorí àwọn ìpènijà tí wọ́n kojú nítorí òjò tó rọ̀ tó bá àwọn irinṣẹ́ wọn jẹ́.[9] Bẹ́ẹ̀ sì ni òjò náà bá àwọn ibùdó ìtàn tí wọ́n fẹ́ lò jẹ́.[10]

Àfihàn àkọ́kọ́ Aloe Vera wáyé ní orílẹ̀-èdè Ghana ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹta ọdún 2020, ní ìlú Accra.[11]Wọ́n ṣàgbéjáde ìpolówó fíìmù yìí kí ọ̀pọ̀ ènìyàn ba lè mọ̀ nípa rẹ̀, Glitz Africa kọ àyọkà pé “Fíìmù yìí ni àwọn òṣèré tó kúnjú òṣùwọ̀n, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn aṣọ ìṣeré wọn bá ìtàn inú fíìmù náà mu, tí ó sì tún ní àhunpọ̀ ìtàn tó dára".Ó tẹ̀síwájú láti ṣàlàyé pé "Fíìmù 'Aloe Vera' ṣàfihàn ẹlẹ́yàmẹyà tí kò fi àyè gba àwọn olólùfẹ́ méjì láti wà papọ̀." [12] Tíkẹ́ẹ̀tì fún ìṣàfihàn àkọ́kọ́ fíìmù yìí tà wàràwàrà, èyí tó mú kí GhanaWeb gbóríyìn fún àṣeyọrí fíìmù náà lórí ìkànni ayélujára wọn.[13][14]

Ní ọdún kan náà, Sedufia ṣe ìkéde pé fíìmù náà máa wà fún wíwò lórí Netflix.[15]

Citinewsroom ṣe àtúnyẹ̀wò fíìmù Aloe Vera, ó sì kọ̀wẹ́ pé "Fíìmù Aloe Vera wà fún gbogbo ènìyàn láti wò, tí ó sì wá̀ ní gbèdéke tó tọ́. Ìṣàfihàn fíìmù náà ò tóbi ní ìwọ̀n, tí àlàyé rẹ̀ ò sì nílò ìtúpalẹ̀ tó lọ títí."[16]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Peter Sedufia premieres new movie 'Aloe Vera' on March 6". Citinewsroom - Comprehensive News in Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-02. Retrieved 2021-02-20. 
  2. "'Aloe Vera' will soon be on Netflix – Peter Sedufia". www.ghanaweb.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-09. Retrieved 2021-02-20. 
  3. "Aloe Vera – NFA MAIN" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-10-23. Retrieved 2021-02-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Annang, Pamela (3 March 2020). "Peter Sedufia to premiere new movie 'Aloe Vera' on March 6". Graphic Online. Archived from the original on 2020-03-20. Retrieved 15 April 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. Asankomah, Tony (2020-02-18). "Trailer Alert: Here's a first look at what "ALOE VERA" is all about.". GhMovieFreak (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-02-20. 
  6. "Peter Sedufia announces title of new movie 'Aloe Vera'". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-09-05. Retrieved 2021-04-14. 
  7. "Mcbrown, Fred Amugi, Others Star In Peter Sedufia's 'Hollywood' Film". Modern Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-04-14. 
  8. "Ghana film industry hasn't shot a film like "Aloe Vera" - Nana Ama McBrown (VIDEO)". Pulse Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-02-05. Retrieved 2021-04-14. 
  9. "How Ghanaian film director blew over N77 million on "Aloe Vera" (VIDEO)". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-05-21. Retrieved 2021-04-14. 
  10. "I cried during one of my shoots because the challenges were too much - Peter Sedufia". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-07-01. Retrieved 2021-04-14. 
  11. ""Aloe Vera" first premiere sold out (PHOTOS)". Pulse Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-09. Retrieved 2021-04-14. 
  12. Empty citation (help) 
  13. "Director of Aloe Vera shares 5 reasons why you must watch the film". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-02-24. Retrieved 2021-04-14. 
  14. ""Aloe Vera" first premiere sold out (PHOTOS)". Pulse Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-09. Retrieved 2021-04-14. 
  15. "'Aloe Vera' will soon be on Netflix – Peter Sedufia". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-09. Retrieved 2021-04-14. 
  16. "Film review: Aloe Vera offers some charm in its vibrant retort to irrational tribalism". Citinewsroom - Comprehensive News in Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-09. Retrieved 2021-04-14.