Ayẹyẹ Ìsìnkú

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ayẹyẹ ìsìnkú àwọn India

Ayẹyẹ Ìsìnkú jẹ́ ọ̀nà ìṣe ẹ̀yẹ, ètùtù tàbí ìṣípà ẹni tí ó di olóògbé (kú).

Ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa Ikú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yorùbá gbàgbọ́ wípé ikú kìí ṣe òpin ìrìn-àjò ẹ̀dá bí kò ṣe ìrín-àjò kúrò ní ipò alààyè sí ipò àìrí, àti wípé ikú jẹ́ ìtẹ̀síwájú nínú ìṣẹ̀mí lásán àmọ́ ní àyè ọ̀tọ̀. [1]

Ìdí tí wọ́n fi ń ṣòkú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní: "Orúkọ rere, ó sàn ju Wúrà Òun Fàdákà lọ". Gẹ́gẹ́ bí àṣamọ̀ yí ti wi, àwọn Yorùbá kúndùn láti ṣètọ́jú orúkọ kí wọ́n si dáàbòbò orúkọ náà kí ó ma bàjẹ́. Àwọn ọmọ àti ọmọmọ pẹ̀lú ẹbí Òun ojúlùmọ̀ lò ma ń ṣàjọyọ̀ lórí ìṣẹ̀mí ayé gidi tí Òkú lò ṣáájú kí ó tó tẹ́rí gbaṣọ. Àjọyọ̀ yí kìí ṣe láti ṣe yègèdè tàbí yẹ̀yẹ́ ẹni wọn tó lọ, bí kò ṣe láti ṣàfihàn ohun rere àti orúkọ rere tí Òkú fi sílẹ̀ẹ̀ lọ. Pàá pàá jùlọ, láti fi àsìkò ikẹ́dùn òun ayẹyẹ so gbogbo mọ̀lẹ́bí òkú papọ̀ kí wọ́n le wà ní ìṣọ̀kan nínú ìṣe wọn gbogbo.[2]

Ṣíṣayẹyẹ Òkú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ayẹyẹ ìsìnkú ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tí òkú bá ti kú. Àwọn mọ̀lẹ́bí yóò ma dín àkàrà, dín mọ́sà fún àwọn tí wón bá wá bá wọn kẹ́dùn ẹni wọn tó lọ láti àárọ̀ tí tí di ìrọ̀lẹ́. Èyí ma ń wáyé lọ́pọ̀ ìgbà fún ọjọ́ mẹ́ta tàbí méje. Èyí dúró fún sàráà (Sacrifice) fún òkú wọn. Mímú ọjọ́ ìṣàjọyọ̀ ìsìnkú ma ń dá lè bí ẹbí kọ̀ọ̀kan bá ṣe fẹnu kò sí. Púpọ̀ nínú ẹbí ni wọ́n sábà ma ń yan isán tàbí ìtàdógún láàyò lọ́pọ̀ ìgbà fún ayẹyẹ àṣekágbá ìsìnkú láyé àtijọ́. Ṣùgbọ́n láyé òde òní, àwọn ẹbí òkú sábà ma ń fi ọjọ́ gbọọrọ tàbí ọdún sílẹ̀ẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó ṣe àṣekágbá òkú wọn. Ìdí èyí ni láti lérò, àti láti wá ohun tí wọn yóò fi bọ́ àwọn èrò tó bá wá síbi ayẹyẹ náà. Ẹ̀wẹ̀, ṣíṣayẹyẹ yí kò ní ṣe kò ní ṣe pẹ̀lú ẹ̀sin, ó kan jẹ́ wípé ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìgbésẹ̀ àti ìlànà tí wọ́n ń tọ̀ lórí irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ nínú gbogbo ẹ̀sìn tó gbajúmọ̀ nílẹ̀ Nàìjíríà tí a mọ̀, gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣe òkú. Oríṣiríṣi ọ̀nà si ni àwọn ẹ̀yà tókù náà ma ń gbà ṣe ìsìnkú wọn. Ó kan jẹ́ wípé ti ẹ̀yà Yorùbá ń ìka ni a gbé yẹ̀wọ̀ lásán ni. [3]

Ohun tí wọ́n fi ń ṣayẹyẹ Òkú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lára àwọn ohun tí wọ́n fi ń ṣayẹyẹ ìsìnkú ni: Óuńjẹ àti ohun mímu oríṣiríṣi tí ẹnu ń jẹ. Pípeléré tí yóò kọrin , lùlù fijó dá wọn lára ya. Gbàgàn ìgbalejò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[4]

Oríṣiríṣi Òkú Sínsi Ní Ilè Yorùbá[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Òkú Abuké
  • Òkú Adẹ́tẹ̀
  • Òkú Aláboyún
  • Òkú Àgbàlagbà
  • Òkú Ọmọdé

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Burial ceremony in Yoruba land". Welcome to the official Home of No-Wayo Bloggers. 2016-11-22. Retrieved 2019-12-18. 
  2. "Nigeria’s flamboyant funerals: Celebrating the dead, but at what cost?". This is africa. 2017-12-14. Retrieved 2019-12-18. 
  3. Nwaubani, Adaobi Tricia (2013-05-23). "Igbo burials: How Nigeria will bid farewell to Achebe". BBC News. Retrieved 2019-12-18. 
  4. "Burial Traditions of Lagos Nigeria". Akip Travel. Archived from the original on 2019-12-18. Retrieved 2019-12-18.