Arrow of God
Olùkọ̀wé | Chinua Achebe |
---|---|
Country | Àwọn Ìpínlẹ̀ Aṣọ̀kan |
Language | Gẹ̀ẹ́sì |
Publisher | Heinemann London |
Publication date | 1964 |
Media type | Print (hardback) |
Pages | 287 pp |
Preceded by | 'No Longer at Ease |
Followed by | 'A Man of the People |
Ìwé eré onítàn Arrow of God [[[1] |Arrow of God]]. Arrow of God. Heinemann. ISBN 1101666382, 9781101666388., ni wọ́n gbé jáde tí ọdún 1964, ni ó jẹ́ ìwé àpilẹ̀kọ ti gbajú-gbsjà ònkọ̀wé Chinua Achebe. Ìwé yí àti Things Fall Apart pẹ̀lú No Longer at Ease, ni wọ́n sọ wípé wọ́n jẹ́ iwé eré oníṣe onítàn tí ìlapa-èrò wọn dọ́gba jùlọ, tí ẹ̀kọ́,ibùdó ìtàn, àti olú-kókó ọ̀rọ̀ inú wọn náà sì fara jọra, tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń pè níTrilogy. Ìwé yí dá lórí olú ẹ̀dá ìtàn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Ezeulu", tí ó jẹ́ bàbá Aláwo fún abúlé àwọn Ìgbò tí ó pọ̀ ní àsìkò ìmúnisìn àwọn Gẹ̀ẹ́sì tí ó kojú ìtẹ̀mẹ́rẹ̀ àwọn amúnisìn àti àwọn olùpologo ẹ̀sìn Kírísítì ní àsìkò ọdún 1920. [2] Wọ́n gbé ìwé náà jáde látàrí ipa ribi ribi tí ilé iṣ ìtẹ̀wé Heinemann African Writers Series kó kí ó lè ṣeéṣe.
Orúkọ tí wọ́n pe ìwé yí Arrow of God ni wọ́n fàyọ láti inú òwe àwọn ẹ̀yà ìgbò tí ó túmọ̀ sí 'iṣẹ́ olúwa àwá márídìí'. [3] Ìwé eré onítàn elére oníṣe Arrow of God gba àmì-ẹ̀yẹ ìdálọ́lá ti Jock Campbell àti New Statesman alákọ̀ọ́kọ́ irú rẹ̀ fún ìkọ̀wé ilẹ̀ Adúláwọ̀[4]
Ìtàn inú ìwé náà léréfèé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìwé ereé onítàn eléré oníṣe yí ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ nínú àwọn abúlé àwọn ẹ̀yà Ìgbò tí ó jẹ́ ìkan lára ìletò àwọn Gẹ̀ẹ́sì amínisìn ní àsìkò ọdún 1920s. Ezeulu jẹ́ baba abọrẹ̀ òrìṣà Ulu tí ó kalẹ̀ sí abúlé Alusi, tí oríṣi ìlú tí àpapọ̀ orúkọ wọn ń jẹ́ Umuaro ń sìn. Ìjà kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin ìlú Umuaro àti Okperi tí ó jẹ́ ìlú kan nítòsí Umuaro, ìjà yí wá sópin nígbà tí ọ̀gbẹ́ni T.K Winterbottom tí ó jẹ́ aṣojú àwọn Gẹ̀ẹ́sì amúnisìn bá wọn dá si.
Àwọn Ìtọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Chinua Achebe - Biography, Books, & Facts". Encyclopedia Britannica. 1998-07-20. Retrieved 2023-06-03.
- ↑ "Arrow of God by Chinua Achebe". Time Magazine. November 10, 1967. Archived from the original on 2012-10-20. https://web.archive.org/web/20121020132753/http://www.time.com/time/magazine/article/0,9171,837568,00.html?iid=chix-sphere. Retrieved 2007-09-19.
- ↑ Smith, Daniel Jordan (September 22, 2001). "'The Arrow of God': pentecostalism, inequality, and the supernatural in South-Eastern Nigeria.". Africa (Edinburgh University Press) 71 (4): 587. doi:10.2307/1161581. ISSN 0001-9720. JSTOR 1161581.
- ↑ Ezenwa-Ohaeto Chinua Achebe: A Biography __:James Currey Ltd ISBN 0-85255-545-8 page 105